Baba Ijesha: Iléèṣẹ́ ọlọ́pàá ní wọ́n le gba béèlì ẹ̀ṣùn bíbá ọmọdé tage àmọ́ wọn kìí gba béèlì bíbá ọmọdé lòpọ̀

Akeem odumosu, ọga ọlọpaa nipinlẹ Eko

Ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ti kede pe oun ko ni gba beeli gbajumọ osere tiata ti wọn fẹsun kan pe o fi tipa ba ọmọ ọdun mẹrinla lopọ, ti ọpọ eeyan mọ si Baba Ijesha.

Kọmisana fun ileesẹ ọlọpa nipinlẹ Eko, Akeem Odumosu lo kede bẹẹ lasiko ipade akọroyin to se ni olu ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko lọjọ Ẹti.

Odumosu, ẹni to sọrọ lori iwọde tawọn ajafẹtọ ẹni kan se wa sọdọ rẹ lati tako beeli Baba Ijesha tun ni, ẹsun meji ni wọn fi kan afurasi naa, idi si niyi ti yoo si se wa ni ahamọ ọlọpaa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Ẹsun akọkọ ni pe o ba ọmọ kekere lopọ lasiko ti ko tọ ati nibi ti ko tọ, ẹẹkeji nipe o n fi ọwọ kan ọmọde naa laigba asẹ lọwọ awọn obi rẹ.

A ri wipe nipa ẹsun keji yẹn, gbogbo iwadi ti a ṣe lo ti fi idi ẹ mulẹ wipe, o sẹ si ẹsun ti wọn fi kan sugbọn à ń duro ki ile ẹjọ sísẹ, ka le gbe lọ si ile ẹjọ.

Awọn ajafẹtọ ẹni

Ẹsun nina ọwọ ere oge si ọmọde ta mọ si Sexual Assault ni wọn le fun afurasi ẹsun naa ni beeli amọ ẹsun ifipa ba ọmọde lopọ, eyiun Defilement ni wọn kii gba oniduro rẹ fun afurasi nipinlẹ Eko."

Kọmisana ọlọpaa ni Eko fikun pe, Ile ẹjọ nikan lo le fi idi rẹ mu lẹ pe lootọ ni Baba Ijesha jẹbi tabi bẹẹ kọ, amọ isẹ tiwa ni ka se iwadii, ka si fi oju afurasi naa ba ile ẹjọ.

"A ti ri ẹri to dani loju wipe Baba Ijesha ṣe nkan to yẹ ko ṣe labẹ ofin sugbon a kò ti fi silẹ.

À ti gbe iwe ẹjọ rẹ (Case file) lọ si ileeṣẹ ijọba to wa nipa ọrọ ofin (Justice ministry) lati ba wa fi oju ofin woo.

Ọga ọlọpaa n ba awọn ajafẹtọ ẹni sọrọ

Nkan ti àwọn ọlọpaa ń duro de niyẹn, esi ti wọn ba fun wa labẹ ofin ni yoo ṣokunfa igbesẹ ọlọpaa sugbọn esikesi ti wọn ba fun wa, ọlọpaa yoo jẹki àwọn araalu mọ.

Emi gẹgẹ bi ẹnikan bi Ọga ọlọpaa ipinlẹ Eko, n ko ti ni kiwọn fi silẹ o, o si wa ni ahamọ ti wọn fi si"

Ọga ọlọpaa tun sọ wipe, ẹsun ti wọn le gba iduro eeyan ni ẹsun ti Baba Ijesha sẹ sugbọn ti wọn ba gba iduro afurasi lori rẹ, ko tumọ si wipe ẹsun ti wọn fi kan ti pari tabi pe o ti jare ẹsun ti wọn fi kan.

"Ofin keji tun ni wipe afurasi ti wọn gba iduro rẹ lori iru ẹsun yii, ṣe eyi ko ni koba iwadi ti ọlọpaa ń se lọ, ti o ba jasi wipe yoo sakoba fun iwadi naa, agbara wa labẹ ofin lati mase gba iduro ẹni bẹẹ."

Ọga ọlọpaa n ba awọn ajafẹtọ ẹni sọrọ

Odumosu wa mọ riri awọn ajafẹtọ ẹni to n se iwọde naa fun ọgbọn agba ti wọn lo lasiko iwọde wọn, to si ni ahesọ ọrọ ni pe wọn fẹ fun Baba Ijesha ni beeli.

"Ko si ẹni to n dunkooko mọ wa lati tu Baba Ijesha silẹ, bẹẹ ni ko si ẹni to n wa eekanna mọ mi lọrun bii Kọmisana ọlọpaa.

N ko le se ohun ti n ko ni awijare fun labẹ ofin, emi funra ara mi si ni mo n se amojuto gbogbo ẹsun to ba jẹ mọ iwa iyajusini laarin takọ-tabo".

Amin iyasọtọ kan

Iwọde alagbara n bọ l‘Eko laarọ oni lati tako beeli Baba Ijesha

Saaju la ti sọ fun yin pe, iroyin to n tẹ wa lọwọ bayii ti salaye pe iwọde alagbara kan yoo waye ni aarọ oni ọjọ Ẹti nilu Eko, lati ta ko gbigba beeli Baba Ijesha.

Baba Ijesha ni gbajumọ osere tiata ti wọn fẹsun kan pe o nawọ ere oge si ọmọde ọmọ ọdun mẹrinla kan laipẹ yii, to si wa ni ahamọ ọlọpaa ni agbegbe Panti nilu Eko.

Afurasi yii ni iroyin kan sọ pe wọn yoo gba beeli rẹ, ti yoo si maa lọ sile lati maa lọ koju ileẹjọ to ba ya, ti ahesọ iroyin kan si ni, fidio fìdí rẹ múlẹ pe lootọọ ni Baba Ijesha ba ọmọdebinrin naa ni ajọṣepọ tipa tipa.

Amọ iroyin to n tẹ wa lọwọ bayii ti salaye pe awọn ẹgbẹ ajafẹtọ ọmọniyan lorisirisi ati awọn obinrin to jẹ abiyamọ ti n gbaradi lati tako igbesẹ gbigba beeli Baba Ijesha naa.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori iwọ̀de alagbara to n bọ naa, agbẹjọro ati ajafẹtọ awọn obinrin, Oluwatoyin Ojo sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ni oun ko le sọ pe awọn ko le fidi rẹ mulẹ pe Baba Ijesha jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

Aworan to n tako iwa ifipabanilopọ

Oríṣun àwòrán, @d_lowla

Ajafẹtọ ẹni naa ṣalaye pe ọmọdebinrin yii sọ pe Baba Ijesha ba oun lajọṣepọ nigba toun wa ni ọmọ ọdun meje, pẹlu afikun pe Baba Ijesha tun ki kọkọrọ bọ oun loju ara.

Bakanna ni Baba Ijesha fun ra rẹ jẹwọ pe lootọọ loun fipa ba ọmọdebinrin yii to n gbe lọdọ adẹrinpoṣonu, Princess lọpọ.

"Lẹyin ti ẹrọ CCTV tu aṣiri bi Baba Ijesha tun ṣe fipa ba ọmọ naa ni ajọṣepọ tàn nígbà to pe ọmọ ọdun mẹrinla, n ṣe lo n bẹbẹ fún aforiji pe iṣẹ Esu ni.

Ati pe ile iwosan fidi rẹ mulẹ pe, ẹnikan ti fipa ba ọmọde naa lopọ lẹyin ayẹwo ti wọn ṣe fún ọmọ ọhun.

Àkọlé fídíò, Ogbomoso: Ẹbọ ọkùnrin àti obìnrin tí kò ní ìbálòpọ̀ rí ni wọ́n rú dènà ogun Fulani

Ko gba ibi kan ye mi ohun to mu kawọn ọlọpaa sọ pe ko si ẹri to daju pe lootọọ ni Baba Ijesha fipa ba ọmọ naa lopọ," ajafẹtọ awọn obinrin ṣalaye.

Agbẹjọro naa sọ pe idi ni yii toun at'awọn ọmọ Naijiria kan fi fẹ ṣe iwọde lọ sọdọ awọn ọlọpaa lori ọrọ naa ni aarọ ọjọ Ẹti.

Ajafẹtọ awọn obinrin yii ko ṣai mẹnu ba ipa ti iyanṣẹlodi awọn oṣiṣẹ eto idajọ le ni lori ọrọ naa .

O ni lootọọ ni eeyan ko gbọdọ lo ju ọjọ kan lọ ni atimọle, ti wọn ba fi ẹsun ti wọn le gba beeli rẹ kan an.

Àkọlé fídíò, Olugbon of Igbon: ‘Rubber Stamp’ làwọn aṣòfin àpapọ̀, wọn kò ṣojú aráàlú

Agbẹjọro naa ṣalaye pe eeyan ko gbọdọ lo ju ọjọ meji ni atimọle lọ ti ileẹjọ ba jina labẹ ofin orile-ede Naijiria.

O ṣalaye pe ileẹjọ lo le sọ bo ya Baba Ijesha jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an tabi ko jẹbi.

O ni ti tawọn ọlọpaa ni lati gbe ẹsun ti wọn ba mu wa fún wọn lọ sí ilé ẹjọ.

Bẹẹ ba gbagbe, ọpọ awọn obinrin to jẹ osere tiata ati iya ọmọ ti ọrọ kan, Princess ni wọn se iwọde kan l‘Ọjọbọ ni agọ ọlọpaa Panti, lati tako gbigba beeli baba Ijesha.