Aisha Lawal: Ẹni tó kéde pé mo kú yóò rí ìbínú Ọlọ́run

Aishal Lawal

Oríṣun àwòrán, aishalawal1/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Igbe hà hà ni ó gba ẹni àwọn ènìyàn lójú ìpó ìkànsíraẹni Instagram Aisha Lawal, lẹ́yìn ti ó jáde wá láti sọ nǹkan ti àwọn kan kọ nípa rẹ.

Gẹ́gẹ́ bí gbajúgbajà òṣèré tiata náà ṣe sọ lásìkò tó n bá àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀ loju opo Instagram rẹ̀, ó ṣàlàyé pé, òun kò kú o.

Bakan naa lo ni òun kò ṣe àìsàn, sùgbọ́n òun kò mọ idí ti ẹni tó n gbé RIP, itumọ eyi tii se ‘Sun re o’ sí orí fótò òun, ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sáájú ni fótò kan tí n jà ràìnràìn lori ayelujara, eyi tó ṣàfihan ọmọ tuntun kan ati Aisha Lawal lórí ìbùsùn nilé ìwòsàn àti fótò rẹ̀.

Ẹni to gbe fọto rẹ sita yii lo kọ àkọ́lé pé, "ìkà ènìyàn nìkan ní yóò rí nǹkan yìí ti kò ni tẹ RIP, arábìnrin yìí bímọ ọkunrin làntì tan, ló bá kú.

Aisha Lawal fa awọn tó n ro ikú ròó le Ọlọ́run lọ́wọ́.

Oríṣun àwòrán, Aisha Lawa

Aisha Lawal ní sàdédé ni òun rí àwọn olólùfẹ́ òun ti wọ́n n fi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ lórí Intagram, ti àwọn to mọ Nọ́mbà aago ilewọ òun sì ń pè oun pé àwọn gbọ́ pé ó kú.

"Lẹ́yìn náà ni mo wá lọ sí orí ayélujára níbí tí mo ti rí nǹkan ti ẹni náà kọ"

"Mí ò mọ nǹkan ti ẹni tó n ṣe irú nǹkan báyìí fẹ́ gbà o, ní tèmí mó fi ẹni náà lẹ fún ìdájọ́ Ọlọ́run"

Bakan naa lo fi kun pe oun ki yoo ku iku kiku kan, bikose yiye lagbara Ọlọrun.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Ọ̀pọ̀ àwọn olólùfẹ́ Aisha Lawal náà bẹnu atẹ lu iru iwa ibi báyìí, to si ni ẹnikẹni to ba kede pe oun ku, yoo ri ibinu Ọlọrun.

O fikun pe oun yoo ri ileri Ọlrun lori aye oun, tori oun n sin Ọlọrun Alaaye, gbogbo irinsẹ esu ti wọn ba si se doju kọ oun, ki yoo se rere.

Aisha Lawal fa awọn tó n ro ikú ròó le Ọlọ́run lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, Aisha Lawal