Abija: Yekeen Ajileye, ọ̀gá mi nínú iṣẹ́ tíátà ṣẹ̀ mí, ó ṣẹ ẹlẹ́dàá mi

Abija ati Ajileye

Oríṣun àwòrán, Screen Shot

Yoruba ni ogun ọmọde ko le sere pe ogun ọdun, ọgbọn agba ko si le se asaro pe ọgbọn osu, arẹmaja kankan ko si rara, ajamarẹ ni ko sunwọn.

Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu agba osere kan to gbajumọ ninu ere tiata lede Yoruba, Alhaji Tajudeen Oyewole, ti ọpọ eeyan mọ si Abija ati ọga rẹ, Alhaji Yekeen Ajileye.

Abija lo jẹ ọmọ isẹ fun Olaleye, to si maa n ko ipa to tọju ninu awọn ere ti ọga rẹ naa ba se bii Koto Aye, Koto Ọrun, Ọpa Aje ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n salaye ohun to mu oun kuro ninu ẹgbẹ osere Ajileye ki onitọun to di oloogbe, Abija sọrọ yanya ninu fido kan to gba ori ayelujara kan ti ileesẹ Mohunmaworan Ojopagogo gbe jade.

Àkọlé fídíò, Abìjà: Bàbá mi fi iṣẹ́ ọdẹ ti ń pa lémi lọ́wọ́ ni nítorí babaláwo ni

Ohun to fa ija laarin emi ati ọ̀ga mi Ajileye ree:

Abija ni awọn osere tiata kan lo wa ba ọga oun pe ki oun wa ba awọn kopa ninu ere kan, ti wọn si san gbogbo owo ti ọga oun beere lori oun fun.

O ni sugbọn ọga oun wa fi gbedeke kan le pe, oun ati Fadeyi Oloro ko gbọdọ kopa papọ ninu ere naa sugbọn ọrọ yiwọ nigba ti awọn de Eko, nibi ti ere naa ti n waye.

"Nigba ti mo de Eko, awọn to ni ere naa gbe emi ati Fadeyi Oloro papọ, ta si dijọ kopa tori n ko le pada sẹyin mọ pe n ko se mọ.

Ọga mi gan ko kọkọ ka ọrọ yii kun nibẹrẹ nigba to gbọ pe emi ati Oloro ti koju ara wa ninu ere naa, afi igba ti ọkan lara awọn iyawo rẹ mu lọ wo ere naa l'Eko, nigba ti sinima naa jade.

Ẹsin obinrin ni ọga mi gun, bo si se jade kuro ni gbọngan sinima naa ni oju rẹ ti pọn nigba to ri omilẹgbẹ ero to wa wo sinima yii.

O dabi pe oun naa ti n gbero tẹlẹ lati gbe emi ati Fadeyi Oloro papọ ninu ere, tawọn yẹn si ti siwaju rẹ se bẹẹ."

Àkọlé fídíò, Yollywood: Kò sí ẹni ti òbí mi kò lè sọ̀rọ̀ sí -Sisi Quadri

Ọga mi yọ orukọ mi kuro ninu awọn ti yoo re Mecca, mo fẹ pokunso

Abija ni oun bẹ ọga oun titi, tawọn agbaagba elere naa si pe awọn joko lati pari aawọ naa amọ ọga oun ko gba, to si kọ lati fi ori jin oun.

O fikun pe nigba to ya, awọn kan ni awọn fẹ ran awọn osere Ajileye lọ si Mecca, ti orukọ oun si wa lara wọn.

O ni akoko ti awọn fẹ se adura Mecca yii ni oun gbọ pe oun ko ni ba awọn yoku lọ si Mecca naa tori Ajileye ti fi orukọ ẹnikan to pe ni Musibau rọpo oun.

"Ẹsẹ kan soso ti ọga mi sẹ mi ree, o dun mi pupọ, koda, o dun ẹlẹda mi, nitori ko sọ fun mi nibẹrẹ pe n ko ni lọ.

Iya ati ẹgbọn mi ti wa ba mi nilu Eko lati Osogbo ni ọjọ ti mo da pe maa se adura Mecca, bi mo si se fẹ maa salaye fun wọn nipa ohun to sẹlẹ, ẹkun ni mo bu si.

Iya mi fẹ lọ ba Ajileye amọ mo ni ko ma lọ, ti oun ati ẹgbọn mi si pada si Osogbo pẹlu ibanujẹ.

Ọjọ kẹta ni mo mu okun pe mo fẹ pokunso, amọ mo pade tọọgi kan to fi ohun ọmọ ita ba mi sọrọ pe se opin aye de ni, ti eeyan ko ba lọ si Mecca."

Abija tẹ́siwaju pe bakan naa ni ọrọ ri nigba to yẹ ki oun lọ si ilu London, ti iwe irinna Passport oun si lo ọdun marun lọwọ eeyan kan, koda, o ni o bajẹ sọwọ ẹni naa.

Àkọlé fídíò, Wùnmí Toríọlá: Toyin Abraham kìí se ọ̀gá mi nínú tíátà

Bi ọna Mecca se la fun mi ree lẹyin aisan ọdun mẹta - Abija

Abija ni bi ọdun mẹta sẹyin ni oun se aisan kan to lagbara, koda gbogbo aye lo gbọ nipa rẹ amọ ni kete ti ara oun n bọ pada sipo, ni ọna la fun oun.

"Redio Ayefele ni Ilumọọka Presenter ti pe mi fun ifọrọwanilẹnuwo, to si fi owo ọkọ ransẹ si mi amọ mo na owo naa jẹun ni, ti n ko si ka ipe rẹ si.

O tun pe mi lẹẹkeji, to si tun fi ẹgbẹrun marun naira ransẹ bii owo ọkọ, ti mo si lọ. Lẹyin eto naa ni obinrin kan ti wọn pe no Alhaja Keromylee pe mi.

O fun mi ni ẹgbẹrun lọna aadọta naira, to si tun leri lati ran mi lọ si Mecca nigba to gbọ pe n kii se Alhaji."

Abija salaye pe oun ko ka ileri naa si, ti oun ko si fi ọkan si tabi sọ fun ẹnikẹni pe oun fẹ lọ si Mecca\.

O ni koda, oun ko sọ fun iyawo oun nile titi di igba ti wọn ni kawọn wa fun idanilẹkọ ati gbigba ẹru tawọn n ko lọ.

"Asiko yii mni mo ke si aya mi, ta si jọ lọ sibi idanilẹkọ naa, ibẹ si lo ti mọ pe mo fẹ lọ Mecca eyi to fa ija nla, diẹ si lo ku ki aarin wa daru."

Àkọlé fídíò, Bọlanle Ninalowo: Ọ̀rẹ́ lásán àti olóore mi ni Mercy Aigbe

Ajileye se adura ni Mecca pe ki Ọlọrun gba gbogbo oore to se fun mi

Abija tun tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe nigba ti oun de Mecca, ni Alfa kan to mọ oun ati Ajileye sọ fun oun pe ibẹ ni ọga oun ti tọrọ lọwọ Ọlọrun pe ko gba gbogbo oore to se fun oun.

"A se ẹsẹ ti mo sẹ Ajileye, o gbe de Mecca. Alfa kan sọ fun mi pe nibiyi ni ọga mi ti gbadura si Ọlọrun pe gbogbo oun ti Ọlọrun se fun mi lati ara oun, eyi to n dun mi ninu, ni ki Ọlọrun gba lọwọ mi.

Alfa naa ni isẹ kan soso ti ọga mi se ni Mecca ree lọdun naa, ti ko si ba wọn kopa ninu isẹ yoku mọ titi to fi pada wale."

Ẹsẹ mi da ninu ijamba ọkọ, mo wa nilẹ fun ọdun meji abọ:

Alhaji Tajudeen Oyewole tun mẹnuba ohun ti oju rẹ ri lọdun 2007 lasiko to ni ijamba mọto, eyi to da gunlẹ fun ọdun meji ati aabọ.

"Location ni mo ti n bọ, nibi ta ti lọ ya fiimu mi ti akọle rẹ n jẹ Ibinu Abija, mo ko ijamba ọkọ nigba ta n pada sile, ti ẹsẹ mi si da.

Ọdun meji aabọ ni mo lo nilẹ lẹ, lai le rin tori ẹsẹ mi ti da. Sinima Ibinu Abija naa ko si tii jade titi di oni, mo sẹsẹ tun fẹ gbe sita ni."

Àkọlé fídíò, hhhhhh

Emi ati ọga mi si dijọ se papọ bii ti tẹlẹ, ko to ku

Alhaji Tajudeen Oyewole wa kede pe oun ati ọga oun pari aawọ aarin awọn, ko to di pe o jẹ Ọlọrun nipe.

O ni oun ti dari gbogbo ẹsẹ ti ọga oun sẹ oun jin in, ti awọn si pada rẹ pada.

"Ajileye pada pe mi lati wa kopa ninu fiimu rẹ ko to jade laye, ti n ko si ka ẹsẹ kankan si lrun, nitori pe ẹgbọn lo jẹ si mi, ta si sun mọ ara wa pẹki pẹki.