Ibrahim Chatta: Èmi ò gbìmọ̀ràn láti gbẹ̀mí ara mi o, ohun tó ṣẹ̀lẹ̀ ni pé - Ibrahim Chatta

Oríṣun àwòrán, screenshot/Ibrahim Chatta/instagram
Gbajumọ oṣere tiata, Ibrahim Chatta ti sọ pe ko si iku loju oun bẹẹ loun o si gbimọran ati gba ẹmi ara oun.
O ni awọn idojukọ ti oun ba pade lẹnu lọwọlọwọ yii lo jẹ ki oun fi kigbe sori ayelujara pe inu iporuru ọkan loun wa.
Ni ọjọ Abamẹta ni eekan oṣere tiata naa fi atẹjade kan si oju opo Instagram rẹ pe nnkan o ri bi oun ṣe fẹ ko ri lwọ yii afi ki Eduwa o ṣaanu oun.
"Olọrun jọwọ. Mo ti n gbe ninu iporuru kan tipẹ bayii, ti mo si n ṣe bii ẹni pe gbogbo nnkan lo danmọran fun mi. Ni bayii, inu iporuru ọkan ni mo wa. Oluwa, jọwọ gba mi."
Eyi mu ọpọlọpọ awọn ololufẹ rẹ lati kigbe sita beere pe ki gan lo n ṣẹlẹ?
Ọgọrọ atẹjiṣẹ lo wọ tẹle atẹjade ori Instagram yii lẹyin ti gbogbo wọn si n kii pe ko rọra ṣe ko si mọkan.
Lara awọn to fi atẹjade ranṣẹ sii ni a ti ri awọn oṣere akẹgbẹ rẹ bii Wumi Toriola, Kẹmi Afọlabi Adeṣipẹ, Yewande Adekọya Abiọdun, Itẹlẹdicon, Ayọ Ọlaiya, Bimbọ Akinsanya, Oyin Elebuibon, Woli Arole ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Amọ, lẹyin bii wakati mejidinlaadọta ni eekan oṣere naa tun b sori oju opo Instagram rẹ lati dupẹ fun ifẹ ti awọn eeyan kaakiri agbaye fi han an lori iṣẹlẹ naa.
O ni inu oun dun pupọ bi awọn eeyan ṣe kan si oun gẹgẹ bi mọ iya wọn lasiko iporuru ọkan ti oun ni naa.

Oríṣun àwòrán, Screenshot/Ibrahim Chatta/instagram
O fi kun un pe oun ti n bọ kuro lọwọ iporuru ọkan ati ibanujẹ naa
O ni ọjọ buruku ni oru ọjọ Satide ọjọ kejidinlogun oṣu kejila dun 2021 si ọjọ Aiku ọjọ kọkandinlogun oṣu kejila.
Ati pe saa kan ni ninu aye oun ti oun si mọ pe yoo kọja lọ gẹgẹ bi ọpọ awọn to kan si oun ṣe gba oun ni amọran.
Ibrahim Chatta ni ibi ti ohun to ṣẹlẹ naa ka oun laya de, koda ọkan lara awọn ẹṣin funfun ti oun fẹran ni ọgba oun tilẹ tun jalaisi ni ọjọ Aiku ti oun ko si tilẹ mọọ lara.
Ṣe lootọ ni pe Ibrahim Chatta fi dan ifẹ awọn ololufẹ rẹ wo ni?
Lasiko ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, awọn kan n woye pe boya ṣe ni gbajumọ oṣere naa fẹ fi da bi awọn eeyan ṣe nifẹ rẹ si wo ni tabi boya oun pẹlu fẹ di ẹni taye yoo maa sọ tabi jẹ ọrọ rẹ lẹnu fun awọn asiko kan.
Ṣe ọpọ iṣẹlẹ lagbo amuludun lẹnu lọwọlọwọ yii lawọn eeyan n fi ero gbe pe awọn ilumọọka kan mọọmọ n ṣe awọn nnkankan lati jẹ ki awọn naa di ọmọ ti wọn n sọ nigboro.
Amọṣa, Ibrahim Chatta ti ni ko si ohun to jọọ ati pe ibanujẹ to gba oun mu naa kii ṣe ṣereṣere rara nitori pe ibi to ka oun laya de, ohun ko tilẹ roju raye awọn oun to ṣe pataki ninu igbesi aye oun.

Oríṣun àwòrán, Ibrahim Chatta/instagram
Njẹ Ibrahim Chatta gbero ati gbẹmi ara rẹ gẹgẹ bi awọn eeyan kan ṣe n ro?
Ọpọ lo n woye pe pẹlu ọrọ ti agba oṣere naa sọ sita yii, o ṣeeṣe o ko fẹ ṣe ara rẹ leṣe tabi gba ẹmi ara rẹ gẹgẹ bi awọn eeyan kan ti wọn pariwo iporuru ati ibanujẹ kan sita maa n ṣe.
Amọ, Ibrahim Chatta ti ṣalaye pe oun ko figba kankan gbaa lero lati gbẹmi ara oun rara ati rara ni.
"Gbigbẹmi ara mi ko tilẹ si nibẹ rara. Ti mo ni ẹyin ololufẹ mi lẹgbẹ mi."
O ni nnkan to ṣe oun n dun oun lọpọ ṣugbọn oun ko gbero ati gbẹmi ara oun.


















