Road accident: Èèyàn mẹ́rin kú nínú ìjàmbá bọ́ọ̀sì tó tàkìtì lópòpónà Eko si Ibadan

Oríṣun àwòrán, Others
Eeyan mẹrin ti jẹ Ọlọrun nipe nigba ti mẹrinla mii farapa ninu ijamba ọkọ bọọsi to takiti ni opopona mọrosẹ ilu Eko si Ibadan to ṣẹlẹ lọjọ Aiku.
Ajọ ẹṣọ oju popo, FRSC ni agbegbe Lufwape ni ijamba naa ti waye ni bii ago mẹta abọ ọsan lọjọ Aiku.
Ajọ FRSC ṣalaye pe ogun eeyan lo wa ninu ọkọ akero naa ninu eyi ti mejila jẹ ọkunrin ti mẹjọ si jẹ obinrin.
- "Àwọn agbésùmọ́mí ló ń ṣe ìjọba lé wa lórí, kìí ṣe ìjọba Nàìjíríà tí Buhari ń darí"
- Ilé ẹjọ́ ti pàṣẹ tuntun fún ọ̀ga ọlọ́pàá Nàìjíríà lórí Rahmon Adedoyin tí Timothy Adegoke kú sí ilé ìtura rẹ̀
- Ọkùnrin kan pokùn so lẹ́yìn tó pàdánù N150,000 owó iléèṣẹ́ sórí tẹ́tẹ́
- Wo orílẹ́èdè tó fẹ́ fi òfin de sìgá mímú fún ìran ọmọ wọn tó ń bọ̀
- Irọ́ ni ìròyìn tó sọ pé àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ kò níì tètè rí owó oṣù Kejìlá gbà
A gbọ pe ṣadeedee ni ọkọ bọọsi akero ọhun bẹrẹ si ni takiti lori ere ti o si lọ kọlu tirela Mack kan loju popo.
Ẹṣọ ajọ FRSC ṣalaye pe lojiji ni tirela Mack bọ siwaju bọọsi akero naa eyi ti dẹrẹba ọkọ naa ko le ri daduro mọ tori ere to n ba bọ.
Agbẹnusọ ajọ FRSC nipinlẹ Ogun, Florence Okpe ni wọn ti gbe awọn to farapa ninu ijamba ọkọ naa lọ si ile iwosan Idera Hospital niluu Sagamu fun itọju nigba ti wọn ko oku eeyan mẹrin ninu ọkọ naa sí mọṣuari.
Ajọ FRSC wa rọ awọn awakọ pe ki wọn rọra sare loju opo tori ẹmi o laarọ.
- Ọmọ ogun méjì rí ẹ̀wọ̀n he lẹ́yìn tí wọ́n yìnbọn pa olùfẹ̀hónúhàn lọ́dún 2020
- Tọkọ-taya dèrò àtìmọ́lé lẹ́yìn tí wọ́n ta ọmọ wọn tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò ju oṣù kan lọ ní ₦50,000
- Ọmọ ogun méjì rí ẹ̀wọ̀n he lẹ́yìn tí wọ́n yìnbọn pa olùfẹ̀hónúhàn lọ́dún 2020
- Èèyàn méjì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Jesu gún pasítọ̀ ìjọ RCCG pa nínú ṣọ́ọ́ṣì l'Eko
- Wo ààrẹ orílẹ̀-èdè tó ṣiṣẹ́ awakọ̀ "taxi" kó tó di ààrẹ
- Àwọn ọlọ́pàá ti gbé tọkọtaya tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàn pé ó fi ọmọ oṣù mẹ́fà dí gbèsè tó fi kú










