Èèyàn méjì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Jesu gún pasítọ̀ ìjọ RCCG pa nínú ṣọ́ọ́ṣì l'Eko

Babatunde Dada

Oríṣun àwòrán, Babatunde dada

Awọn afurasi ọmọ ita ti pa pasitọ ijọ Redeemed Christian Church of God kan to wa ni Festac Town, nijọba ibilẹ Amuwo-Odofin, nipinlẹ Eko.

Iroyin sọ pe inu ṣọọṣi RCCG Chapel of Resurrection ọhun ni wọn pa Pasitọ Babatunde Dada si, lọjọ keji, oṣu Kejila, ọdun 2021.

Gẹgẹ bi iwe iroyin The Punch ṣe sọ, awọn meji kan to ṣẹṣẹ fi aye wọn fun Jesu ninu ijọ naa lo pa a .

Iroyin sọ pe ọjọ Aiku to ṣaaju ọjọ naa, ni awọn ọdọ mejeeji jade sita lasiko ti ijọsin n lọ lọwọ pe awọn fi aye awọn fun Jesu.

Koda, ọjọ ni ọjọ akọkọ ti wọn lọ si ṣọọṣi naa.

Àkọlé fídíò, KieKie

Lẹyin ti wọn jade, ti wọn fi aye wọn fun Jesu, ni awọn alaṣẹ ile ijọsin naa fun wọn ni ile gbigbe ninu ọgba ile ijọsin ọhun, nitori wọn ni awọn ko ni ibi ti awọn n gbe.

Ko si ti i to ọsẹ kan ti wọn ti n gbe inu ọgba ile ijọsin, ni iroyin sọ pe wọn gún pasitọ pa.

Àkọlé fídíò, Mama Deeper Life Ondo

Aya oloogbe naa, Bose Dada sọ fun awọn akọroyin pe ọkọ oun ni oluṣiro owo ati alamojuto ni ọfiisi ile ijọsin naa, to si tun jẹ oluṣọ agutan ni ṣọọṣi RCCG miran, Chapel of Glory, to wa ni Agboju.

Ko ti i pẹ ti tọkọtaya naa ṣe igbeyawo, ti iyawo si wa ninu oyun.

Àkọlé fídíò, Ìdí tí Tòmátò ẹ̀sà kò ṣe dára fún ìlera yín; wo àwọn kókó márùn-ún yìí

Bakan naa ni mọlẹbi rẹ kan, Abolarinwa Olatunbosun sọ fun iwe iroyin Punch pe lẹyin ti Pasitọ Dada gba owo ni banki ni wọn pa a.

O ni o lọ gba owo ni banki, to si pada si ile ijọsin naa.

Àkọlé fídíò, Teslim Thunder Balogun: Àwọn oní-Tomato, aláta, oníṣu á máa kó ọjà wọn lọ́fẹ̀ẹ́ sínú ọkọ̀

Nibi to ti n sinmi ni aja kinni ṣọọṣi, ni wọn sọ pe awọn meji to ṣẹṣẹ fi aye wọn fun Jesu ọhun wọle lọ ọ ba loke, ti wọn si fọ ni ori, gun ni nkan pa ki wọn o to gbe owo lọ.

Aburo oloogbe to ba BBC sọrọ, Akin Dada, ni ẹgbọn oun ni ṣọọbu kan nitosi ṣọọbu naa, nibi to tun ti n ṣe iṣẹ agbafọ aṣọ.

O ni koda o tun gba awọn ọkunrin meji ọhun sibẹ lati ma a ba ṣiṣẹ.

Àkọlé fídíò, FUTA First Class Twins

Bakan naa lo ni ọwọ ti tẹ ẹnikan lara awọn afurasi naa nilu Ilorin to salọ.

Ọkan lara awọn foonu oloogbe ti wọn mu, ni awọn ọlọpaa fi tọpasẹ rẹ.

Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Adekunle Ajisebutu to fidi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC sọ pe iwadii ti n lọ lori iṣẹlẹ naa.