RCCG pastor gunned down: Ọmọ ìjọ RCCG f'ara gba ìbọn lóríi pẹpẹ níbi ìsìn ìkómọ, ó gba ibẹ̀ kú!

Oríṣun àwòrán, NPF
Iroyin to n tẹ wá lọ́wọ́ báyìí sọ pé ọmọ ìjọ Ìràpadà, Redeemed Christian Church of God, King of Kings Parish tí dagbere fàyè nígbà tí àwọn agbebon yinbon bàa lórí pẹpẹ.
Ileese Ọlọpaa Ìpínlẹ̀ Eko sọ fún BBC Yoruba pé lootọ ni ó ṣẹlẹ̀ tí wọn sì ti fi to àwọn létí.
Ẹwẹ, ileese Ọlọpaa ni àwọn ko leè fìdí rẹ múlẹ̀ bóyá pasito to wá lórí ìjọ náà ni tàbí ọmọ ìjọ tàbí òṣìṣẹ́ ìjọ.
- N8M tán yán-yán ni Abba Kyari gbà lọ́wọ́ Hushpuppi - FBI Amẹríkà
- Àlááfíà ni Bola Tinubu wà - Sanwo-Olu
- Tóò bá ń dédé sọ fótò tàbí fídíò nù lórí fóònù, Watssap ló gbé ètò tuntun jáde ó!
- Ilé ẹjọ́ fún Sunday Igboho ní ànfààní láti rìn ní òmìnira láàrin ìlú
- Ilé ẹjọ́ ti gba béèlì àwọn èèyàn méjìlá tí DSS mú nílé Sunday Igboho
- UAE yí ìpinnu padà,ìrìnàjò bàálù bẹ̀rẹ̀ padà láàrin Nàìjíríà àti Dubai
Iroyin ni lásìkò tí wọn ń ṣe ìsìn isọmọlorukọ lọwọ ni àwọn agbebon kan ṣe iṣẹ́ aburu yìí.
Bolanle Ibrahim, wá lórí pẹpẹ ni ìlú Madan ni ijoba ìbílẹ̀ Ikosi Ketu nigba ti iṣẹlẹ náà wáyé.
Oloogbe ìránṣẹ́ Ọlọ́run yìí ń gbàdúrà fún àwọn kan lásìkò ìkómọ ọmọ tuntun ni àwọn aráabí dédé ja wo inú Ṣọ́ọ̀ṣì.
Iroyin kan sọ pé ṣe ni wọn wọ Ibrahim jáde síta láti inú Ṣọ́ọ̀ṣì tí pasito àgbà kan nínú ìjọ si gbá tẹ́lẹ̀ wọn tó ń béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ wọn.
A gbọ́ pé àwọn apaayan náà dojú kọ pasito tó ń bí wọn lejọ yii wọn sì padào faabọ sórí ẹni tí wọn wọ jáde.
Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ́n olóògbé náà ṣe sọ tí ìròyìn kan gbé e, Arábìnrin Justina Alebiosu ni dájúdájú wọn dìídì rán wọn láti pá àbúrò òun ni.
Alebiosu sọ fún ìwé ìròyìn Telegraph pé kí wọn tó paa, wọn fi àwòrán ara rẹ hàn láti fi aridaju hàn pé òun gangan ni àwọn fẹ pá.
"Lóòótọ́ inú ẹṣin Mùsùlùmí ni wọn bí wá si sugbọn a yí padà si ẹṣin Kristẹni. Èrò mi ni pé àbúrò mi dá owo pọ pẹ̀lú èèyàn kan".
Obìnrin náà ni àwọn apaayan náà tún da ẹru bolẹ pé àwọn yóò pa ọmọ ìjọ kankan tó bá gbiyanju àti bí àwọn lẹjọ ó sì bẹ àwọn Ọlọpaa pé kí wọn dá òkú àbúrò òun silẹ fáwọn.
Kudirat to jẹ iyawo olóògbé ni ọkọ òun wà nínú awẹ lọwọ lọ́jọ́ tí wọn pá a yí, bù ẹnu atẹ lu ìròyìn to sọ pé ọkọ rẹ wà nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn.
Ẹwẹ, àlùkò ro Ọlọpaa Ìpínlẹ̀ Eko, Muyiwa Adejobi ni àwọn n ṣèwádìí kíkún lórí iṣẹlẹ náà "torí a ti ní àṣírí ọna ti a le tọ nínú ìwádìí náà".
- Kí ló mú kí géńdé múra bí obìnrin láti bá ọ̀rẹ́bìrin rẹ̀ kọ ìdánwò?
- Ẹ fún wa ní oṣù márùn ún láti fí lé àwọn ajínigbé Fulani kúrò nínú igbó- Olórí Fulani
- Olórí ọ̀dọ́ ẹgbẹ́ PDP sọ àbùkù ọ̀rọ̀ sí Ààrẹ Buhari àti SGF, ẹ̀wọ̀n jàntò ló rí he!
- Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ "baby" bóo ṣe jẹ́ kí ọkùnrin míì gbẹ́nu sí ìdí, ọyàn rẹ nílé Ẹlẹ́gbọ̀n-ọ́n àgbà BB Naija - Ọkọ Tega














