UEA lift travel ban: Wo nkan tó yẹ kí o mọ̀ báyìí tí ìrìnàjò bàálù bẹ̀rẹ̀ padà láàrin Nàìjíríà sí Dubai

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orileede UAE ti gbẹsẹ kuro lori ofin to de lilọ bibọ baalu lati Naijiria ati orileede mẹwa mii.
Ajọ to n ri si iṣakoso iṣẹlẹ pajawiri ni Naijiria,NCEMA, lo kede ọrọ yi.
Ikede yi n waye lẹyin oṣu meji gbako ti wọn ko fi faaye gba baalu Naijiria kankan lati wọ ilẹ naa tori Covid-19
Pẹlu ikede yi, lati ọjọ Karun oṣu Kẹjọ arinrinajo to ba ti ni iwe moyege ayẹwo Covid-19 le kọja ni papakọ ofurufu UAE.
Loṣu kẹfa ọdun yi ni ikede to fofin de irinajo laarin Naijiria ti UAE kọkọ desi eti igbọ araalu.
Amọ bayi,NCEMA ti sọ loju opo wọn ni Twitter pe awọn arinrinajo to ba ti gba iwe ẹri moyege ayẹwo Covid-19 laarin ọjọ mẹta yoo le gba papakọ ofurufu UAE kọja.
''Wọn tun gbọdọ ṣafihan ẹri ibi ti irinajo wọn yoo kangun si plu pe awọn papakọ UAE yoo fi aaye sọtọ fawọn arinrinajo to n gba papakọ ofurufu wọn kọja''
- Wo àwọn ìlànà tuntun ti o gbọdọ tẹlèé rèé ki ó to le wọkọ̀ òfurufú lọ sókè òkun
- Kí ló ń sọ ọmọ Nàìjíríà d'èrò ilẹ̀ òkèèrè tí ìjọba kò ronú sí?
- Wo àmí ẹ̀yẹ tí Abba Kyari tí gba gẹ́gẹ́ bí ògbóǹtagìrì ọlọ́pàá kí wọ́n tó fi ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu kàn án
- Njẹ́ o mọ̀ pé bíi ọdún 700 sẹ́yìn ni wọ́n ti ń bọ Osun-Osogbo? Mọ̀ síi nípa ìtàn ojúbọ̀ nàá
- Ìjọba Amẹ́ríkà ti kó abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 mílíọ̀nù mẹ́rin fún Nàìjíríà
Lara awọn orileede mii ti ayipada ofin yi de ba ni India, Pakistan, Sri Lanka, Uganda, Vietnam ati South Africa.
Awọn to ku ni Afghanistan, Indonesia, Bangladesh ati Nepal
Ohun ti ikede UAE yi tunmọ si fun orileede Naijiria
Igba akọkọ kọ ni yi ti UAE ko ni gba ki awọn baalu wọn wa si Naijiria lati gbe arinrinajo tabi ki ti Naijiria wọ papakọ ofurufu wọn.
Lọjọ Kẹrin oṣu keji 2021 ni Emirates Airline gbegi dina ki awọn baalu wọn maa kero lati papakọ ofurufu Eko ati Abuja lọ si Dubai.
- "Tinubu ò kú o, àlááfíà ló wà, àmọ́..."
- Ọmọ Ọba Dubai yóò san owó ìtọ́jú ọmọ Nàìjíríà tó bí ìbẹrin sí Dubai tí kò sí rówó san
- Àwọn òbìnrin tó ń ya fọ́tò ìhòhò ara wọn níwájú ilé kó sí gbaga ọlọ́pàá!
- Wo àmí ẹ̀yẹ tí Abba Kyari tí gba gẹ́gẹ́ bí ògbóǹtagìrì ọlọ́pàá kí wọ́n tó fi ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu kàn án
- Irọ́ ní ò, Adeyinka Daniel, akẹ́kọ̀ọ́ FUTA tí kú kí wọ́n tó gbé e wá sí ''health Centre'' FUTA
- Ìwádìí ní gómìná New York fipá k'ẹnu ìfẹ́ sáwọn obìnrin, Biden rọ̀ ọ́ pé kó fipò sílé
Aṣẹ yi ko sẹyin bi igbimọ to n mojuto ọrọ Covid-19 ni Naijiria ṣe kọ lati tẹle ilana ti wọn gbe kalẹ fun ayẹwo arinrinajo.
Gẹg bi Emirates ti ṣe sọ, wọn ni awọn yoo''ṣafihan ilana tuntun loju opo arinrinajo laipẹ''
Ni bayi, awọn arinrinajo Naijiria lọ si Dubai :
- gbọdọ ti gba iwe ẹri ayẹwo Covid-19 ti wọn ṣe laarin ọjọ meji ṣaaju irinajo. Eyi ko kan awọn ọmọ ilẹ UAE
- Arinrinajo nilati ṣafihan iwe ẹri moyege to ni ami idanimọ QR Code to gba lati ile ayẹwo ti ijọba Naijiria fontẹ lu
- Gbogbo arinrinajo gbọdọ ṣe ayẹwo Covid-19 kan kete ti wọn ba balẹ si papakọ ofurufu Dubai
- Awọn arinrinajo to ṣi n tẹsiwajuni lati tẹle gbogbo ilana ibi ti wọn yoo pari irinajo wọn si.















