Tokyo 2020: Odunayo Adekuroye: Ṣàǹgbá fọ́! Ìrètí Nàìjíríà fún góòlú, Adekuroye pòfo nínú ìjànkadì ní Tokyo 2020

Daniel

Oríṣun àwòrán, @Daniel Igali facebook

Gbajugbaja ajijakandi, Odunayo Adekuroye ti ọpọ eeyan ti ni ireti pe oun ni yoo gba goolu fun Naijiria ninu idije Olympiki Tokyo 2020 fidi rẹmi lairo tẹlẹ.

Anastasia Nichita ọmọ orilẹ-ede Moldova lo fi iya jẹ Adekuroye niluu Tokyo.

Adekuroye lo kuku n kọkọ n ṣiwaju ninu ijankadi ọhun, koda ami ayo mẹjọ si meji ni Adekuroye fi n ṣagba Nichita.

Ṣadeedee kan ni nkan yi biri, ti Odunayo ṣubu loju ija.

Iṣubu yii gan an lo mu ki Nichita bori ninu ija ipele ẹlẹni mẹrindilogun ọhun.

Àkọlé fídíò, Esabod, Sunday Igboho: Kò burú bí Igboho ṣe wà lẹ́wọ̀n báyìí,ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí i ti aláboyún

Amọ, ireti diẹ sí wa fun Adekuroye lati gba ami ẹyẹ baba tawọn oloyinbo n pe ni "bronze."

Ṣugbọn to wà nibẹ ni pe Nichita to fẹyin Odunayo gbalẹ gbọdọ wọ Ipele aṣekagba ni Tokyo.

Àkọlé fídíò, Tunde Bakare journey in life: Bàbá bàbá mi ni Lèmọ́mù àkọ́kọ́ ní Sodeke Abeokuta ṣùgbọ́n..

Ẹwẹ, Blessing Oborududu gbarada ninu ijankadi ti ẹ.

Koda, ami ẹyẹ fadaka ni Oborududu gba nigba ti ọmọ ilẹ Amẹrika, Tamyra Marianna Mensah fẹyin rẹ gbalẹ pẹlu ami ayo mẹrin sí ẹyọkan ninu ijankadi 68kg.

Àkọlé fídíò, Ọ̀pẹlọpẹ́ Ajá tí Ifa ní kí a fi ṣètùtù ní Ekiti ní 1942 ni kò jẹ́ kí ìjàmbá náà pọ̀ jù- Ol