Blessing Okagbare at Tokyo 2020 Olympics: Àjọ eré ìdárayá lágbáyé lé Blessing Okagbare kúrò ní Tokyo 2020 Olympics

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ajọ to nboju wo ayẹwo ogun lilo laarin awọn elereidaraya ti paṣẹ lọ rọọkun nile naa fun eekan elere ije ọlọgọrun mita(100 meters) ati igba mita ( 200 meters) ọmọ Naijiria ni, Blessing Okagbare nibi idije Tokyo 2020 Olympics to n lọ lọwọ bayii lorilẹede Japan.
Ọpọ ọmọ Naijiria ti inu wọn n dun lọjọ Ẹti lori iroyin pe elere ije ọmọ Naijiria meji lo moribọ wọ ipele to kangun si aṣekagba ere ije onimita ọgọrun ni idunnu naa ko pẹ fun pẹlu iroyin pe ayẹwo fihan pe Okagbare to jẹ ọkan ninu awọn meji naa lo ogun amuṣẹya HCG eleyi to jẹ ara awọn ogun ti ajọ naa fi ofin de pe kawọn elere idaraya jina sii.
- Kí ni àwọn ẹ̀sun tuntun tí ìjọba ìpínlẹ̀ Kaduna tún gbé dìde tako Ibrahim El-zakzaky?
- Ikú Tope AjogbaJesu, ohun tí a mọ̀ nípa ohun tó ṣokùnfà ikú rẹ̀ nìyí
- 'Lábẹ́ òfin àjọ ECOWAS, kó ṣééṣe kí Benin Republic jọ́wọ́ Sunday Igboho fún Nàìjíríà'
- Àwọn ohun mẹ́rin tó yẹ kí ẹ ko mọ nípa Ramoni Igbalode tí gbogbo ayé ń pè ní Hushpuppi
- Pàá lẹ́ẹ̀kínní, pàá lẹ́ẹ̀kejì, Germany d'áṣọ ìyà fún D'Tigers Nàìjíríà lẹ́yìn ìkọlù Australia ní Olympics
- Àwọn eléré ìdárayá ilẹ̀ Afrika tó yẹ kí o wò
Bi ẹ ko ba ni gbagbe lọjọ diẹ sẹyin lawọn ajọ yii kan naa yọ awọn elere idaraya ogun bi ẹni yọ jiga lori ẹsun pe wọn eto ayẹwo ogun oloro ti wọn ṣe fun wọn ko kun oju iwọn to yẹ fun elere idaraya to fẹ kopa ni idije agbaye bii Olympics. Mẹwaa ninu awọn elere idaraya naa lo jẹ ọmọ orilẹede Naijiria.
Blessing Okagbare jẹ ọkan gboogi ireti orilẹede Naijiria lati ri ami ẹyẹ gba ni idije Tokyo 2020 Olympics.
Ni idije Olympics ti ọdun 2008 ni Beijing lorilẹede China, Okagbare gba ami ẹyẹ Fadaka lẹyin to ṣe ipo keji ni idije ilẹ fifo ti a mọ si Long jump. Lẹyin eyi lo tun gba ami ẹyẹ miran ni idije ilẹ fifo ti a mọ si Long jump yii kan naa ati ere ije igba mita (200 meters) ni idije ere idaraya agbaye, World Championships lọdun 2013.












