AjogbaJesu Twins: Ọgbẹ́ inú, Ulcer ló pa Tope, ọ̀kan lárá àwọn ìbejì AjogbaJesu - Amágbálẹ́gbẹ́ rẹ̀

Awọn ibeji AjogbaJesu

Oríṣun àwòrán, Ajogbajesu instagram

Tọpẹ, ọkan lara awọn ibeji Ajogbajesu ti jade laye. Akọrin ẹmi naa jade laye lọjọ Ẹti nilu Ibadan

Gẹgẹbi ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ rẹ ṣe sọ fun BBC News Yoruba, ọgbẹ inu, iyẹn Ulcer lo ṣokunfa iku rẹ.

Gẹgẹ bi alaye ti amugbalẹgbẹ rẹ naa ṣe fun BBC News Yoruba, o ti to ọjọ melokan bayii ti akọrin naa ti n ba aisan ọgbẹnu inu Ulcer faa.

Àkọlé fídíò, Bí ìjọba bá kọ̀ tí kò ṣèdájọ́, tí Ọlọ́pàá kọ̀ pé àwọn kọ́ ló paá, ẹni tó pa ọmọ mi, náà máa ...

O ni nigba ti awọn amugbalẹgbẹ rẹ kan de ile rẹ ni owurọ ọjọ Ẹti, ọgbọn ọjọ oṣu keje ọdun 2021 ni wọn baa lori ibusun to wa ti gbogbo ara rẹ ti le. Eyi lo mu ki ẹnikeji rẹ, iyẹn Kehinde o paṣẹ ki wọn tete maa gbe lọ si ileewosan.

"Nigba ti wọn fi de ileewosan Ọyọmesi nilu Ibadan ni wọn rii pe ko si ẹjẹ lara wọn mọ. Nitori ọgbẹ inu ti wọn ni, o ti wọ aga ara wọn gan, nibẹ ni wọn dakẹ si ni owurọ yii"

Aisan ọgbẹ inu yii lawọn dokita ni o ti wọ agọ ara akọrin ẹmi naa eleyi ti ko si jẹ ko si ẹjẹ pupọ lara rẹ mọ.

Ọmọ mẹta ati iyawo ni akọrin naa fi silẹ saye lọ.

Tope AjogbaJesu jáde láyé!

Awọn ibeji AjogbaJesu

Oríṣun àwòrán, other

Ọkan lara awọn ibeji AjogbaJesu, ti orukọ rẹ n jẹ Tọpẹ ti jade laye.

Tọpẹ AjogbaJesu gẹgẹ bi ọpọ ṣe mọọ jẹ ọkan lara awọn akọrin meji ninu ẹgbẹ orin AjogbaJesu Twins.

Orin Kristẹni ni wọn yan laayo lasiko ti irawọn wọn jade pẹlu ọwọ 'tungba'ti wọn fi nkọrin ẹmi tiwọn.

Ọkan lara awọn to sun mọ olorin naa sọ pe owurọ ọjọ Ẹti lo jade laye.

Àkọlé fídíò, Igi Ọ̀pẹ abàmì tó dá ní orí 42 l'Ekiti rèé o, 'bí mo ṣe ríi l'orí mi ń dìde fììì'