Ibadan Shoprite shooting: Èyí ni bí wọ́n ṣe pa akẹ́kọ̀ọ́ Poly Ibadan tí wọ́n sì sọ òkú rẹ̀ sí orí àkìtàn

Oríṣun àwòrán, other
Ni alẹ ọjọ Aiku ni iroyin iṣẹlẹ buruku kan jade pe ọlọpaa kan ti yinbọn pa ọdọkunrin akẹkọjade ileẹkọ gbogbnṣe Poly Ibadan kan t orukọ rẹ n jẹ Akintunde Babatunde.
Iroyin naa sọ pe nibi nnkan ọmọkunrin rẹ ni ibọn ti ba a.
Nnkan bii ọsẹ mẹrin sẹyin ni ọmọdekunrin naa kẹkọjade ni ileewe giga naa ki o to fafa gbọta ọlọpaa gẹgẹ bi awọn eeyan ṣe sọ.
Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn ṣọ pe awọn ọlọpaa yinbọ fun ọdọkunrin naa lasiko ti ko fẹ fi jọwọ ara rẹ silẹ fun ọlọpaa ti wọn ko wa ṣọ ọgba ile itaja nla naa.
- A kò bèrè fún owó kankan lọ́wọ́ Hushpuppi - Abba Kyari dá èsì padà fún ileẹjọ́ US
- Wo iye èèyàn tó dèrò ọ̀run lásìkò ìkọlù ẹgbẹ́ Shi'ite àti àwọn agbófinró
- Mo gbà pé mo jẹ̀bi gbogbo ẹ̀sùn wíwọ́ké àti kíkó owó pamọ́ lọ́nà àìtọ́ - Hushpuppi
- 'Nàiìjíríà ti pèsè ''Private jet'' tí yóò gbé Igboho padà sílé láti Cotonou sílẹ̀ kí ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀'
Iroyin abẹle tun sọ pe nibi ti Akinọla Babatunde ti n mu ohun ti wọn fura si pe o jẹ igbo ni wọn ti baa.
Eeyan kan ti ọrọ naa ṣoju rẹ ni pe bi o ṣe n gbiyanju lati sa mọ awọn ọlọpaa naa lọwọ ti o si n gbiyanju lati fo odi to yi ile itaja naa ka ni ọkan lara awọn ọlọpaa naa yin in ni ibọn.
Amọṣa, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti yọ ọwọ ọlọpaa kuro ni bi Akinọla ṣe ku.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ, Adewale Oṣifẹsọ ni iya awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun ni o fa iku rẹ atipe iwadii ṣi n lọ lọwọ sii.
BBC News Yoruba se ibewo idile Akintola ninu Ibadan lati bawon kedun isele na, Baba Omo okunrin bawaso, woni awon le so boya awon olopa tabi awon elegbe okukun lo se iku pa Babatunde Akinola.
Waheed Akinola ṣalaye pe alabasọ oun ni Akinọla to ku naa ati pe awon si rira ni owurọ ọjọ ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.
Waheed Akinola so pe nigba to di ale ti awonko rii ni awon pe ero ibanisọrọ rẹ ti arakurin kan sigbe ipe naa pe "eni to ni phone ti ku si Palms mall"
Baba Akinola tesiwaju pe lesekese ni awon morile ibudo na ti awon si na oku omo awon ni ori akitan.
Oku Akinola Babatunde won ni siwa pelu awon olopa ipinle Oyo
Egbon Ologbe na BBC News soro pe oun igbagbo awon olopa lo se iku pa aburo oun.














