Hushpuppi gbà pé òun jẹ̀bi ẹ̀sùn kíkó owó pamọ̀ lọ́nà àìtọ́, ọmọ Nàìjíríà míì tó ń báa ṣiṣẹ́ rèé

Oríṣun àwòrán, Hushpuppi/Instagram
Hushpuppi sọ wi pe ọga ọlọpaa kan ni Naijiria ran oun lọwọ lati fi panpẹ ọba mu olubaṣiṣẹpọ to fẹ tu aṣiri rẹ.
Ileeṣẹ olotu idajọ lorilẹede Amerika, DOJ ni awọn ti fi panpẹ ọba mu awọn ọṃ Naijiria mẹta to lọwọ ninu bi Raymond Hushpuppi Abbas ṣe ji iye owo to le ni biliọnu kan naira lasiko ti wọn n lu jibiti lori ẹrọ ayelujara.
FBI ni awọn fi panpẹ ọba mu awọn mẹta na ni Ọjọ Kejilelogun, Osu Keje lasiko igbẹjọ to ni Hushpuppi lo ọna ẹburu lati gba owo lọwọ oniṣowo kan.
Orukọ wọn ni Yusuf Adekinka Anifowoshe, a.k.a. "AJ," 26, tọ n gbe ni Brooklyn, New York; Rukayat Motunraya Fashola, a.k.a. "Morayo," 28, to n gbe ni Valley Stream, New York ati Bolatito Tawakalitu Agbabiaka, a.k.a. "Bolamide," 34, to n gbe ni Linden, New Jersey.
Awọn mẹtẹẹta naa ni wọn yoo yọju si ileẹjọ ni ilu Los Angeles ni Ogunjọ, Osu kẹjọ, ọdun 2021. Ẹwọn ogun ọdun lo n duro de wọn ti wọn ba jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.
Oniṣowo ti wo.n lu ni jibiti naa aṃ ti wọn ko darukọ rẹ ni lo n gbiyanju ati kọ ileewe fun awọn ọmọde ni Qatar.
- Ẹbí gba ẹ̀mí ọmọdébìnrin kan nítorí ó wọ ṣokoto "jeans"
- Kí ni Ọ̀gágunfẹ̀yìntì Buratai ń ṣe ní Benin Republic, ìlú tí Sunday Igboho ti ń jẹ́jọ́?
- Àwọn ọ̀nà tí òfin tuntun CBN lórí Bureau De Change tí wọ́n gbé'gi lé ṣe kàn ọ́
- Olùwọ́de 47 nínú àwọn tí ọlọ́pàá kó ní ìwọ́de Yoruba Nation ti gba ìtúsílẹ̀ láhámọ́ ọlọ́pàá
Ninu atẹjade naa ti FBI gbe jade ni Hushpuppi ti jẹwọ pe lootọ ni oun jẹbi gbogbo ẹsun ti wọn fi kan an.
Bakan naa ni Hushpuppi sọ wi pe ọga ọlọpaa ni Naijiria ran oun lọwọ lati fi panpẹ ọba mu olubaṣiṣẹpọ to fẹ tu aṣiri rẹ.
Ninu owo ti Hushpuppi ji naa ni o ti ra aago ọwọ to to $230,000 eleyii ti Richard Mile RM11-03 se, to si fi si oju opo ikansiraẹni Instagram.
Bakan naa ni wọn fẹsun kan Hushpuppi pe o lo owo naa lati ra iwe igbelu ni orilẹede St. Christopher and Nevis island kontri, to si tun fi ṣe igbeyawo ofege, to si sanwo abẹtẹlẹ fun awon oṣiṣẹ ijọba ni St.Kitts.
Mo gbà pé mo jẹ̀bi gbogbo ẹ̀sùn wíwọ́ké àti kíkó owó pamọ́ lọ́nà àìtọ́ - Hushpuppi

Oríṣun àwòrán, Screenshot/Hushpuppi/
Ilumọọka ori atẹjisẹ Instagram, Ramon Abass ti gbogbo eniyan mọ si Hushpuppi ti sọ fun ile ẹjọ pe oun gba pe oun jẹbi ẹsun meji ti wọn fi kan.
Ẹsun naa to da lori igbimọ pọ lati kowo ilu pamọ lọna aitọ gẹgẹ bi ìwé kan tí BBC foju kan eyi ti agbẹjọro rẹ pẹlu sì sọ pé ìwé naa kii ṣe ayederu.
"Olujẹjọ naa ti yoo foju bale ẹjọ bayii lati bẹbẹ pe òun jẹbi ẹsun meji ti wọn fi kan oun ninu ipejọ orilede Amerika ati Ramon Olorunwa Abass ti wọn pe ni Case No. 2:20-CR-00322-ODW.
Ṣe ni Hushpuppi darukọ ọga ọlọpaa Abba Kyari nibi igbẹjọ pe oun fun un atawọn mii nileeṣẹ ọlọpaa ni owo abẹtẹlẹ. Amọ Abba Kyari ti fesi lori ayelujara rẹ pe A kò bèrè fún owó kankan lọ́wọ́ Hushpuppi - Abba Kyari dá èsì padà fún ileẹjọ́ US
"Wọn fẹsun kan pe oun pamọpọ lati kowo ilu pamọ lọna aitọ eyi to si lodi si ofin kejidinlogun ti U.S.C § 1956(h). " Bi iwe ile ẹjọ naa ṣe sọ.

Oríṣun àwòrán, USAO

Oríṣun àwòrán, USAO
Gẹgẹ bi iwe ẹsun ile ẹjọ to n ja rainrain yii ṣe sọ, Hushpuppi ṣe adehun pẹlu ile iṣẹ ti idajọ ilẹ Amẹrika ti Central District ti California (USAO).
Ati pe adehun yii ko kọja agbegbe USAO bákan naa ni ko ni nnkan ṣe pẹlu ijọba apapọ, ipinlẹ ati awọn agbejọro ilẹ okere, agbofinro tabi awọn alaṣẹ.
Nigba ti BBC kan si agbẹjọro Hushpuppi Loius Shapiro lati fi idi ọrọ mulẹ pe onibara rẹ gba pe oun jẹbi ẹsun, o si sọ pé òun kìí sọrọ nipa igbẹjọ ti oun ba n ṣe lọwọ.
Ṣugbọn nipa boya awọn ni Iwe to jẹyo lori ayelujara jẹ ootọ, O ni bẹẹ ni ootọ ni awọn iwe naa.
Awọn adehun miiran ti Hushpuppi tun ṣe gẹgẹ bi o ṣe han ninu iwe ọhun ni:
- Oun ko ni jiyan lori gbogbo awọn okodoro ọrọ to wa ninu adehun
- Oun yoo faramọ gbogbo idajọ ti wọn ba fun oun gẹgẹ bi adehun
- O faramọ ki ile ẹjọ maa ba igbẹjọ lọ yala nipa luilo amohunmaworan C"VTC") ayelujara tabi lori foonu ati gbogbo ọna tiile ẹjọ ba fi ara mọ lati ṣe igbẹjọ naa

Oríṣun àwòrán, USAO

Oríṣun àwòrán, USAO
Kini ijiya to wa fun iru ẹsẹ Hushpuppi?
O ṣeeṣe ki o koju ẹwọn ogun ọdun ti wọ́n ba ṣe igbẹjọ tan gẹgẹ bi nnkan to wa ninu iwe ile ẹjọ naa.
" Olujẹjọ ni oye pe ijiya ẹsẹ si ofin ikejidinlogun orilde ilẹ Amẹrika Code Section 1956(h) ni ẹwọn ogun ọdun.
" Ọdun mẹta ni wọn yoo fi ma moju to, ti yoo si san owo itanran ẹgbẹrun lọ́nà aadọ́ta dọla tabi ilopo meji ere tabi adanu lori ẹsẹ ti o ṣe, bákan naa ni yoo tun san ọgọrun dọla gẹgẹ bi owo abẹwo"
Iwe ile ẹjọ fi kun pe o ṣe pataki lati ni oye pe, ile ẹjọ yoo ni ki wọn san ẹkunrẹrẹ owo fun awọn ti o lu ni jibiti nitori pe o ti gba pe oun jẹbi ẹsun.
Bakan naa ni o gba pe nitori ifọwọsolwọpọ USAO pẹlu adehun yii, ile ẹjọ le ni ki o sanwo fun awọnti ko si lara awọn ti ko lu ni jibiti nitori pe o ti gba pe oun jẹbi ẹsun.
"Ni koko olujẹjọ gba pe yoo ṣe adapada fun gbogbo ẹni to ba ti fi ara ko ninu iwa ọdara ti olujẹjọ hu gẹgẹ bi iwe naa ṣe sọ.

Oríṣun àwòrán, USAO

Oríṣun àwòrán, USAO

Oríṣun àwòrán, USAO

Oríṣun àwòrán, usao

Oríṣun àwòrán, AFP
Awọn eleto abo Orilẹede United Arab Emirates lo kọkọ mu Hushpuppi to n gba ni Dubai ninu oṣu kini ọdun 2020 lẹyin ti wọn fẹsun kan pe oun gbiyanju lati ji ọpọ milọnu dọla nipa lilu Email ati ọna Yahoo-Yahoo ati awọn awọn ọna jibiti miiran.
Ile iṣẹ awọn agbẹjọro, ilé ifowopamọ ati ẹgbẹ agbabọọlu Premiere League kan ni o tun pinu lati lu ni jibiti nigba ti wọn mu.
Ninu oṣu keje ọdun 2020, orilede UAE pada da Hushpuppi pada si Chicago ni orilede Amerika labẹ ẹka akanse FBI ti wọ́n si kọkọ gbe lọ si ile ẹjọ.
Lasiko to to wa ni atimọle, ile ẹjọ Ariwa Illinois ni orile-ede USA ti pasẹ pe ki wọn gbe Hushpuppi lọ si Los Angeles ni bi igbẹjọ yoo
Kí ìgbẹjọ tó bẹrẹ Ramon Abass ti pe oun jẹbi ẹsun mẹrin ti wọn fi kan oun, lati ori kiko owo owo pamọ lọna aitọ awọn oniruuru ẹsun mii.
Ki o to di asiko yii, awọn onimọ ti sọ fun BBC tẹlẹ pe ti wọ́n ba ri pe Hushpuppi jẹbi ẹsun, o kere tan yoo lọ ẹwọn ogun ọdun.

















