Yoruba people: A ǹ fẹ̀ kí gbogbo ìpínlẹ̀ Yoruba ní Naijiria di ọ̀kan ṣoṣo - Ẹgbẹ́ YYSA

Yoruba

Oríṣun àwòrán, YYSA

Lọna ati jẹ ki gbogbo ọmọ Yoruba di ọkan ṣoṣo kaakiri ilẹ Naijiria, ẹgbẹ awọn ọdọ ilẹ Yoruba, Yoruba Youth Socio-cultural Association, YYSA, ti sọ pe ki gbogbo ipinlẹ Yoruba ni Naijiria di ọkan ṣoṣo.

Ninu atẹjade kan ti awọn alaga ẹgbẹ ọhun ni guusu iwọ-oorun Naijiria fọwọ si ni wọn fi ọrọ naa lede.

Atẹjade ọhun ni "Awa ẹgbẹ Yoruba Youth Socio-cultural Association n pe fun iṣọkan ati isopọ awọn ipinlẹ Yoruba ni Naijiria ki a le di ẹya ti ko ni ṣe fọwọ rọ ṣeyin kaakiri agbaye."

Ẹgbẹ naa rọ gbogbo gomina ilẹ Yoruba lati fọwọ sowọpọ gbe awọn ileeṣẹ to wa labẹ Oodua Investment ga fun idagbasoke ẹya Yoruba.

Bakan naa ni wọn tun kesi gbogbo gomina to n ṣakoso awọn ipinlẹ guusu iwọ-oorun Naijiria lati kan si awọn akẹgbẹ wọn ni Kwara, Kogi ati Edo lati fimọ ṣọkan nitori ọpọ ọmọ Yoruba lo wa lati awọn ipinlẹ naa.

Ẹgbẹ YYSA jẹ ọkan gboogi lara awọn ẹgbẹ ọmọ Oodua to n pe fun iṣọkan ati idagbasoke ilẹ Yoruba.

Afojusun ẹgbẹ naa ni lati jẹ ki gbogbo ẹya Yoruba jẹ ọkan ni Naijiria, nilẹ Afrika, ati lawọn ilẹ miran lagbaye bii Caribbean ati Guusu ilẹ Amẹrika.