Báyìí ni o ṣe lè fi orúkọ oògùn tàbí àgbo rẹ sílẹ̀ lábẹ́ àjọ NAFDAC

Herbs

Oríṣun àwòrán, @LondonMudlark

Àkọlé àwòrán, O maa fun ajọ NAFDAC ni diẹ lara agbo naa fun atupalẹ ati ayẹwo finifini
    • Author, Olumide Owaduge
    • Role, BBC Yoruba, Lagos

Lati igba ti arun Coronavirus ti kọlu gbogbo agbaye, ọpọ awọn onimọ iṣẹgun oyinbo ati ibilẹ lo ti n gbiyanju lati wa ojutu si arun naa.

Kaakiri agbaye ni awọn eleto ilera ti n wa ọna lati ṣe abẹrẹ ajẹsara fun un ṣugbọn wọn ko tii ri ọna abayọ titi di asiko yii.

Awọn ologun ibilẹ kan ni Naijiria ti n sọ pe awọn ni oogun to le koju arun naa ti ijọba Naijiri ba gba wọn laye lati ko sita.

Ṣugbọn ti wọn ko mọ ohun to yẹ ki wọn ṣe ki oogun tabi agbo wọn le gba ountẹ ijọba labẹ ajọ NAFDAC to n risi ọrọ yii.

Eyi ni awọn ọna ti o le gba lati fi orukọ oogun tabi agbo rẹ silẹ labẹ ajọ to n ṣakoso oogun pipo ni Naijiria, NAFDAC.

1. Igbesẹ akọkọ ni gbigba fọọmu ni ọfiisi NAFDAC to ba sunmọ ọ julọ.

Nibi yii lo ti maa ṣalaye iru oogun ti o fẹ gbe jade, eroja ti o fi po oogun naa, iṣẹ tio n ṣe, atawọn nnkan mi ti wọn ba bere ninu fọọmu naa.

2. Ọfẹ kọ ni fọọmu naa ba de o, o maa san iye owo kan ti NAFDAC ko darukọ.

3. Bẹẹ naa lo tun maa ṣalaye bi awọn onibara rẹ ṣe le lo ogun naa. Boya nigba kan lojumọ ni, igba meji, ati bẹ bẹ lọ.

nafdac

Oríṣun àwòrán, @NafdacAgency

4. O tun maa sọ ninu fọọmu naa idi pataki ti o fi ro pe awọn eeyan ilẹ Naijiria nilo oogun ti o fẹ gbe jade ọhun.

5. O maa fun ajọ NAFDAC ni diẹ lara agbo naa fun atupalẹ ati ayẹwo finifini.

6 Lẹyin eyi ni o maa fiwe ranṣẹ si ọfiisi NAFDAC to wa ni Oshodi, ni ipinlẹ Eko lati fi to wọn leti pe o fẹ fi orukọ agbo rẹ silẹ.

7. Lẹyin eyi ni NAFDAC yoo lọ ṣe apero lori boya ki wọn fi ontẹ lu irufẹ agbo bẹ tabi ki wọn gbẹsẹle.

Àkọlé fídíò, Seyi Makinde; Ilé iwosan kan ṣoṣo tó wà ní Idí-Iroko /Adewole tí bàjẹ́ pátápátá.

Lẹyin ti NAFDAC ba ti fi ontẹ lu agbo rẹ tan, o laṣẹ lati taa laarin ọdun meji si marun un ko to tun lọ ṣe atunṣẹ iwe aṣẹ agbo naa.

Ajọ NAFDAC laṣẹ lati gbẹsẹle le agbo rẹ lẹyin ọdun meji tabi marun un ti o ba kọ lati sọ iwe aṣẹ ọhun dọtun.

Àkọlé fídíò, Yetunde Bakare dárà lórí ètò Ṣé o láyà, ẹ ràn án lọ́wọ́ nínú ìbéèrè tó ṣì