Tax on House rent: Kò yẹ kí ìjọba máa ní àwọn mẹ̀kúnú lára lásìkò Coronavirus

Buhari

Oríṣun àwòrán, Presidency

Àkọlé àwòrán, Ijọba tí ní àwọn fẹ́ maa gba owo ori lórí owó ilé tí àwọn ènìyàn bá ń sàn àti owó ìwé ẹrí ilẹ̀.

Onimọ nipa eto ọrọ aje lorilẹ-ede Naijiria, Bismark Rewane ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ijọba lati fi owo ori kun owo ile ti awọn eniyan n san lasiko yii.

Eyi ko ṣẹyin iroyin ti ẹka ijọba to n risi eto owo ori ni Naijiria fi lede wi pe awọn fẹ maa gba owo ori lori owo ile ti awọn eniyan n san.

Koda, wọn wọn yoo maa gba owo ori lori iwe ẹri ‘emi ni mo ni ilẹ’, iyẹn Certificate of Occupancy (C of O).

Onimọ nipa eto ọrọ aje ni Naijiria, Bismark Rewane nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ ni ko yẹ ki ijọba maa ni awọn eniyan lara lasiko arun Coronavirus.

Rewane ni bi o tilẹ jẹ pe ijọba ni ẹtọ lati gba awọn owo ori naa, kii ṣe igba ti ọrọ aje ba dẹnukọlẹ tabi ti ajakalẹ arun n ba agbaye finra.

O ni: ‘Igbesẹ ijọba ko ba lọ daadaa ka ni wi pe ohun gbogbo n lọ deede lai si ọrọ aje to dẹnu kolẹ, tabi arun Coronavirus to ti jẹ ki ọpọ eniyan ṣe ofo ẹmi ati iṣẹ’.

‘Ki ijọba sọ ohun gbogbo ti wọn ba lero lati ṣe di ẹyin ajakalẹ arun, ti ọrọ aje ba gberu si.’

Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Others

O ni ohun ti ijọba le ṣe lasiko yii lati mu ki ọrọ aje gberu si ni lati fi aaye silẹ ki awọn eniyan da okowo silẹ labẹle,

Ati ki awọn eniyan wa lati oke okun lati wa da okowo silẹ ni Naijiria.

Àkọlé fídíò, Láàrín ìdílé ẹlẹ́ni márùn ún yìí, ọmọ kan ṣoṣo ló léè sọ̀rọ̀

Bakan naa lo gbe oriyin fun ijọba pe wọn mu adinku ba iye owo ti awọn eniyan n san lori ẹyawo fun awọn olokowo keekeeke.

Bẹẹ lo salaye pe ijọba naa gbiyanju nitori wọn fun awọn mẹkunnu lanfaani lati ya owo lọwọ Banki apapọ Naijiria, CBN ni iye owo ti ko pa wọn lara lati san pada.

Àkọlé fídíò, 'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'