Funsho Adeolu: Ìwọ̀kuwọ̀ àti ìrìnkurìn obìnrin míì ń fa ìfipábánilòpọ̀

Funsho Adeolu

Oríṣun àwòrán, Instagram adeolufunso

Àkọlé àwòrán, Funsho Adeolu: Ìwọ̀kuwọ̀ àti ìrìnkurìn obìnrin míì ń fa ìfipábánilòpọ̀

Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Funsho Adeolu sọ pe, ọpọ awọn obinrin lo n ṣ'okunfa ifipabanilopọ to gogo lawujọ bayii.

Adeolu woye ọrọ yii lasiko to n kopa lori eto ifọrọwerọ kan lori ikanni BBC News Yoruba.

O ni o ṣeeṣe kawọn ọkunrin ti o n fipa bawọn obinrin lopọ larun ọpọlọ, amọ awọn obinrin mii ti wọn n rinrin kurin lo maa ri irikuri.

O fikun ọrọ rẹ pe, gbogbo awọn ọkunrin ti wọn n fipa bawọn obinrin lopọ kiri, ati ilẹ lo ti wọ wa.

Funso Adeolu ati iyawo rẹ

Oríṣun àwòrán, Instagram adeolufunso

Funso Adeolu: O ni bi wọn ṣe tọ awọn ọmọkunrin mii lo jẹ ki wọn maa huwa ifipabanilopọ nitori ko si ohun to le mu ọkunrin kan fipa ba obinrin lopọ.

''Koda ko yẹ ki ọkọ fipa mu iyawo rẹ, ko yẹ ki o fi ipa mu un,'' Funsho Adeolu lo woye bẹẹ.

Nigba ti o n sọrọ nipa bi awọn olootu ṣe maa n fun awọn oṣere nipa ti wọn yoo koo ninu ere, Adeolu ni awọn eeyan to ba burẹwa ko le ko ipa to pọ ninu ere.

Àkọlé fídíò, Oríṣí ìjìyà ní àwọn bíi Gómìnà El Rufai àti Fayemi ń bèèrè f'àwọn afipábánilòpọ̀

O ṣalaye pe, awọn to ba burẹwa lo maa n kopa bi iwin, Eṣu ati ọmọ ọdọ ninu ere.

Adeolu ni ẹsin kan naa lo yẹ ki tọkọ-taya maa ṣe, ki alaafia le jọba ninu idile pẹlu afikun pe adura ati ifarada ṣe pataki ninu ohun to n mu idile duro.

O wa sisọ loju rẹ pe ọdun mẹjọ ni oun ati pẹlu iyawo oun fi fẹ ara awọn, ki awọn to fẹ ara wọn bii tọkọ-taya.

''Igbeyawo wa ti pe ọdun mẹrindinlogun bayii, a kii ṣe ọkọ ati iyawo, ọrẹ lemi ati iyawo mi, mi o ni ọrẹ mii lẹyin rẹ,''

O ni oun maa n fifẹ han si iyawo oun lori ayelujara, lati jẹ ki o jẹ awokọṣe fawọn eeyan.

Funso Adeolu, iyawo ati ọmọ rẹ meji

Oríṣun àwòrán, Instagram adeolufunso

O si tun kede pe, "mama ati baba mi jọ ṣere ni wọn fi bi mi, wọn ko fẹ ara wọn, iyẹ lo jẹ ki n pinnu pe iyawo ti mo ba fẹ gbọdọ ba mi kalẹ.

Nigba to n sọrọ lori awọn oṣere kan ti wọn kii le sọ ede Yoruba ninu ere, Adeolu ni itiju nla ni.

O ni awọn ti wọn ro pe ipa ki oun maa le obinrin kiri nikan ninu ere ni oun maa n ṣe, ko mọ pupọ nipa oun.

Adeolu ni oun ti kopa ninu oriṣiriṣii ere to le ni igba, ti oun si ko oniruuru ipa ninu wọn.

Àkọlé fídíò, Láàrín ìdílé ẹlẹ́ni márùn ún yìí, ọmọ kan ṣoṣo ló léè sọ̀rọ̀