Kogi FMC: Àwọn Jàndùkú kó àwọn àkọsilẹ̀ ilé ìwòsàn, ẹ̀rọ kọ̀mpútà ati fóónù àwọn dókìtà lọ

Kogi FMC: Àwọn Jàndùkú yabo ilé ìwòsàn FMC nípìnlẹ̀ Kogi

Oríṣun àwòrán, others

Ìròyìn sọ pé àwọn jàndùkú yabo ilé ìwòsàn ìjọba àpapọ̀ FMC to wa nílùú Lokoja, ìpínlẹ̀ Kogi, ti wọ́n sì kó gbogbo àwọn àkọsilẹ̀ ilé ìwòsàn, àwọn kọ̀mpútà ati fọ́ọ̀nù àwọn dókìtà lọ.

Sáájú ní àwọn dókítà ti pè fún ìpàdé oníròyìn láti lówùrọ̀ òní, láti bèèrè fún ibùdó àyẹ̀wò ní ìpínlẹ̀ Kogi.

Bákan náà ni àwọn òṣìṣẹ́ fẹ́ sọ èrò wọ́n lóri ìpèníjà ti àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn náà ń kojú lásìkò ààrùn Covid-19 yìí.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọ̀kan lára òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn náà to ba BBC Yoruba sọrọ labẹ asọ ni ariwo àwọn oṣiṣẹ́ ni òun gbọ́, lásìkò ti òún pè láti báwọn sọ̀rọ̀ lórí ìpàdé ti ó yẹ kó wáye lówùrọ̀ òní.

Kogi FMC: Àwọn Jàndùkú yabo ilé ìwòsàn FMC nípìnlẹ̀ Kogi

Oríṣun àwòrán, other

Osisẹ Alukoro fun ilé ìwòsàn náà, ọgbẹ́ni Abdullahi fìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún BBC Yoruba pé, lóòtọ́ ni ìṣèlẹ̀ náà wáyé.

Deede aago mẹjọ owurọ la gbọ̀ pe awọn janduku ọhun ya bo ile iwosan ijọba naa, wọn n yin ibọn soke laibikita, ti wọ́n si dẹru ba awọn alaisan to wa nibẹ.

Ọ̀kan nínú àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn náà fí ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé gbogb àwọn òṣìṣẹ̀ ilé ìwòsàn náà ti lọ silé bótill jẹ́ pé àwọn aláìsàn pọ̀ lórí àkéte àìsàn tó lágbára.

Òṣìṣẹ́ náà sàlàyé pé àwọn ti ni ìṣòrò pẹ̀lú gómínà ìpínlẹ̀ Kogi s''ajú àsìkò yìí pé, ilé ìwòsàn FMC ti ń gbẹ̀yìn gbẹbọ jẹ́ fúu ìjọba lórí ọpé kò sí ààrùn Covid-19 ni ìpínlẹ̀ Kogi.

O ní gbogbo ìgbà ni àwọn ènìyàn ń wá ti ǹkan tó n ṣe wọ́n sì jọ mọ́ ààrùn Covid-19 sùgbọ́n kò sí ẹrọ àyẹwó àti pé ni ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn máa n dari wọ́n lọ si ilú Abuja.

Ìjọba tún paá láṣẹ pé kí ilé ìwòsàn náà má dari àwọn ènìyàn sí ilé ìwòsàn Abuja mọ́ láì gba àṣẹ láti ọ̀dọ̀ ìjọba ìpínlẹ̀ Kogi, Lẹ́yìn èyí ọ̀pọ̀ àwọn ti FMC fi sọ́wọ́ si Abuja ló ní ààrùn náà.

Láìpẹ́ yìí ọ̀kan nínú òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn FMC náà kú nípa ààrùn Coronavirus, èyí sì ló fàá ti ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ṣe fẹ́ ṣe ìpàdé láti sọ ẹ̀dùn ọkàn wọ́n fú ìjọba.

Ẹ̀wẹ̀, àtẹjáde ti ìjọba ìpínlẹ̀ Kogi fisíta sàlàyé pé àwọn ẹbi aláìsàn kan níle ìwòsàn náà ti wọ́n kọ̀ láti tójú, dé bi pé o wá bí ọmọ sí ẹnu ọ̀nà ilé ìwòsàn náà.

Nítori náà, wàhálà tó ṣẹlẹ̀ lówùrọ̀ yìí wáyé nítori pé àwọn afẹhónúhàn náà jẹ́ ẹbí àwọn aláìsàn ti àwọn aláṣẹ́ ilé ìwòsàn FMC kọ̀ láti tójú.