Ambode: Òtítọ́ ọ̀rọ̀ nípa ìròyìn tó sọ pé Ambode ni APC fún ní tíkẹ́étì sẹ́nétọ́

Ambode

Oríṣun àwòrán, @Ambode

Àkọlé àwòrán, Òtítọ́ ọ̀rọ̀ nípa ìròyìn tó sọ pé Ambode ni APC fún ní tíkẹ́étì sẹ́nétọ́

"Ko ti i si ẹnikẹni to kàn si Akinwumi Ambode pe wọn fẹ fun un ni tikẹẹti lati dupo sẹnetọ nipinlẹ Eko."

Eyi ni idahun ti oluranlọwọ fun gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ, Akinwumi Ambode, fun BBC lori iroyin to n lọ nigboro pe oun ni yoo rọ́pò Ọṣinọwọ.

Adebayo Ọṣinọwọ ni sẹnetọ to soju ẹkùn idibo ìlà Òòrùn Eko, ko to di oloogbe lọjọ kẹẹdogun, osu Kẹfa, ọdun 2020.

Oluranlọwọ naa to fẹ ka fi orukọ bo oun ni asiri sọ pe o ṣe e ṣe ko jẹ pe awọn eeyan kan to fẹ wo bi Ambode ṣíṣe gbajúmọ̀ si lo n gbe iroyin naa kiri.

Bakan naa lo tun ni Ambode ko tii gba ipe lati ẹgbẹ oṣelu APC lori eyi rara.

O ni: "Lootọ, Ambode náà ni ẹtọ lati du ipo sẹnetọ naa, nitori pe ọmọ ẹkùn idibo ọhun ni.Sugbọn, ṣe ẹni ti wọn ko ti ẹ sọ fun pe wọn fẹ fun ni tikẹẹti lati dupo sẹnetọ, ni yoo kopa ninu eto idibo."

Àkọlé fídíò, Láàrín ìdílé ẹlẹ́ni márùn ún yìí, ọmọ kan ṣoṣo ló léè sọ̀rọ̀

Iroyin yii ti kọkọ bẹrẹ bi idibo lori ayelujara, nibi ti awọn araalu ti fi orukọ awọn oloṣelu bi Abike Dabiri-Erewa, Gbenga Ashafa, ati awọn miran silẹ pe ta a ni yoo rọ́pò Osinowo.

Saaju eyi ni awọn kan sọ lọdun 2019 nigba ti ẹgbẹ oṣelu APC ko fun Ambode ni tikẹẹti lati dupo gomina fun saa kejì, pe o ṣe e ṣe ki ẹgbẹ fi ipo sẹnetọ tu u lójú.

Àkọlé fídíò, 'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'

Oluranlọwọ Ambode sọ pe o ṣe e ṣe ko jẹ pe eyi ni awọn eeyan ranti ti wọn fi n sọ pe Ambode ni yoo rọ́pò Osinowo to di oloogbe.

O ni: "Nkan to ye gbogbo àwọn to mọ nipa oselu nipinlẹ Eko ni pe ọrọ kii sáábà ri i bi gbogbo eniyan ba ṣe ro pe yoo ri."

Àkọlé fídíò, Oríṣí ìjìyà ní àwọn bíi Gómìnà El Rufai àti Fayemi ń bèèrè f'àwọn afipábánilòpọ̀

Ajọ eleto idibo ni Naijiria, INEC, ko ti i kede ọjọ ti atundi ibo naa yoo waye.

Ofin Naijiria fi lélẹ̀ pe atundi ibo gbọdọ waye laarin aadọrun ọjọ, ti aaye aṣofin kan ba ṣófo.