Olatunde Falabi: Ilé ẹjọ́ yẹ àga mọ́ Ọba Ìkirè nìdí lẹ́yìn ọdún 27 lórí ìtẹ́

Oríṣun àwòrán, @Oba Olatunde
Ile ẹjọ giga kan ni ipinlẹ Ọṣun ti yẹ aga mọ Ọba Olatunde Falabi to jẹ Akire ti ilu Ikire nidi.Awuyewuye lori ẹni ti ipo ọba naa kan ni Ikire ti bẹrẹ lati ọdun 1993 nigba ti Ọba Falabi gori itẹ.Eyi to mu ki ọkan lara awọn to n du ipo ọba ọhun, Ọmọba Tajudeen Olarewaju, lati idile Aketula pe ẹjọ lodi si ọba tuntun to ṣẹṣẹ gori itẹ lọjọ naa lọhun.
Wọn fa ẹjọ naa titi to fi de ile ẹjọ to gaju ni Naijiria lọdun 2014, ti ile ẹjọ ọhun si ṣedajọ pe kii ṣe Falabi ni oye naa tọ si, bikoṣe Olarewaju.
Lẹyin idajọ naa ti ijọba ipinlẹ Osun gbiyanju lati yọ Ọba Falabi lori itẹ.
Ni eyi to mu ki oun ati awọn agbẹjọro rẹ gba ile ẹjọ giga ipinlẹ lọ, pe idajọ ile ẹjọ to ga ju naa ko sọ pe ki oun kuro lori oye.
Falabi sọ pe gomina ana nipinlẹ naa, Rauf Aregbesola lo pe oun si ipade kan ni ilu Oṣogbo lọdun 2014.
Ati pe ninu ipade yii ni Aregbesola ti sọ fun oun niwaju Adajọ agba ipinlẹ ọhun ati kọmiṣọnna to n ri si ọrọ lọbalọba pe wọn ti yọ oun lori itẹ.
Nigba to n ṣedajọ rẹ lori ọrọ naa, Adajọ A. B. AbdulKareem sọ pe Ọba Falabi ko lẹtọ lati wa lori itẹ gẹgẹ bi Ọba ilu Ikire.
Adajọ ọhun tẹsiwaju pe Ọmọba Tajudeen Olarewaju ni oye ̣Ọba naa tọ si.Lẹyin naa lo ni ko lọ rọọkun nile, ki ẹni ti oye ọhun tọ si le e bọ sori itẹ.















