Ojú ẹni máa là... ọ̀dọ́mọdé tó padà dí dókítà lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbìyànjú láyé

Oríṣun àwòrán, @others
Yorùbá ni bi eeyan ba ni suuru ti ko si tete ku, o di dandan ko jẹ ẹran tó ju erin lọ
Bí ènìyàn ba sì ni àfojúsùn, o di dandan kí o ṣ'ori Ire, ko bọ kuro lọwọ iṣẹ ati oṣi.
Báyìí ni ọ̀rọ̀ irirnajo ọdọmọkunri omo orile-ede South Africa kan ṣe rí, iyẹn Ntando Makhubela.
Oriṣiiriṣi iṣẹ agbara ni Ntando ti ṣe ko to pari ẹ si ko maa ṣíṣe gẹ́gẹ́ bí ọmọ tó n ta epo bentiroolu nílé epo to sì ti àti ibẹ̀ di dókítà oníṣègùn òyìnbó.
Ntando Mkhubela jẹ ẹni odun mẹẹdọgbọn to fi itan aye rẹ gba awọn ọdọ bii tirẹ ni imọran lori bi o ṣe ta epo títí to fi di dókítà
Lati ìgbà to ti sọ itan bí o ṣe rìn irinajo ìgbésí aye rẹ̀ lórí ayélujára ni ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ti n rii gẹ́gẹ́ awokọse rere láwùjọ.
Leyin to parí ilé ìwé Gírámà pẹlu awọn maaki to lamilaaka, Makhubela kò ní Ore òfẹ́ láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Fáṣítì nítorí ìṣòro aisowo.
O lọ ilé ẹ̀kọ́ Cyril Clarke lọ́dún 2014 ro si ni àwọn maaki tó ga ju nínú àwọn imo sáyẹ́nsì bí isiro, Physics, Biology, ṣùgbọ́n ko si owó láti lọ sí Fáṣítì.
Ntando bẹ̀rẹ̀ sini ṣíṣe nílé epo, ibẹ ni ẹnìkan ti rii ti o si ri pe ọmọ to ni làákàyè ni.
Ṣe ori to ba maa gbe ẹni lo maa n gbe alawo ire ko ẹni, Oluranlọwọ yii lo ba Ntando wa ọ̀nà ètò ẹ̀kọ́ òfẹ́ sí Fáṣítì, èyí lo sì ran an lowo láti kàwé.
Láìpẹ́ yìí ni Makhubela yóò bẹ̀rẹ̀ si ní gbé ìgbé ayé to wù ú láti ìbẹ̀rẹ̀ aye rẹ̀, nítorí pé díẹ̀ loku kí wọ́n ṣe ayẹyẹ ìgbà ni wọlé fún un gẹ́gẹ́ bí dókítà onímọ̀ ìṣẹ̀gùn òyìnbó.















