Aso ebi: Ẹ wo bí ọ̀làjú ṣe yí Ìró àti Bùbá padà ní ilẹ̀ Yorùbá

Oríṣun àwòrán, @Diran
Aṣa aṣọ wiwọ ni ilẹ Yoruba ṣe pataki pupọ.
Oriṣiriṣi aṣọ lo ti wa tipẹ tipẹ bii Aṣọ Ofi / Aṣọ Oke, Sanyan, Alari, Damaski to jẹ afinju aṣọ nigba aye rẹ, Léèsì, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Awọn aṣọ kan wa ti a mọ awọn iran, ẹya tabi awọn eeyan kan mọ, bii adirẹ ati Kampala to jẹ ti awọn Ẹgba ni Abeokuta.
Diran ayaworan se atupalẹ bi awọn obinrin ni ilẹ Yoruba ṣe n wọ aṣọ 'Iro ati Buba' ni aye atijọ ati ayipada to de ba ni aye ode oni.
Ẹgbọn Arakunrin Oye Diran lo kọkọ fi aworan ti ẹbi rẹ ya ni ọdun 1960 han,
Aworan yii lo si jẹ ohun iyalẹnu fun un bi iyatọ si ti de ba bi awọn obinrin ile Yoruba ni aye igba naa ṣe n dárà pẹlu aṣọ 'Iro ati Buba' ni ọdun 1960, 1970 ati ọdun 1980.

Oríṣun àwòrán, @Diran
Aworan iya rẹ ati ẹgbọn rẹ safihan awọn arẹwa obinrin to wọ irọ ati buba, eleyii to wọpọ laarin awọn obinrin to wa lati ẹya Yoruba lorilẹ-ede Naijiria.
Diran to jẹ ọmọ Yoruba, to si jẹ ayaworan to n gbe ilu New York, lorilẹ-ede Amerika bẹrẹ si ni ṣe iwadii lori bi lilo iro ati Buba laarin awọn obinrin ṣe ti yipada si ti aye atijo.
Amọ ti o ti si jẹ ohun to gbajumọ lawujọ awọn Yoruba.
Eleyii jẹ iwuri fun Diran to si mu ki o bẹrẹ si ni wa awọn aworan lori ayelujara, amọ o ṣeni laanu wi pe ko ri awọn aworan to safihan bi wọn ṣe n wọ iro ati Buba laye atijọ.
- Ẹ wo bí Hushpuppi ṣe farahàn nílé ẹjọ́ l'Amẹrika fún ìgbà àkọ́kọ́ láti jẹ́jọ́
- Bàbá Aláàfin ìlú Ọ̀yọ́, Elérúwà àti àwọn Ọba Ilẹ̀ Yorùbá míràn tí wọ́n rọ̀ lóyè
- Ìjọba Nàìjíríà ti mú Dókítà Anu tí àwọn kan f'ẹ̀sùn kàn pé ayédèrú iṣẹ́ abẹ ìdí ló n ṣe
- Erépá ní bàbá àti ìyá mi ṣe tí wọ́n fi bí mi, wọn kò fẹ́ra wọn- Funsho Adeolu
Diran sọ fun BBC pe ohun ti oun ri ni bi awọn eniyan se n lo iro ati Buba laye ode oni eleyii ti a mọ si 'Aṣọ Ẹbi'.
Eleyii to mu ki o bẹrẹ si ni ya aworan awọn aṣọ alaranbara yii ti o pe akọle rẹ ni 'A TI DE'.

Oríṣun àwòrán, @Diran
Gẹgẹ bi a ti mọ asa ilẹ Yoruba si, wọn fẹran ariwo lasiko ayẹyẹ bii ki a si ile tuntun, ikomọjade, igbeyawo ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Wọn a si fi ile pọti, fi ọna roka ni, fi gbogbo agbada din ẹran ti gbogbo eniyan yoo si wọ aṣọ alaranbara wa si ibi ayẹyẹ naa.
Ohun ti o wọpọ laye atijọ ni ki awọn obinrin wọ irọ ati buba ti a maa n pe ni 'isalẹ apoti'.
Eleyii to tumọ si aṣọ to n dan gbinrin, ti o si jẹ wi pe asiko ayẹyẹ nikan ni a ma n wo.
Amọ, laye ode oni, ohun gbogbo ti yii pada, ohun ti a n wọ laye isinyii ni asọ-ẹbi,
Eleyii ti wọn fi n ṣe pọn dandan fun gbogbo awọn elejo ni ibi ayẹyẹ lati ri i pe wọn wọ aṣọ kan naa.
Iru awọn aṣọ bayii tun di ọjọ miran, ọjọ irẹ ko tun to ri ita nitori kii ṣe isalẹ apọti mọ, bi ati mọ ọ si laye atijọ.

Oríṣun àwòrán, @Diran
Diran ti wọn bi ni ilu Eko sọ wi pe nkan bii ọdun 2000 ni bi awọn eniyan se n wọ iro ati buba ti o si bẹrẹ si ni yipada.
Ni ọdun 1960, iro ati buba maa n kọja orunkun diẹ si isalẹ.
Amọ ni bayii, awọn obinrin a ma a wọ iro ati buba ti yoo tilẹ ma a de atẹlẹsẹ wọn.
Ti awọn asa aṣọ riran ni aye ode oni si ti rapala wọ bi awọn eniyan se n ran iro ati buba ni aye ode oni.

Oríṣun àwòrán, @ Diran
Diran to jẹ ayaworan isaraloge ati asọ wiwọ igbalode, fi kun un wi pe oge ṣiṣe ati aṣọ wiwọ ti yipada lati faaye gba wiwọ irọ ati buba lọna igbalode.
Ti awọn miran a si fi apa yẹbẹ-yẹbẹ sii, tabi ki o yẹ lorun diẹ, tabi ki orun rẹ ga soke.
Bakan naa ni awọn miran n lo aṣọ bi Ankara, Chiffon tabi Organza lati fi dara to ba wu wọn.
Igba miran aṣọ naa le fẹ lara tabi ki o lẹ mọ wọn lara pẹkipẹki.
Diran ṣalaye wi pe: 'A ti De' ti oun pe akọle awọn aworan ti oun ya yii ṣe apejuwe awọn obinrin to dantọ,
Awọn obinrin ti wọn si ni igbẹkẹle ninu ara wọn, ti wọn si n polongo pe eniyan ti de si gbagede ogẹ ṣiṣe ati aṣọ wiwọ.
Eleyii tun safihan bi awọn ọmọ Yoruba ṣe fẹran afẹfẹ yẹyẹ to n polongo pe wọn ti de si agbo ayẹyẹ lati wa safihan ẹwa aṣọ wọn.
- Wo awọn Aàrẹ nílẹ̀ Áfríkà to ti gba oyè "Field Marshal" rí
- Ẹ wo bí ìsìnkú Adegbenro, Kọmíṣọ́nnà l‘Ondo ṣe lọ...
- Wo àdúgbò tó ń jẹ́ orúkọ èèbó amúnisìn tí yóò pa orúkọ dà l’Eko
- Adesoji Aderemi, Ọọ̀ni Ifẹ̀ àti gómìnà Adúláwọ̀ àkọ́kọ́ láyé eèbó amúnisìn
- Ìjọba tó wà lóde yìí kò ní ìfẹ́ aráàlú la ṣe dá ẹgbẹ́ NCF sílẹ̀ - Femi Falana
















