Domestic Violence: Obìnrin kan wọ gàù lẹ́yìn tó kan ìṣó mọ́ ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ lórí ní Enugu

Oríṣun àwòrán, Wacol
Ijọba ipinlẹ Enugu ti sọ pe oun ti bẹrẹ iwadii lori obinrin kan ti wọn fẹsun kan pe o kan iṣo mọ ọmọ ọdọ rẹ lori.
Wọn fi ẹsun kan arabinrin naa, Ifeoma King pe o kan iṣo mọ ọmọ ọdun mẹwaa ọhun, Nenoma Ndadi lori.
Awọn alabagbe obinrin naa sọ pe o fi aṣọ we ọmọ ọhun lori lẹyin to ṣe iṣẹ ibi naa ki awọn eeyan ma ba ri pe o ti ni ipalara.
Ṣugbọn aṣiri tu nigba ti ọmọ ọhun figbe ta, ki awọn eeyan to lọ gba silẹ.

Oríṣun àwòrán, Wacol
Ọmọ ọhun ti wa nile iwosan Parklane ni ilu Enugu bayii, nibi to ti n gba itọju lọwọ.
- Ẹ wo bí Hushpuppi ṣe farahàn nílé ẹjọ́ l'Amẹrika fún ìgbà àkọ́kọ́ láti jẹ́jọ́
- Ìjọba Nàìjíríà ti mú Dókítà Anu tí àwọn kan f'ẹ̀sùn kàn pé ayédèrú iṣẹ́ abẹ ìdí ló n ṣe
- Erépá ní bàbá àti ìyá mi ṣe tí wọ́n fi bí mi, wọn kò fẹ́ra wọn- Funsho Adeolu
- Àjọ NCDC kéde ènìyàn 454 tó tún ṣẹ̀ṣẹ̀ ní Coronavirus ní Nàìjíríà
Nigba to n fi erongba rẹ lede lori ọrọ naa, Ọjọgbọn Joy Ezeilo to n ṣoju ẹgbẹ ajafẹtọ obinrin atawọn ọmọde, Women Aid Coellective, WACOL ni iṣẹlẹ naa jẹ eyi to bani ninu jẹ pupọ, ati pe o lodi si ofin to rọmọ ẹtọ awọn ọmọ wẹwẹ.
Ẹwẹ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ ọhun, Daniel Ndukwe ti sọ fun BBC pe kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ naa ti paṣẹ pe ki iwadiii bẹrẹ lori ọrọ ọhun.
O ni "A o jẹ ki gbogbo ara ilu mọ ohun ti a ba babọ lẹyin iwaddi wa."












