Tokyo 2020: Orílẹ́èdè Nàìjíríà kò tíì rí àmì ẹ̀yẹ kankan gbà nínú ìdíje Olympics tó ń lọ

Awọn agbabọọlu alapẹrẹ Naijiria

Oríṣun àwòrán, D'Tigers/Nigerian Basketball

Ẹgbẹ agbabọọlu alapẹrẹ Naijiria, D'Tigers tun ti fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ keji ti wọn gba ninu idije Olympics to n lọ lọwọ niluu Tokyo lorilẹede Japan.

Ẹgbẹ agbabọọlu alapẹrẹ orilẹede Australia lo kọkọ fiya jẹ D'Tigers Naijiria ninu ere bọọlu ti wọn kọkọ.

Ṣugbọn Germany fi ọba lee fun wọn nigba ti wọn ṣe iya airo tẹlẹ fun Naijiria pẹlu ami ayo 99-92.

Germany lo kọkọ ṣiwaju ni ipele akọkọ pẹlu ami ayo 21-24 ki D'Tigers to gbafuja lọwọ wọn ni ipele keji pẹlu ami ayo 29-26.

Ọmi ni awọn mejeeji jọ ta ni ipele keji, ṣugbọn Naijiria fidirẹmi ni ipele kẹrin ere bọọlu alapẹrẹ naa.

D'Tigers ti n lewaju pẹlu ami ayo mọkanla ni ipele kẹta ki wọn to padanu ipo aṣiwaju wọn eyi to mu wọn fidi rẹmi.

Naijiria ati Germany lo fẹyin gbalẹ ninu ere bọọlu alapẹrẹ ti wọn kọkọ kopa ninu rẹ ni idije Tokyo 2020.

Agbabọọlu apẹrẹ Naijiria

Oríṣun àwòrán, D'Tigers/Nigerian Basketball

Nigba ti Austalia fiya jẹ Naijiria, Italy lo pokọ iya fun Germany.

D'Tigers gbọdọ jawe olubori bayii ninu ere bọọlu alapẹrẹ wọn to kẹyin lọjọ Abamẹta ki to le ni ireti lati tẹsiwaju ninu idije Olympics.

Ẹwẹ, agbabọọlu tẹniisi ori tabili, Aruna Quadri naa fidi rẹmi ninu ere ọwọ lori tabili to ṣe pẹlu ninu idije ọlọdanni ni Tokyo 2020.

Ọmọ Brazil, Gustavo Tsuboi lo di ẹru iya le Quadri lori pẹlu ami ayo 4-2 (15-13, 9-11, 6-11, 11-7, 7-11, 6-11).

Ohun to jẹ iyalẹnu ni pe ọga ni Quadri jẹ fun Tsuboi lagbo tẹniisi ori tabili lagbaaye.

Amọ Quadri ni lootọọ ni Tsuboi jẹ si oun ṣugbọn o pegede ju oun lọ ninu ere ọwọ ti awọn jọ ṣe.

Nibayii, orilẹede Naijiria ko tii ri ami ẹyẹ kankan gba ninu idije Toyo 2020 to n lọ lọwọ.