US Covid-19 Moderna Vaccine:Amẹ́ríkà fí abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 mílíọ̀nù mẹ́rin ṣọwọ́ sí Nàìjíríà

Aworan oṣiṣẹ ileeṣẹ Amẹrika ni Naijiria

Oríṣun àwòrán, United States Mission Nigeria

Àkọlé àwòrán, Awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ Amẹrika ni Naijiria n ṣe afihan abẹrẹ ajẹsara ti wọn fun Naijiria

Ijọba orileede Amẹrika ti ṣe iranwọ abẹrẹ ajẹsara Covid-19 miliọnu mẹrin ṣọwọ si orileede Naijiria.

Eyi jẹ ọna kan gbogi lati fi koju ajakalẹ aarun naa gẹgẹ bi awọn alaṣẹ Naijiria ti ṣe sọ.

Yatọ si abẹrẹ ajẹsara Moderna to kan Naijiria yi, awọn orileede Afrika mii yoo gba miliọnu marundinlọgbọn abẹrẹ yi lati ọdọ ijọba aarẹ Joe Biden.

Iranlọwọ abẹrẹ yi to jẹ ẹlẹẹkeji iru rẹ wa lara eto Covax ti wọn fi n ṣe iranwọ abẹrẹ ajẹsara fawọn orileede ti o ku diẹ kaato fun.

Awọn alaṣẹ ileeṣẹ ilera Naijiria lo gba abẹrẹ ajẹsara yi nilu Abuja tii ṣe olu ilu Naijiria.

Loṣu kẹta ọdun yi ni Naijiria tiu ṣaaju gba abẹrẹ ajsara to fẹ ẹ to miliọnu mẹrin AstraZeneca nipasẹ eto Covax yi kan naa.

Lọwọlọwọ bayi, ida kan ninu ida ọgọrun awọn eeyan Naijiria lo ṣẹṣẹ ri abẹrẹ ajẹsara gba ninu awọn eeyan igba miliọnu orileede ọhun.

Niṣe ni awọn alaṣẹ n bẹru pe ọwọja aarun Covid-19 ni Naijiria le bẹ silẹ nitori bi awọn to n ko aarun naa ṣe n pọ si lẹnu ọjọ mẹta yi.

Àkọlé fídíò, Igi Ọ̀pẹ abàmì tó dá ní orí 42 l'Ekiti rèé o, 'bí mo ṣe ríi l'orí mi ń dìde fììì'