Covid-19 herbal medicine: Ooni ṣe ìfilọ́lẹ̀ òògùn ìbílẹ̀ coronavirus

Oríṣun àwòrán, Ooni Palace
Bi orilẹede Naijiria ṣe ti n reti abẹrẹ ajẹsara coronavirus, Arole Oduduwa, Ooni Ile Ife, Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi Ojaja II ti ṣe ifilọlẹ oogun ibilẹ to le gbogun ti coronavirus atawọn arun mii ninu agọ ara.
Eto naa waye ni aafin Ile Ife nipasẹ ajọ Herbal Remedies International ti Ooni jẹ alaga rẹ pẹlu ajoṣepọ gbajugbaja oniṣegun ibilẹ, Dokita Akintunde Ayeni to jẹ oludari ati alakoso ilẹeṣẹ oogun ibilẹ YEMKEM International LTD.
Awọn ti wọn ṣẹṣẹ ṣe ifilọlẹ rẹ naa ni Verozil to n gbogun ti arun karun to ba fẹ wọ agọ ara, Bitter Leaf Capsule, eyi to n ṣiṣẹ ẹjẹ ruru ati itọ ṣuga.
- Olasunkanmi ló ń gbọ́ gbogbo bùkátà ilé títí dórí "Pampers" ọmọ, ibo ni kí n ti bẹ̀rẹ̀? - Ìyàwó Olasunkanmi Olawunmi
- Covid-19 tún ṣekú pa èèyàn mẹ́fà míì ní Nàìjíríà, èèyàn 634 míràn tún ṣẹ̀ṣẹ̀ kó o
- Abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 ń yí àwọn èèyàn sí oníbálòpọ̀ akọsákọ àti abosábo - Alfa Abbas
- Kò tíì sí ọ̀rọ̀ ìyàwó báyìí o, kí n tó lè sọ̀rọ̀ pé mo fẹ́ gbé ìyàwó, màá ...- Oba Oloyede Akinghare II
- Yajoyajo: Agbébọn tún jí akẹ́kọ̀ọ́bìnrin tó lé ni 300 gbé ní ìlú Jangebe
- Wọn ò fẹnu kò mi lẹ́nu rí tàbí lọ́ mọ́ mi lẹ́yìn ìtàgé, kí n tó di oní Hijab - Arapa re gangan
Awọn oogun mii ti wọn ṣẹṣẹ fi lọlẹ ni Vision Pro to n gbogun ti arun oju ati Rio Capsule eleyi to n ṣiṣẹ fun arun aile ṣe deedee ọkunrin pẹlu aya rẹ.
Nigba ti o ba awọn akọroyin sọrọ, Oba Ogunwusi sọ pe ko yẹ ki orilẹede Naijiria tun maa ko oogun wọle lati ilẹ okeere mọ pẹlu bi Eleduwa ti fi ewe ati egbo jinki wa nilẹ Afirika ati Naijiria papaa julọ.
Ooni sọ pe ajọ eleto ilera lagbaaye , WHO gan an fidi rẹ mulẹ pe orilẹede Naijiria ni awọn egbo to wulo fun ṣiṣe abẹrẹ fun wiwo ọpọlọlọpọ arun.

Oríṣun àwòrán, Ooni Palace
''A ko maa da eto yii ṣe lasan, inu mi dun lati sọ fun yin pe abadofin kan wa nile aṣofin agba l'Abuja bayii to da lori lilo oogun ibilẹ ni Naijiria,'' Ooni ṣalaye.
Oba Ogunwusi ṣalaye pe abadofin ọhun ni yoo maa ṣe amujoto lilo oogun ibilẹ ni Naijiria.
Ooni fikun ọrọ rẹ pe ileeṣẹ YEMKEM lo to gbangba sun lọyẹ nipa pipo oogun ibilẹ lẹyin to ti n ṣiṣẹ naa fun bii ogoji ọdun.

Oríṣun àwòrán, Ooni palace
''Lati oṣu kẹsan ọdun 2020 ni ajọ NAFDAC ti buwọlu oogun naa, ṣugbọn mo ni a gbọdọ pakeeji oogun naa daadaa ko to jade,'' Ooni lo sọ bẹẹ.
Ooni sọ pe ẹgbẹẹgbẹrun alarun coronavirus lo ti lo oogun yii ti wọn si ti ri iwosan lọwọ arun naa.
Ooni fikun ọrọ rẹ pe ohun to kan ni lati gba ẹgbẹrun lọna ọgọrun ọdọ ṣiṣẹ bayii lẹyin ti oogun naa ti jade tan.
Ẹwẹ, oludamọran agba si Aarẹ Muhammadu Buhari lori ọrọ ipese iṣẹ, Ọgbẹni Afolabi Imoukhuede to wa nibi ifilọlẹ naa gboṣuba fun Ooni fun iṣẹ takun takun to ṣe lori oogun naa.















