Attahiru Jega, APC, PDP: Ọ̀rọ̀ di gbas gbos, APC fèsì lórí ọ̀rọ̀ tí Jega sọ pé kí aráàlú má ṣé dìbo fún wọn

Ọrọ ti di gbas gbos laarin ẹgbẹ oṣelu mejeeji to lorukọ ni Naijiria,All Progressives Congress,APC,Peoples Democratic Party PDP ati alaga tẹlẹ ri ajọ eleto idibo Attahiru Jega.
Fakinfa yi ko si sẹyin ọrọ ti Ọjọgbọn Jega sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu BBC pe ki awọn ọmọ Naijiria ma se dibo fawọn ẹgbẹ yi.
Latari eyi, ẹgbẹ oṣelu PDP naa ti fesi pada ti wọn si ni ki Jega ma se fi awọn we ijọba APC ti ko seso rere fawọn ọmọ Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Others
Ṣaaju ni ẹgbẹ oṣelu APC naa ti ni ki Jega ma ṣe da awọn papọ pẹlu PDP ninu ọrọ rẹ rara ti rara nitori PDP lo ba Naijiria jẹ tawọn ṣi n gbiyanjulati ṣe atunṣe.
Kola Ologbondiyan to jẹ akọwe ipolongo ẹgbẹ PDP sọ pe Jega ṣe afihan aimọkan pẹlu bi ko ṣe ri iyatọ to wa laarin ijọba awọn ati ti APC.
O tẹsiwaju pe lasiko ijọba PDP idagbasoke ba ọrọ aje Naijiria ni afiwe ti APC to sọ ọpọ sinu iya ohun iṣẹ.
Ologbondiyan ṣapejuwe dollar to ti gbowo lori to fi mọ iye owo epo bẹntiroo to ti ga si labẹ ijọba APC.
O ni bi Jega ba foju sunukun wo, yoo ri pe awọn kii ṣe ẹgbẹ kanna pẹlu APC to n fi awọn we.
Ki ni APC sọ ṣaaju tẹlẹ lori ọrọ Jega
Ẹgbẹ́kẹgbẹ́ ní PDP lóòótọ́ ṣùgbọ́n má ṣé dà wá papọ̀ mọ wọn- APC
Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress APC to wa lori oye ni Naijiria ti fesi sọrọ Attahiru Jega to sọ pe ki araalu ma ṣe dibo fun ẹgbẹ naa.
Jega to fi igba kan jẹ alaga ajọ eleto idibo Naijiria, INEC, ko fi mọ lori APC nikan,
O ni ẹgbẹ Peoples Democratic Party ati APC ko ni akọsilẹ daadaa kankan lati nkan bi ogun ọdun ṣẹyin ti wọn ti n ṣe ijọba ni Naijiria.
APC àti PDP ló ba Nàìjíríà jẹ́, ẹ má dìbò fún wọ́n mọ́- Attahiru Jega
Ọrọ rẹ yi lo mu ki ẹgbẹ oṣelu APC tutọ soke foju gba ti wọn si sọ pe ko ma ṣe da awọn pọ mọ ẹgbẹ PDP ati pe ọrọ ti ko fẹsẹ mulẹ lo n sọ nipa awọn.
Akọwe agba ẹgbẹ igbimọ amulelọwọ APC, Sen. John James Akpanudoedehe lo fi ọrọ yi sita ninu atẹjade.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Senatọ naa ni ki Ọjọgbọn Jega mọ pe biba ẹgbẹ awọn lorukọ jẹ ko le mu agbega ba a ninu oṣelu.
''A ri nkan ti Jega kọ nibi to ti da ẹgbẹ wa pọ mọ PDP.
Lootọ ni pe PDP kuna lati ṣamuṣẹ ileri wọ́n fun araalu amọ ẹgbẹ wa lo n ṣe atunṣe gbogbo panti ti wọn da silẹ lẹyin ọdun mẹrindinlogun lori aleefa''
- Rògbòdìyàn yóò bẹ́ sílẹ̀ láàrin Naijiria àti Benin tí wọ́n bá fi Sunday Igboho sílẹ̀ báyìí- Agbẹjọ́rò
- Fúnrara Bukola Saraki ló lọ sí EFCC láti lọ yanjú ọ̀rọ̀ ara rẹ̀- Agbẹnusọ Saraki
- Bukola Saraki ti wà ní àhámọ́ àjọ EFCC
- Wo iná olójú mẹ́rìndínlógún, arugbá àtàwọn ohun míì tí yóò wáyé l'Ọdún Osun Osogbo 2021
- Oyedepo tún ti fèsì sí áwọn tó bẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ tó gbé lórí àwọn Pásítọ̀ rẹ̀
- Àwọn dókítà da iṣẹ́ sílẹ̀ káàkiri Naijiria, ilé ìwòsàn dá páròpáro!
James tẹsiwaju pe ''a ko ni maa ba Jega gba ọrọ bi ẹni n gba igba ọti nitori naa a gba a ni imọran lati lọ kọju mọ iwadii ẹkọ ko si mu aridaju jade nipa iṣesi itẹsiwaju ti ẹgbẹ APC n gbiyanju lori''
Ninu ọrọ Jega to sọ fun BBC ninu ifọrọwanilẹnuwo kan, o ni apẹrẹ ni gbogbo aburu tawọn ẹgbẹ APC ati PDP ṣe jẹ faraalu ki wọn ma dibo fun wọn mọ.
Jega ni''APC ati PDP ti 'se ijọba, a ti foju rii, wọn ko ni aniyan lati ṣe atunṣe''
''Ẹ wo nkan ti wọn sọ nipa awọn to kowo ilu jẹ,wọn lawọn yoo fiya jẹ wọn nigba ti wọn wa ni PDP, ṣugbọn nigba ti wọn pada si APC, wọn dakẹ pẹm lori ọrọ wọn ni''.
Ọjọgbọn Jega wa sọ pe idi ree ti oun fi darapọ mọ ẹgbẹ PRP lati le mu atunṣe ba Naijiria.
Titi di ba ṣe n ko iroyin yi jọ, ẹgbẹ oṣelu PDP ko ti fesi si ọrọ Jega.





















