Esabod, Sunday Igboho: Kò burú bí Igboho ṣe wà lẹ́wọ̀n báyìí,ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí i ti aláboyún tó ń rọbí ni- ESABOD

Àkọlé fídíò, Esabod, Sunday Igboho: Kò burú bí Igboho ṣe wà lẹ́wọ̀n báyìí,ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí i ti aláboyún

Ijiroro, 'Strategy'ati ifikunluku lo yẹ ko ṣaaju ki sunday Igboho to bẹrẹ ijijangbara Yoruba Nation- ESABOD

Esther Asabi Aboderin Tokunbo ESABOD to jẹ oniṣegun ibilẹ ati oludasile ileeṣẹ Esabod lo ba BBC Yoruba sọrọ lẹkunrẹrẹ lori.

Esabod ni iran Yoruba maa n gbekẹle agbara oogun, aye ati nkan amusagbara sugbọn wọn ko kii n lo ọpọlo ti oyinbo n pe ni Strategy'.

Lori ọrọ Yoruba Nation:

ESABOD ni pe iran Yoruba lo n ṣe ara wọn lati igba iwaṣẹ wa.

O ni ọrọ Yoruba Nation kii ṣe ija lasan rara bikoṣẹ ija to gba ero ati iṣẹ ọpọlọ.

Esabod

Oríṣun àwòrán, others

Esther ni pe ko si ominira ti kii mu itajẹsilẹ da ni.

O ni: Gbogbo nkan kọ ni Olorun maa ṣe lori ọrọ Sunday Igboho, ọpọlọ lo ku lọna abayọ.

O sọ ọna meji ti oun ro pe iran Yoruba le gba pẹlu Sunday Igboho lati fi jẹ ki o bọ ki iran Yoruba Nation si wa si imuṣẹ.

Kini ESABOD sọ lori ọ̀rọ̀ Iyabo Ojo, Nkechi Blessing ati TAMPAN:

Esther Aboderin Tokunbo ṣlaye fun BBC Yoruba pe TAMPAN lo gbe ẹjọ wa ba oun nigba ti wọn rii pe oun da sii.

O ni oun ati awọn Oloye ẹgbẹ naa sọrọ ni kikun lori lẹta idaduro ti wón fun Nkechi Blessing ati Iyabo Ojo.

Esabod ni ọpọlọpọ ija oṣere ni oun maa n pari funra oun.

O sọ bi wọn ṣe pada gbọrọ si oun lẹnu ti ija naa si pari nji alaafia.

Esabod

Oríṣun àwòrán, others

Lori Ere awọn Yollywood asiko yii n kọ?

Esabod ni ko si ẹkọ ti Yollywood isinyi n kọ eeyan mọ, wọn n ba aye ọdọ jẹ ni

O ni ariwo 'Won n jealus mi' ni awọn oṣere asiko yii maa n pa ti ẹ ba n ba wọn wi.

Esabod ni ere wọn ko kọnilẹkọ iwa ọmọluwabi bikose pe ko ba aye awọn ọdọ jẹ ni.

Esabod

Oríṣun àwòrán, others

Lori ọrọ Yomi Fabiyi àti Fiimu ọkọ Iyabọ?:

Esabod ni pe o yẹ ki ijọba Naijiria mu Yomi Fabiyi lọ sile ẹjọ lori fiimu ọkọ Iyabọ ni.

O ni aato inu ere naa buru jai.

Niṣe lo yẹ ki agbara ofin baa nitori pe ere naa lodi is ẹkọ ati aṣa ilẹ Yoruba.