Sunday Igboho: Rògbòdìyàn yóò bẹ́ sílẹ̀ láàrin Naijiria àti Benin tí wọ́n bá fi Igboho sílẹ̀ báyìí- Malik Olusegun Falola

Àkọlé fídíò, Ikọ BBC Yoruba ba agbẹjọro Sunday Igboho sọrọ lori idi to fi wa ni ahamọ

Ọkan lara awọn agbẹjọro ajijagbara Yoruba Nation, Sunday Ighboho, ti sọ pe wọn n daabo bo ajijagbara naa ni bo ṣe wa ninu ẹwọn lasiko yii.

Agbẹjọro naa, Malik Olusegun Falola sọ fun awọn akọroyin pe ijọba Benin mọọmọ fi Igboho si ahamọ ni, ki awuyewuye to n waye lori ọrọ rẹ le dinku.

Falola, to jẹ olukọ nipa imọ ofin ni fasiti kan lorilẹ-ede Benin Republic ṣalaye pe ofin ajọ ECOWAS ko fun ijọba Naijiria lanfaani lati gbe Igboho wa si Naijiria lati wa jẹjọ.

O ni "Ofin agbaye ati ofin ajọ ECOWAS ko fun Buhari laaye ko sọ pe ki wọn gbe Sunday Igboho wa si Naijiria lati wa jẹjọ."

Falola ni ijọba Naijiria le bere pe ki ijọba Benin gbe ẹni to ba jale tabi pa eeyan wa si Naijiria, ṣugbọn kii ṣe bii ẹni ti ko ṣẹ labẹ ofin bii Igboho.

Agbẹjọro naa sọ siwaju si pe ẹni to ba n wa aabo lori ọrọ to jọ mọ ọrọ oṣelu yoo ri abo naa gba lọwọ ijọba Benin Republic.

Àkọlé fídíò, Kemi Olunloyo on Sunday Igboho: Mi ò gbè lẹ́yìn Yoruba Nation àmọ́ mo wà lẹ́yìn Sunday Igb

O fi kun pe ajijagbara naa tun le maa gbe inu ilu naa gẹgẹ bii ẹni to lọ fi ori rẹ pamọ lai si wahala kankan.

Ni ti awọn to n funrere pe ki wọn tu Igboho silẹ, Falola sọ pe o ṣeeṣe ki igbesẹ bẹẹ da wahala silẹ laarin orilẹ-ede Naijiria ati Benin Republic.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, wọn le ṣekupa Igboho ti wọn ba tu silẹ lọwọ yii pe ko maa lọ.

O ni "Ti awọn kan ba ni ki wọn fi Sunday silẹ bayii ko le ni ominira, ẹni naa fẹ ṣekupa ni."

"To ba jẹ ilu oyinbo ni, wọn le fi silẹ ko maa lọ nitori abo to peye wa nibẹ, amọ ko si abo to peye nibi."

Àkọlé fídíò, Igi Ọ̀pẹ abàmì tó dá ní orí 42 l'Ekiti rèé o, 'bí mo ṣe ríi l'orí mi ń dìde fììì'

"To ba n lọ laarin ilu ti wọn ba yinbọn fun nkọ? Tabi ki wọn lọ sile rẹ lati lọ yinbọn nibẹ."

Falola ni bo tilẹ jẹ pe ẹwọn ni Sunday Igboho wa, ko yẹ ki wọn fi irufẹ ọwọ ti ba fi mu awọn ọdaran mu.