What is food poisoning: Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa májèlé oúnjẹ àti bí o ṣe lè dẹ́kun rẹ̀

All Nigerian Foods

Oríṣun àwòrán, All Nigerian Foods

Ọpọ eeyan lo ti maa n gbọ nipa majele ounjẹ (food poisining), ti ko mọ ohun to tumọ si.

Lọpọ igba ni awọn eeyan tilẹ ti dero ile iwosan, ti awọn dokita yoo si sọ pe majele ounjẹ ni wọn ni ṣugbọn ti wọn ko mọ ohun to ṣokunfa rẹ.

Awọn miran tilẹ lero pe ohun to tumọ si ni pe ki wọn fi majele sinu ounjẹ fun eeyan lati jẹ.

Ṣugbọn ki ni wọn n pe ni "Food poisoning" gan?

Dokita kan, to jẹ onimọ nipa itọju idile ni ile iwosan ijọba apapọ to wa niluu Owo, FMC, Olaniyi Ojo Johnson ṣalaye fun BBC ohun ti wọn n pe majele ounnjẹ.

Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola kìí ṣe agbódegbà Yahoo, Ó ń fẹ́ kí ìjọba, Òbí àti ilé ìjọsìn ṣe ohun tó y

Gẹgẹ bii ohun to sọ, awọn kokoro aifojuri kan lo maa n ṣokunfa majele ounjẹ.

O ni "Awọn kokoro ti a ko foju ri le wo inu ounjẹ tabi omi, ti yoo si maa bi si ninu irufẹ omi tabi ounjẹ bẹẹ."

Amala

Oríṣun àwòrán, Chioma Jeremiah

"Awọn kokoro naa maa n tọ awọn oje kan sinu ounjẹ, yala wọn ti ṣe ounjẹ naa ni tabi wọn ko gbe kana daadaa ko le pa awọn kokoro naa, ẹni bẹẹ le maa fi ami ailera han."

Olaniyi ni awọn ami naa maa n fara laarin wakati mẹfa pere, ailera naa si le da ge ẹmi eeyan kuru.

Àkọlé fídíò, Okunade Sijuwade: Ìfẹ́ tí Sarun tó súnmọ́ Ooni jù láyé ní sí í ló sọ ọ́ di abọ́bakú- Adeye

Iru ami wo ni ẹni to ba ni majele ounjẹ yoo ri?

Dokita Olaniyi sọ pe awọn ami to wọnpọ ju ni ki eeyan maa bi tabi ki wọn maa ṣe igbọnsẹ gbuuru.

Àkọlé fídíò, Ibeju Lekki Free Trade Zone: A ti bí ọmọ tó lọ Fásitì tí kò rí iná ọba rí- Olawale Eleto

O ni omi inu ara ni irufẹ ẹni bẹe yoo maa ya danu, ti omi inu ara eeyan ba si ti tan, iku ko jina si irufẹ ẹni bẹẹ.

O ṣalaye pe "Awọn nnkan wa ti wọn n pe ni 'electrolyte'ninu agọ ara, to ba ti jo danu ti wọn ko si tete daa pada, iku de niyẹn."

Ọna abayọ

Bo tilẹ jẹ pe Olaniyi sọ pe awọn ọmọde ati agbalaba lo wa ninu ewu to pọ ju lọwọ majele ounjẹ, o fi kun pe ti irufẹ ẹni bẹẹ ba le tete mu "ORS" ti wọn n pe ni "somi dagbo," irufẹ ẹni bẹẹ ni ireti.

Àkọlé fídíò, 'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'

Ẹwẹ, Olaniyi gba awọn eeyan nimọran lati maa gbe ounjẹ gbona daadaa ki wọn to jẹ.

Ki wọn si tun dẹkun ati maa mu omi ti ko mọ geere.

Ṣugbọn o ni ọna abayọ kankan ṣoṣo to daju ni pe ki eeyan tete kọri si ile iwosan to ba ti ri irufẹ apẹrẹ bẹẹ.

Àkọlé fídíò, Oduduwa republic: Mo kọ̀ láti kópa nínú ìwọ́de Yoruba Nations rally ni Eko- Iba Gani Adams