Erinjiyan Ekiti: Àjọ̀dún odò Ẹ̀rìn, omi tí wọn kò gbọdọ̀ pa ẹja abàmì inú rẹ̀ wáyé nílùú Erinjiyan

Ọdun Ẹrin ni ilu Ẹrinjiyan ni ipinlẹ Ekiti ni ibi ti wọn ti n kan sara si odo ẹrin ati awọn ẹja iṣẹmbaye inu odo naa.
Gẹgẹ bi itan ti kabiyesi ilu Ẹrinjiyan Ekiti, Ọba Adegoroye Oludaare Ọmọṣeebi, Adegoroye keji ṣe sọ, omi Ẹrin ti wọn n ṣe ajọyọ rẹ yii ni wọn fi ṣe iṣẹdalẹ ilu Ẹrinjiyan.
Omi ẹrin yii si jẹ nnkan pataki ti awọn eeyan ilu naa joko ti.
- Awujale Ijebu Ode, Ọba Adetona wọ́gilé àjọ̀dún Ojude Oba tọdún yìí
- Ẹ wo ibi ọ̀rọ̀ dé dúró lórí àwọn afurasí tó lọ́wọ́ nínú ikú Tolulope Arotile
- Buhari fẹ́ dá Naijiria padà sí ọdún 1984, ṣùgbọ́n a kò ní gbà fun- Femi Falana
- A ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ẹ̀sùn tí Igboho, Akintoye àti Ilana Omo Oodua gbé wa síwájú wa- ICC
- Ọmọ Naijiria 350 ni ẹ̀mí wọn sọnù nínù ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi lọ́dún 2020
Gẹgẹ bi itan ṣe sọ awọn abami ẹja kan wa ninu odo naa to jẹ pe ẹnikẹni ko gbọdọ paa. Bi eeyan kan ba paa, ko si bi wọn ṣe lee se to ṣe ni yoo maa luwẹ ninu omi gbigbona ti wọn ba fẹ fi se e.
Lasiko ajọdun odo Ẹrin yii lawọn eeyan ti maa wa n beere ohunkohun ti wọn ba n fẹ ti wọn si maa n ni ẹri ọpẹ lori ohun ti wọn ba n beere.
Gẹgẹ bi Kabiyesi Ọba Adegoroye ṣe sọ, lasiko ajọdun naa wọn a maa din akara ti awọn eeyan yoo maa ṣe wẹjẹwẹmu.
Lasiko ọdun yii naa lawọn ọmọde yoo ṣe ohun ti wọn n pe ni 'Igbo olokun' ti wọn yoo sin awọn akun si ara wọn lọ si idi odo yii. Awọn ọmọ naa yoo wọ inu igbo ti omi yii wa, ẹẹkan lọdun si wọn si maa n wọ igbo naa.
- Aya Aarẹ Ghana ati aya ìgbákejì Aarẹ Ghana ti dá gbogbo owó oṣù tí wọ́n gbà láti 2017 padà sápò ìjọba
- Ó kéré tán, ajínigbé ti pa èèyàn 222 láàrìn oṣù mẹ́ta ní Kaduna- Gomina El Rufai
- Ìjọba Gombe kọ́ iléẹ̀kọ́ tuntun sí ẹgbẹ́ àwọn iléeṣẹ́ elétò aàbò kí ọwọ́ ajínigbé má tẹ̀ akẹ́kọ̀ọ́ mọ́
- Mọ si nípa àbá òfin tí yóò mú kí ìjọba ìpínlẹ̀ Ekiti le gbẹ́sẹ̀ lé ilé tàbí ilé ìtura tí ífipá bálòpọ̀ bá ti wáyé
- Wọ́n ní Ìyá Esabod yẹn ma ń ṣépè, fi òṣèré wọ́lẹ̀, mò ń retí èsì yín sí ọ̀rọ̀ tí mo fi síta yìí - Mr Portable
- Kò sọ́jà mọ́! A ti ti Ọjà Ladipo pa nítorí rògbòdìyàn tó bẹ́ sílẹ̀ níbẹ̀ - `ijọba ìpínlẹ̀ Eko
- Oríire ńlá ló jẹ́ fún àwọn ọmọ Naijiria pé orílẹ̀-èdè yìí ṣì wà ní ọ̀kan ṣoṣo- Buhari











