Nigeria security, Kaduna Kidnapping: Ó kéré tán, ajínigbé ti pa èèyàn 222 láàrìn oṣù mẹ́ta ní Kaduna- Gomina El Rufai

Oríṣun àwòrán, other
Obinrin mẹsan an ati ọmọde mẹjọ wa ninu awọn ti agbebọn pa nipinlẹ Kaduna.
O kere tan eniyan to le ni igba ti padanu ẹmi wọn laaarin Oṣu Kẹrin si Oṣu Kẹfa, ọdun 2021
Ninu atẹjade ti ijọba ipinlẹ Kaduna fi lede ni wọn ti sọ wi pe eniyan to le ni ẹẹdẹgbẹrin ni awọn ajinigbe ti jigbe lọ nipinlẹ naa.
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ọkùnrin tó gbé ọ̀kadà iléesẹ́ sá lọ lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́
- Sunday Igboho, Akintoye àtàwọn míràn fa Buhari, Malami àtàwọn míì lọ síwájú ilé ẹjọ́ àgbáyé ICC
- Oríire ńlá ló jẹ́ fún àwọn ọmọ Naijiria pé orílẹ̀-èdè yìí ṣì wà ní ọ̀kan ṣoṣo- Buhari
- Gbẹgẹdẹ gbiná, ṣọ́jà àtàwọn jàǹdùkú fìjà pẹẹ́ta lọ́jà Ladipo l'Eko
- Mr. Portable sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí Mr. Latin lórí gbas-gbos tó ń wáyé lágbo òṣèré tíátà Yoruba
- Ìjọba Gombe kọ́ iléẹ̀kọ́ tuntun sí ẹgbẹ́ àwọn iléeṣẹ́ elétò aàbò kí ọwọ́ ajínigbé má tẹ̀ akẹ́kọ̀ọ́ mọ́
- Gbàgbé ẹ! Ìjọba kò lè yọwọ nínú fifi ọba jẹ láéláé- Oba Tejuosho
Ninu atẹjade ti ẹka eto aabo nipinlẹ naa gbe jade ni wọn ti fi lede pe eniyan 239 ninu awọn ti wọn jigbe naa jẹ ọbinrin ti mejilelọgbọn si jẹ ọmọde.
Obinrin mẹsan ati ọmọde mẹjọ wa ninu awọn ti wọn pa.
Iye awọn ti wọn farapa ninu ijamba naa le ni igba eniyan (266), ti mejidinlogun ninu wọn si jẹ obinrin ati ọmọde marun un.
Bakan naa ni ifipabanilopo waye ni ipinlẹ ogun kaakiri orilẹede Naijiria, ti mẹtala ninu wọn si jẹ ọmọde.
Awọn ẹṣọ alaabo ninu atẹjade naa ni awọn gbiyanju lati pa awọn agbebọn mẹtadinlaadọrun, ti awọn si fi panpẹ mu eniyan mẹrinlelogun ninu wọn laarin oṣu mẹta naa.
Bakan naa ni wọn ji ẹgbẹrun mẹjọ maluu gbe laarin asiko yii, ti wọn si pa eniyan ẹẹdẹgbẹta laarin Oṣu Kini,ọdun 2021 si Osu kẹta, ọdun 2021.
Ijọba ipinlẹ Kaduna fikun pe ijinigbe yii ti ba ọrọ aje ipinlẹ naa jẹ, ti awọn agbẹ si ti kuro ni oko nitori oro oko wọn ti awọn agbebọn ti bajẹ.
Bakan naa ni ijọba ni awọn n tiraka lati koju iṣoro eto aabo to dẹnukọlẹ naa, ti gbogbo igbiyanju wọn si n gberasoke ju ti tẹlẹ lọ.
Ẹwẹ, Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kaduna ni awọn ẹsọ alaabo amuṣẹya ni awọn ti doola ẹmi akẹkọọ kan ninu awọn mọkanlelọgọfa ti wọn ti gbe lọ.
- Aya Aarẹ Ghana ati aya ìgbákejì Aarẹ Ghana ti dá gbogbo owó oṣù tí wọ́n gbà láti 2017 padà sápò ìjọba
- Gbàgbé ẹ! Ìjọba kò lè yọwọ nínú fifi ọba jẹ láéláé- Oba Tejuosho
- Ọkùnrin márùn-ún tí wọ́n bá lórí kerewà bọ́ sọ́wọ́ Ọlọ́pàá ẹ̀sìn Islam
- Ohaneze Ndigbo lẹ́tọ̀ọ́ láti gba agbẹjọ́rò fún Nnamdi Kanu- Malami
- 'Lóòtọ́ èmi ni mo ṣagbátẹrù òpó alátagbà Airtel lọ sí Ago Owu ṣùgbọ́n kìí ṣe àkànṣe iṣẹ́ agbègbè mi'
- Àwọn Aṣòfin yọwọ́ nínú àbádòfin tí yóò máa fòfin de àwọn akọ̀ròyìn lẹ́yìn tí wọ́n fẹ̀hónúhàn
Èèyàn 2,371 ni wọ́n jí gbé, N10biliọnu owó ìtúsílẹ̀ làwọn ajínigbé gbà lóṣù mẹ́fà àkọ́kọ́ ọdún 2021
Àbájáde ìwádìí ní èèyàn 2,371 ni wọ́n jí gbé, N10biliọnu owó ìtúsílẹ̀ làwọn ajínigbé gbà lóṣù mẹ́fà àkọ́kọ́ ọdún 2021
Laarin oṣu kini si ikeje ọdun 2021, ẹgbẹrun meji o le ọdunrun ati mọkanlelaadọrin lawọn eeyan ti awọn ajinigbe ti ji gbe kaakiri awọn ipinlẹ mẹrẹẹrindinlogoji to wa lorilẹ-ede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, other
Ajọ aṣewadi nipa ọrọ aje ti orukọ rẹ n jẹ SBM Intelligence lo kede eyi loju opo ayelujara rẹ.
Ajọ naa ni eyi jẹ abajade iwadi kan eyi ti wọn ṣe lori wahala ati ipenija abo lorilẹede Naijiria.
- Wo òtítọ́ nípa oúnjẹ Nódùùlù táwọn ọmọde máa ń jẹ
- Mi ò lè fọwọ́ sí àbáòfin kankan tí yóò fòfin de iṣẹ́ akọ̀ròyìn - Femi Gbajabiamila
- Irọ́ ni o! Awujale ilẹ̀ Ijebu kò wàjà, ẹ sinmi ariwo
- A gbọ́dọ̀ fi àwọn olùwọ́de Yorùbá Nation sí àhámọ́ fún ọjọ́ 21, bí bẹ́ẹ̀ kọ́.....- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko
- Ẹ fọkàn balẹ̀, Wakili ò gbèrò láti ṣe ìkọlù sí Igangan àti Ibarapa lọ́jọ́ Ileya- Ọ̀gá ọlọ́pàá Oyo
Gẹgẹ bi abajade iwadi naa tun ṣe yọju rẹ sita, ipinlẹ Niger, Katsina ati Kaduna lo n gbegba oroke niti iṣẹlẹ ijinigbe lorilẹ-ede Naijiria.
Nigba ti iwadi naa wa n gbe owo to rọ mọ ijinigbe naa yẹwo, o ni titi di ọgbọn ọjọ oṣu kẹfa ọdun 2021, biliọnu mẹwaa naira lawọn eeyan ti san gẹgẹ bii owo itusilẹ fun awọn eeyan wọn ti wọn ji gbe laarin asiko naa.

Oríṣun àwòrán, @SBM Intelligence
Ilakalẹ abajade iwadi wọn naa tun sọ di mimọ pe losu keji ọdun 2021 nikan eeyan marunlelẹgbẹta (605), ẹẹdẹgbẹta o le mẹrinlelọgbọn ni awọn ajinigbe ji gbe loṣu kẹta, ọtalelọọdunrun o din mẹta ni oṣu marun un.bakan naa lo fi han pe ojilelẹgbẹta ati mẹta 643 ni wọn ji gbe ni ipinlẹ Niger ti wọn si pa mejidinlọgọta.
Okoolelẹẹdẹbẹta o din ẹyọkan (519) ni wọn ji gbe ni Zamfara ti mejilelogun si ku.
Ni ipinlẹ Kaduna ọtalelọdunrun ni wọn ji gbe, mọkanlelogoji leyan to jade laye nipasẹ iṣẹlẹ ijinigbe nibẹ.
- A ti gbé ìgbésẹ̀ láti pèsè agbẹjọ́rò tó dántọ́ kí Kanu lè rí ìdájọ́ òdodo gbà - Ohaneze Ndigbo
- Ìròyìn òfegè ni pé Alabi Yellow jáde láyé lánàá
- Wo ìgbésẹ̀ tí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ń gbé lẹ̀yìn tí wọ́n rí ẹ̀dà Covid-19 "Delta variant" tuntun níbẹ̀
- Ẹ fọkàn balẹ̀, Wakili ò gbèrò láti ṣe ìkọlù sí Igangan àti Ibarapa lọ́jọ́ Ileya- Ọ̀gá ọlọ́pàá Oyo
- Wo ìlú kan ní Italy tó ṣetán láti fún ọ ní N13.6 mílíọ̀nù tí o bá gbà láti gbé níbẹ̀
- Wọ́n ti yọ ojú òpó 'GoFundMe' tí wọ́n ṣí fún Baba Ijesha ní Ireland kúrò lórí ayélujára
Agbekalẹ awọn ipinlẹ yoku niwọnyii: Abia (6), Abuja (50), Adamawa (3), Akwa Ibom (2), Anambra (14), Bauchi (3), Bayelsa (7), Benue (6), Borno (1), Cross River (4), Delta (51), Ebonyi (5), Edo (18), Ekiti (14), Enugu (15).
Bakan naa, ipinlẹ Eko (6), Nasarawa (44), Ogun (26), Ondo (17), Osun (23), Oyo (61), Plateau (10), Rivers (14), Sokoto (10), Taraba (46), ati Yobe (4) Gombe (1), Imo (25), Jigawa (2), Kano (3), Katsina (236), Kebbi (81), Kogi (31) ati Kwara (10).
.





















