Peter Fatomilola: Àsìkò ti tó kí ìpinyà wa, kí kaluku mójútó ọ̀rọ̀ ajé rẹ̀- Peter Fatomilola

Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola: Robbery burú ju Yahoo lọ, iṣẹ́ ọpọlọ lọmọ Yahoo fi ń gba owó ìran baba

Owó táwọn Òyìnbó jẹ Babańlá Yorùbá ní àwọn ọmọ Yahoo-yahoo ń gbà padà- Peter Fatomilola

'Robbery' burú ju Yahoo lọ, iṣẹ́ ọpọlọ lọmọ Yahoo fi ń gba owó ìran baba wọn padà lọ́wọ́ Oyinbo amúnisìn

Oyinbo ko iran baba nla Yoruba lẹru fun ọdun 500 pélu ọpọlọpọ iya- Peter Fatomilola

Agbaọjẹ oṣere ati olukọ Yoruba, Alagba Peter Fatomilola lo sọrọ nipa awọn ọmọ Yahoo ati ọrọ ki Yoruba da duro.

Fatomilola

Oríṣun àwòrán, @Fatomilola

O ni iṣẹ ọpọlọ lawọn ọmọ Yahoo n ṣe lati gba owo ti iran oyinbo jẹ baba nla iran Yoruba ti wọn ko lẹru.

O ni ọmọ Yoruba ko ṣa a deede maa ṣe yahoo. airise se lo n fa a.

Fatomilola ni Obi. alagbatọ ati Ijọba lo fa ohun to n sun awọn ọdọ si iṣẹ yahoo.

Peter Fatomilola ni gbogbo ọna loun fi faramọ 'Yoruba Nation'

O ni ko si ohun to buru ninu ti iran Yoruba, Igbo ati Hausa ba ni ki onikaluku lọ da ọmọ iya ẹ gbe.

O ni ti onikaluku ba pin lọtọọtọ, ẹnu a ka awọn adari wa, a maa le fẹnuko ba wọn wi.

Lori ọrọ Sunday Igboho:

Sunday Igboho kii ṣọmọ ale rara ni Peter Fatomilọla fi bẹrẹ ọrọ lori ọrọ Sunday Igboho ti apeja rẹ n jẹ Oloye Sunday Adeyemọ.

Peter Fatomilola ni gbogbo ara ni oun fi faramọ ijijangbara awọn akoni ọdọ Yoruba bii Sunday Igboho.

Fatomilola

Oríṣun àwòrán, @fatomilola

Peter Fatomilola ni igba gbogbo ni oun maa n gbadura fun Sunday Igboho nitori pe Yoruba Nation se koko bayii.

O ni ki a kọkọ ja fun orilẹ-ede ti wa ki a to maa yanju ọrọ tani yoo ṣe olori orilẹ-ede Yoruba Nation.

Fatomilola

Oríṣun àwòrán, others