Sheik Gumi: Iléeṣẹ́ Ológun Nàìjíríà kìlọ̀ fún Sheikh Gumi pé kó ṣọ́ ẹnu rẹ̀ lórí àwọn agbébọn

Oríṣun àwòrán, Others
Ileeṣẹ ologun lorilẹede Naijiria ti ṣekilọ fun gbajumọ asaaju ẹsin musulumi ni, Sheikh Ahmad Abubakar Gumi pe ko ṣọ ẹnu rẹ lori ọrọ awọn agbebọn lorilẹeede Naijiria.
Ileeṣẹ ologun fesi si ọrọ kan ti gbajumọ alfa musulumi kanSheikh Gum sọ lori eto mohumaworan kan.
Sheikh Gumi sọrọ kan Laipẹ yii lori eto mohunmaworan kan pe awọn kan wa to n lẹdi apo pọ tabi ṣe agbodegba fawọn agbebọn naa.
- A kò gbọ́ pé Sunday Igboho fẹ́ ṣe ìwọ́de ní ìpínlẹ̀ Eko- Kọmisọ́nnà ọlọ́pàá
- Kí ló mú Olorì Badrat Ajoke kúrò ní ààfin Oyo lọ́jọ́ Iléyá?
- Ẹ̀yin ọmọ Yoruba, ẹ múra láti dìbò ''referendum'' kúrò ní Naijiria, ìjọ̀ba àpapọ̀ à ń bò- Banji Akintoye
- Mo nírètí pé Baba Ijẹsha yóò gba béèlì ní iléẹjọ́ tí yóò tí farahàn lónì - Yomi Fabiyi
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo àti àwọn ẹlẹ́sìn àbáláyé bẹ̀rẹ̀ àjọṣepọ̀ láti fí opin sí ìṣoro ètò aàbò
- Buhari ní kí ilé aṣòfin àgbà buwọ́lu N895b gẹ́gẹ́ bíi àfikún owó ètò ìṣúná ọdún 2021
Gumi ni ijakulẹ ijọba lo bi wahala agbebọn ati pe pupọ wọn gan ni ko dagba to awọn ti wọn ji gbe lọ.
O ni awọn agbebọn kii jini gbe pa bikose lati pawo sapo.
Alukoro ileeṣẹ ọmọogun oriilẹ, Onyema Nwachukwu ṣalaye ninu atẹjade kan pe irõ pata ni Gumi n pa mọ awọn ologun lati ba a lorukọ jẹ.
O ni lootọ awọn amunibuni lee wa laarin awọn ologun sugbọn ileeṣẹ ologun ko ni faye gba awọn agbẹyinbẹbọjẹ laarun wọn, ọmọogun ti ọwọ ba wa tẹ yoo gba idalẹbi rẹ ni ibamu pẹlu ofin ologun ile Naijiria.
O wa rọ awọn majẹkobajẹ lawujọ pe wọn maṣe sọ ara wọn di odaluru letu to le tun fẹ wahala abo to wa nilẹnloju sii.
- Gọngọ́ sọ, àwọn Ṣọ́jà lé ọlọ́pàá lùgbẹ́ lágọ́ ọlọ́pàá l' Osogbo
- Ọwọ́ ọlọ́pàá ti tẹ̀ ẹni méjì tó lọ́wọ́ nínú àgbo tó pa ẹni mẹ́wàá ní Kwara
- Ẹ̀yin ọmọ Yoruba, ẹ múra láti dìbò ''referendum'' kúrò ní Naijiria, ìjọ̀ba àpapọ̀ à ń bò- Banji Akintoye
- Iyabo Ojo, eléyìí tẹ ṣe lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha tó, tó bá ṣẹ̀yín kí ẹ dáríjì - Ọlọfaina bú sẹ́kún
- Ta ló gbé ìròyìn ikú ẹlẹ́jẹ̀ nípa Wòlìí SK Abiara, kí ní wọ́n sì ṣe fún un?
- Ẹ̀bùn owó, oúnjẹ, aṣọ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ní ìkókó mú wọlè fún ẹbí Kemisola Ogunniyi ní Ondo
Pipa ní wọ́n gbọ́dọ̀ pa àwọn agbébọn tí wọ́n ń jí àwọn ènìyàn gbé, ẹ da ọ̀rọ̀ Sheik Gumi nù -Aisha Yesufu
Gbajugbaja ajafẹtọ ọmọniyan ni Naijiria, Aisha Yesufu ti sọ wi pe awọn oṣiṣẹ alaabọ ni aṣẹ lati pa awọn agbebọn ti wọn n ji awọn eniyan gbe paapaa awọn akẹkọọ.

Oríṣun àwòrán, Others
Yesufu to sọrọ naa loju opo ayelujara rẹ ni awọn agbebọn ti ṣekupa ọpọlọpọ eniyan, ti wọn si ti sọ di alairile gbe, nitori naa ijọba nilo ati pa wọn run.
O sọ ọrọ yii tako ọrọ ti Ilumooka àlfá ẹṣin Islam kan to tun máa n ba awọn àgbesunmọmi at'awọn ajinigbe sọrọ pẹlẹ kutu, Sheik Gumi to ni ki i ṣe pipa awọn agbebọn ni ọna abayọ si eeto aabo to dẹnukọlẹ ni Naijiria.
- 'Kò sí ẹni tó lè ní kí a má wá sí Èkó, iwọ́de òní pẹ̀lẹ́ kùtù la fẹ́ ṣe'
- Ó yẹ kí ìjọba wá ǹkan fi tan àwọn ajínigbépawó, ǹkan bíi owó, iṣẹ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ
- Ohun tó dára fún ètò ọ̀rọ̀ ajé wá ni láti yá owó fún ṣíṣe ojú pópó wá - Fashola
- Gómìnà ṣàbẹ̀wò sí àwọn tí ọlọ́pàá yìnbon lù l'Enugu, Ọ̀gá ọlọ́pàá ní ìwádìí gbọdọ̀ wáyé kíákíá
- Father's Day fa gbas-gbos láàrin Mercy Aigbe àti ọkọ rẹ̀ tẹ́lẹ̀, Gentry, ọkọ́ ní òun le tú àwọn àṣírí ìwà nọ̀bì rẹ̀ síta
- Ìgbẹ́jọ́ Kemisola Ogunniyi kò wáyé lóní, ó tún dọ̀la, ṣùgbọ́n... - Agbẹjọ́rọ̀
Gumi lasiko to n ba ileeṣẹ iroyin Punch sọrọ ni o to egberun lọnà ọgọrun agbebon lo wa ni iha Ariwa Iwo Oorun Naijiria nikan.
O ni pipa awọn agbegbọn yoo ba nkan jẹ si ni nitori awọn agbebọn naa ko ka iwe, nitori naa ẹni to ba pa wọn, pipa ni wọn yoo ma a pa awọn ti wọn ba jigbe.
Amọ, Yesufu ni awọn ọdaran ni awọn agbegbọn, ti Ọlrun si lọwọ si pe ki wọn fi iya jẹ awọn aṣeka ni awujọ.
''Ẹ gbọdọ pa awọn agbebọn nitori wọn ti pa ọpọlọpọ eniyan, ti wọn si ti ba ile ati ọna jẹ kaakiri orilẹ-ede Naijiria''
''Ọlọrun sọ wi pe ki a ma jẹ ẹlẹṣẹ tabi ọbayejẹ, bakan naa lo si sọ pe ki a ma kẹyin si wọn tabi ṣe bi ẹni pe wọn ko si ni aye.''
- Kò sí ìpínlẹ̀ tí ijọba mi kò tíì fọwọ́ bà sí rere- Ààrẹ Muhammadu Buhari
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ẹni ọdún 40 tó fipá bá ìyá ọdún 60 lòpọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun
- A kò gbọ́ pé Sunday Igboho fẹ́ ṣe ìwọ́de ní ìpínlẹ̀ Eko- Kọmisọ́nnà ọlọ́pàá
- Ó yẹ kí ìjọba wá ǹkan fi tan àwọn ajínigbépawó, ǹkan bíi owó, iṣẹ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ
- Lẹ́yìn ìjà tò gbẹ̀mí èèyàn bíi mẹ́ta, Makinde sè ìfilọ́lẹ̀ ìgbìmọ̀ àlákòóso Amọtẹkun
- 'Kò sí ẹni tó lè ní kí a má wá sí Èkó, iwọ́de òní pẹ̀lẹ́ kùtù la fẹ́ ṣe'
''Nitori naa awọn ẹsọ alaabo gbọdọ ṣekọlu si awọn agbebọn naa ati gbogbo awọn ọbalaye to n pa awọnb eniyan kaakiri''
Alfa Gumi yìí ni dandan, o di igba ti ijọba ba ba awọn Fulani darandaran sọrọ, ko lè sí ileewe kankan ti abo rẹ daju.















