Àwọn ṣọ́jà ya bo àgọ́ ọlọ́pàá láti tú akẹgbẹ́ wọn, afurasi ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn sílẹ̀ l' Osogbo

Oríṣun àwòrán, OsunMap
Gọngọ sọ, àwọn ṣọjà lé ọlọ́pàá lùgbẹ́ lágọ́ ọlọ́pàá l' Osogbo
Ipaya gbode lagbegbe Ọbẹlawọ lagbegbe opopona to lọ si ilu Ikirun nilu Osogbo lalẹ ọjọ Isẹgun nigna ti awọn ṣọja mẹta kan yabo agọ ọlọpaa to wa lagbegbe naa lati tu akẹgbẹ wọn tawọn ọlọpaa mu si atimọle silẹ.
- Buhari ní kí ilé aṣòfin àgbà buwọ́lu N895b gẹ́gẹ́ bíi àfikún owó ètò ìṣúná ọdún 2021
- Ẹranko àìmọ́ kan wọ Nàìjíríà, ó pa ènìyàn mẹ́rin ní Benue- ilé iṣẹ́ ọmọogun ni ìròyìn òfegè ni
- Ẹ̀yin ọmọ Yoruba, ẹ múra láti dìbò ''referendum'' kúrò ní Naijiria, ìjọ̀ba àpapọ̀ à ń bò- Banji Akintoye
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo àti àwọn ẹlẹ́sìn àbáláyé bẹ̀rẹ̀ àjọṣepọ̀ láti fí opin sí ìṣoro ètò aàbò
- Mo nírètí pé Baba Ijẹsha yóò gba béèlì ní iléẹjọ́ tí yóò tí farahàn lónì - Yomi Fabiyi
Iroyin abẹle jẹ ko di mimọ pe awọn ọmọogun naa bẹrẹ si nii yinbọn soke kikan-kikan nigba ti wọn de agọ ọlọpaa naa eleyin to mu ki awọn ọlọpaa at'awọn ara adugbo o sa asala fun ẹmi wọn.
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe awọn ẹlẹgbẹ okunkun kan lawọn ọlọpaa mu si atimọle.
Amọṣa ọkan ninu wọn jẹ ibatan ṣọja kan ; ṣọja naa lo wa gba mọlẹbi rẹ naa silẹ.
Lasiko ti wọn n sọrọ pẹlu awọn ọlọpaa naa ni ariyanjiyan bẹ sílẹ ti awọn ọlọpaa naa fi fi si atimọle lai mọ pe o ti kan sawọn akẹgbẹ rẹ ṣaaju.
- Ẹ̀bùn owó, oúnjẹ, aṣọ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ní ìkókó mú wọlè fún ẹbí Kemisola Ogunniyi ní Ondo
- Ẹ̀wọ̀n ọdún méje gbáko ni adájọ́ sọ pé kí Farouk Lawan fi ṣara ridin!
- Ilé ẹjọ́ ECOWAS pàṣẹ fún Naijiria láti gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí òfin tó fi de Twitter
- Ta ló gbé ìròyìn ikú ẹlẹ́jẹ̀ nípa Wòlìí SK Abiara, kí ní wọ́n sì ṣe fún un?
- Àwọn lọ́balọ́ba nílẹ̀ Yoruba dalẹ̀ wa lórí àwọn ọmọ OPC mẹ́ta tí wọ́n tímólé láìṣẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ Iskilu Wakili - Ẹgbẹ́ OPC
- Yinka Alaṣeyori fi ọ̀rọ̀ ìjínlẹ̀ púpọ̀ àti omijé ṣàlàyé Oniduro Mi
Laipẹ lawọn ṣọja mẹta de tijatija ni nnkan bii agogo mẹjọ alẹ lati fi tipa yọ akẹgbẹ wọn ni ahamọ ọlọpaa.
Elomiran to ṣoju rẹ ni awọn ọlọpaa to wa lagọ ọlọpaa nibẹ bẹrẹ si ni yinbọn soke lati le wọn sẹyin, ṣugbọn nigba to ya lawọn ọlọpaa naa doju ibọn kọ wọn ṣugbọn ko ran wọn.
Awọn ṣọja naa le awọn ọlọpaa to wa ni agọ naa danu ki wọn to tu akẹgbẹ wọn silẹ.















