Buhari,N895 extra budget: Buhari ní kí ilé aṣòfin àgbà buwọ́lu N895b gẹ́gẹ́ bíi àfikún owó ètò ìṣúná ọdún 2021

Buhari

Oríṣun àwòrán, others

Buhari ń bèrè N895b àfikún owó ètò ìṣúná ọdún 2021 láti ra abẹ́rẹ́ Covid-19 àti ohun ìjà ogun

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ke si ile igbimọ aṣofin agba lati buwọlu wo ti iye rẹ le ni biliọnu mẹjọ naira gẹgẹ bii afikun oeo eto iṣuna ọdun 2021.

Aarẹ ile naa, Ahmed lawan lo kede bẹẹ lasiko to n ka iwe ti Buhari fi ṣọwọ si ile ọhun lẹyin ti igbimọ aṣejọba Buhari ti kọkọ buwọlu owo ọhun ṣaaju.

Lara owo ọhun ni wọn sọ pe awọn yoo lo lati ra awọn ohun ija fun ileeṣẹ ọmọ ogun lọna ati gbogun awọn ọmọ ẹgbesumọmi atawọn janduku.

Ijọba apapọ yoo tun lo lara owo naa lati ra abẹrẹ ajẹsara Covid-19 atawọn irinṣẹ miran ni ẹka eto ilera Naijiria.

Lẹta ọhun ka pe "Inu mi dun lati kọwe si yin pe ki ẹ buwọlu afikun owo eto iṣuna ti ọdun 2021."

"Iye owo ti a n bere fun ni N895,842,465,917.00."

Àkọlé fídíò, Kò sí ẹni tí mo fura sí lórí ikú ọkọ mi, àmọ́..- Adebisi aya Titus Ejanla tí wọ́n pa ní Ib

Yatọ si abẹrẹ Covid-19 ati ohun ija fun ileeṣẹ ọmọ ogun ti ijọba apapọ fẹ ra, wọn ni awọn yoo tun lo lara owo naa lati ṣe itọju awọn eeyan bii ẹgbẹrun lọna aaḍota to ni arun kogboogun HIV/AIDS labẹ eto NCAPS.

Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola: Robbery burú ju Yahoo lọ, iṣẹ́ ọpọlọ lọmọ Yahoo fi ń gba owó ìran baba

Gẹgẹ bi iwe naa ṣe sọ, ileeṣẹ ọmọ ogun nilo awọn ohun ija igbalode lati koju awọn janduku, bakan naa ni ijọba fẹ ṣeto awọn afẹfẹ eemi gaasi kakiri Naijiria.

Àkọlé fídíò, End SARS: Kemi jáde níle láti lọ bá mi ra oògùn ni mo gbọ́ pé ọlọ́pàá ti gbée- Ìyá Kemisol

Aarẹ Buhari sọ pe yatọ si owo yii, awọn inawo kan ṣi wa ti ijọba fẹ ṣe, ṣugbọn awọn yoo ko gbogbo rẹ sinu eto iṣuna ọdun to n bọ eyii ti awọn yoo gbe wa siwaju ile naa titi oṣu Kẹsan an ọdun yii.

Lẹyin naa lo bere fun atilẹyin awọn ọmọ ile aṣofin naa lati tete buwọlu afikun eto iṣuna ọhun ki iṣẹ le bẹrẹ ni kankan.

Àkọlé fídíò, Fulani attack, Ajowa Ondo: Àwọn Bororo yìí ti kọ́kọ́ ń dàná ní Ajọwa tẹ́lẹ̀, ọmọ mi 5 di

Bayii, ijoko ile Igbimọ Asofin ti waye lati ka ibeere Buhari lẹẹkeji ni ana nile igbimọ Asofin ni Abuja.

Ohun to ku naa ni ki awọn ọmọ ile igbimọ Asofin ka a lẹẹkẹta ki wọn si fẹnuko lori boya wọn fi ọwọ sii tabi bẹẹkọ.

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, @MBuhari

Kò sí ìpínlẹ̀ tí ijọba mi kò tíì fọwọ́ bà sí rere- Ààrẹ Muhammadu Buhari

Ààrẹ Muhammadu Buhari ni kò sí ìpínlẹ̀ kan ni Nàìjíríà tí ìjọba òun kò tíì fọwọ́ bà nípa isẹ àkànṣe amáyédẹrùn.

Buhari so èyí níbi ìpàgọ́ àwọn ẹ̀ka ọ̀dọ́ All Progressive Congress tó wáyé ní gbongan International Conference Centre, Abuja l'ọ́jọ́ Aje.

Lorí ètò ààbò, ààrẹ Buhari tí akọ̀wé ìjọbaa àpapọ̀, Boss Mustapha ṣojú fún ṣàlàyé pé ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá ká ìbọn mọ́ lọ́wọ́ lọ́nà aitọ́ yóò fojú wina òfin.

Àkọlé fídíò, Fulani attack, Ajowa Ondo: Àwọn Bororo yìí ti kọ́kọ́ ń dàná ní Ajọwa tẹ́lẹ̀, ọmọ mi 5 di

Boss Mustapha rọ àwọn ọ̀dọ́ láti hùwà tí yóò mú itẹsiwaju bá orílẹ̀ èdè yìí àti àwọn tikara wọn.

"Aarẹ náà gbà pé lóòótọ́ orileede yìí ń kojú ìṣòro ètò àbò tó mẹ́hẹ, láti orí ìdí gùn jalè ojú pópó, ìjínigbé, ìgbésùmọ̀mí àwọn darandaran agbébọn to ń pá àwọn àgbẹ̀ àti àwọn tó ń pànìyàn ni ìhà ila-oorun Gúsù."

Boss Mustapha fi wọn lọ́kàn balẹ pé ìjọba yìí yóò fòpin sí gbogbo pálapàla tó wà nílẹ̀ yìí pàápàá jùlọ lórí ètò àbò tó mẹ́hẹ.

Àkọlé fídíò, End SARS: Kemi jáde níle láti lọ bá mi ra oògùn ni mo gbọ́ pé ọlọ́pàá ti gbée- Ìyá Kemisol

Boss Mustapha ni: "Gbogbo èrò ìjọba, isẹ àkànṣe àti yiyan awọn eniyan sipo ni ìjọba yìí ṣe ní ìlànà ọgbọọgbà fún gbogbo ẹ̀yà.

"Kò sí ìhà ibikan ni orilẹ-ede yìí tí ìjọba kò tíì fọwọ́ bá ní ọ̀nà tó ni ìtumọ̀, yálà nípa ṣíṣe ohun amáyéderùn, ètò ọgbìn, tàbí bí nnkan ti ẹkùn kọọkan bá nílò ṣe ṣe pàtàkì sí.