Kebbi kidnap, Nigeria Army: Mo ṣetán láti wọ inú igbó lọ wa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jígbé- Gomina ìpínlẹ̀ Kebbi

Kebbi

Oríṣun àwòrán, Facebook/Prounitate

Ọmọ ogun ilẹ̀ Nàìjíríà ti dóòlà ẹ̀mí díẹ̀ nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jígbé ní ìpínlẹ̀ Kebbi

Ọmọ ogun ilẹ̀ Nàìjíríà ti dóòlà ẹ̀mí díẹ̀ nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jígbé ní ìpínlẹ̀ Kebbi

Ileeṣẹ ologun ilẹ̀ Naijiria ti kede pe wọn ti ri mẹrin ninu olukọ ati akẹkọọ pada.

Ogagun agba Onyema Nwachukwu salaye pe, wọn ti da ọpọ omo ogun lọ si agbegbe naa lati wọnu igbo lọ.

Lọjọ Eti ni awọn ọmọ ogun kọkọ doola ẹmi olukọ meji ati akẹkọọ marun un leyin ti wọn kọlu awọn ajinigbe naa.

Ni ọsan ni awọn ajinigbe naa yabo ile ẹkọ FGC Birnin Yauri Secondary School, ti wọn si ji awọn akẹkọọ ati olukọ gbe

Àkọlé fídíò, 'Ọwọ́ mi ti ń jẹ́rà ká tó mọ̀ pé àfi kí wọ́n tún gé e bí mo bá ṣì fẹ́ máa ṣe iṣẹ́ awakọ̀ lọ'

Mo ṣetán láti wọ inú igbó lọ wa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jígbé- Gomina ìpínlẹ̀ Kebbi

Ijọba Kebbi n gbiyanju lati doola gbogbo awọn ti wọn ji gbe

Gomina Abubakar Atiku Bagudu sọ pe oun ṣetan lati ṣaaju awọn to n lọ wa awọn ti ajinigbe ji.

Kebbi

Oríṣun àwòrán, Bagudu Facebook

Gomina ipinlẹ Kebbi, Abubakar Atiku Bagudu sọ pe o tẹ oun lọrun lati saaju awọn to n lọ wa akẹkọọ ti wọn jigbe.

O ni ko ni oun lara lati wọ inu igbo ti wọn gbagbọ pe wọn ko awọn ọmọ naa pamọ si lọ.

Gomina Bagudu sọrọ yii nigba ti o n sepade pẹlu Gomina Kayode Fayemi ti ipinlẹ Ekiti ati Gomina Badaru Abubakar ti ipinle Jigawa.

Gomina Kebbi ni oun ko ni lọ si ọffisi mọ bikoṣe lati tẹle awọn ọdẹ aṣọgbo lọ.

O ni mo seleri lati wọ inu igbo lọ pẹlu awọn ọdẹ lati lọ gba awọn akẹkọọ ti ajinigbe ji gbe ni Kebbi.

Àkọlé fídíò, End SARS: Kemi jáde níle láti lọ bá mi ra oògùn ni mo gbọ́ pé ọlọ́pàá ti gbée- Ìyá Kemisol

O ni ki awọn ọdẹ aṣogbọ bẹrẹ ipalẹmọ pe ni kete ti awọn osisẹ eleto aabo ba ti ni o ya ni oun naa setan.

Bayii, Ijoba ipinlẹ Kebbi ti ti awọn ile ẹkọ meje pa nitori iṣẹlẹ ijinigbe to waye ni Federal Government College, Birnin Yauri,.

Àkọlé fídíò, 'CAC Agbala Itura ni mo ti bẹ̀rẹ̀ ìlú lílú kí ń tó máa bá Janet, àbúrò Michael Jackson lù Gangan àti Omele'

Wọn fi eyi sita ninu atéjade wọn ti wón fi ṣalaye bi wọn se ri eeyan mẹrin gba ninu awọn ti wọn ji gbe nile ẹkọ Yawuri Secondary School nipinlẹ Kebbi.

Ileeṣẹ ologun ni' Awon ọmọ ogun Operation Endangered Forest ati awọn omọ ogun ofurufu Naijiria lo ri wọn ko.

Ogagun agba Onyema Nwanchukwu to buwọlu atẹjade naa ni ẹmi ọmọ ogun kan bọ si iṣẹlẹ naa.