Nigeria Military plane and Nasarawa cow killing: Ṣé lóòtọ́ ni àwọn ọmọ ogun òfurufú Nàìjíríà ṣèèṣì pa máàlú 1,000 ní Nasarawa?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ibeere ti ọpọ n beere ni pe ṣe awon ọmọ ogun ilẹ̀ Naijiria ko tun riran ri maalu mọ yató si awọn ọmọogun ọlọtẹ tabi awọn agbesunmọmi ni?
Iroyin naa ni pe ọkọ ofurufu awọn ọmọ ogun ilẹ̀ Naijiria kan lo deede lọ pa maalu to le ni ẹgbẹrun kan.
Iroyin naa ni pe ikọlu naa waye si awọn darandaran Fulani ni agbegbe ijoba ibile Keana ati Doma ni ipinlẹ Nasarawa ni aarin gbungubn Naijiria.
Sugbọn oludari ifitonileti fun ileeṣẹ ọmọ ogun ofurufu Naijiria, Ogagun Edward Gabkwet salaye fun BBC pe ọrọ ko ri bẹẹ.
- Mọ̀ si i nípa ìtàn eégún Gelede àti pàtàkì eégún náà sí àwọn obìnrin nílẹ̀ Yoruba
- Mo kú tì, nítorí pé àsìkò mi kòì tó láti padà sí ọ̀run- Kunle Ologundudu
- Sójà obìnrin lù mí lálù bami nílùú Ibadan
- Ọkọ́ mi lá àlá pé bàálù já, kó tó kú nínú ìjàmbá bàálù lọ́jọ́ kẹta - opó olóògbé
- Ìwádìí rèé lórí gbas-gbos tó wáyé lórí ikú ọmọogun òfúrufú l'Oshodi l‘Ọ́jọ́bọ
Kini Ileeṣẹ ọmọ ogun ofurufu Naijiria sọ?
Edward ni pe ko si maalu kan to ku laisko ikọlu sawọn oniṣẹ ibi agbegbe naa.
O ni nitooto ni ikọ ọmọ ogun kọlu awọn oniṣẹ ibi ni agbegbe naa lati wagbo dẹkun fun wọn.
Kini awọn Fulani Darandaran sọ?
Ọ̀rọ̀ ṣọtọọtọ lẹnu olori awọn darandaran Fulani Makiyaya National Association, Muhammad Kiruwa Ardon Zuru.
Zuru sọ fun BBC pe ikọ omọ ogun ofurufu Naijiria ṣe ikọlu laarin ọjọ Bọ, ọjọ kẹwaa si ọjọ Aiku, ọjọ kẹtala oṣu kẹfa yii.
- Èèmọ̀! Ọmọogun 20 sọnù sínú ìjàmbá ọkọ̀ òfurufú mẹ́ta lóṣù mẹ́ta
- Ó pé ọdún mẹ́wàá tí Barrister kú; wo ǹkan tó yẹ láti mọ̀ nípa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi olórin, tẹ̀wé-tẹ̀wé, akọ̀wé àti sọ́jà
- Ariwo ẹkún sọ níbi ìsìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja
- Walter Carrington ràn mí lọ́wọ́ kí ń lè sá àsálà lásìkò tí Abacha ń wá mí kiri- Obasanjo
O ni a gba iroyin pe awọn kan n ji ẹran ko salọ kuro ni agbo ẹran awọn eeyan wa lasiko igba naa.
Ardon Zuru tun nni pe nitootọ ko si ẹni to fara pa ṣugbọn ikọlu naa mu ẹmi awọn ẹran kan lọ nigab ti awọn miran ṣesẹ.
O ni: A n reti abọ kikun lati ọdọ awọn adari ẹkun naa ki a to le sọ nipato iye adanu naa.
A maa wa fi apapọ iye to jẹ ranṣe si alaga igbimọ ati Sultan Sokoto ni kikun.















