Military Plane Crash: Opó Alfred Onifade ń ṣèdárò ikú ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú ohùn arò

Oloogbe Alfred ati Jeniffer aya rẹ

Oríṣun àwòrán, joba_star/Instagram

Adura nla ni pe ki ọba oke jẹ ki tọkọ taya lo ara wọn pẹ, ki wọn ma si tete di opo ọsan gangan.

Jeniffer Olufade, tii se opo ọkan lara awọn awakọ baalu to ba isẹlẹ baalu ologun to ja rin, Alfred Olufade ti n fi itara ati omije se idaro iku ọkọ rẹ.

Olufade, to n fi ohun aro sọrọ loju opo Instagram rẹ salaye pe ọkọ oun ti la ala ni oru mọju Ọjọbo Ogunjọ osu Karun pe baalu oun ja.

Alfred ati Jeniffer, ti wọn se igbeyawo alarinrin ni osu mẹta sẹyin salaye pe aago mẹrin idaji Ọjọbọ naa ni ọkọ oun ji oun loju oorun pe oun la ala abaadi naa.

Oloogbe Alfred ati Jeniffer aya rẹ

Oríṣun àwòrán, joba_star/Instagram

"Tibẹru tibẹru lo fi ji mi loju oorun pe o la ala pe baalu rẹ ja nigba tẹ n lọ si Kaduna, o ni se ni ala naa da bi tootọ.

Mo gbadura taratara fun ọ nidaji ọjọ naa, mo si fi ọ lọkan balẹ pe ko ni si ewu, ti mo si tun bi ẹ nipa akọsilẹ ilana ibi tẹ n lọ ati awọn ti o ba kọwọrin.

O sọ fun mi pe Asaniyi, mo si ni ko maa lọ, ko ni si ewu, arinye lo maa rin."

Jeniffer tẹsiwaju pe lootọ ni ọkọ oun lọ si Enugu, Owerrri ati Abuja, ti awọn si dijọ pe ara awọn pẹlu ẹrọ ayaworan fidio, tawọn si sọrọ fun igba pipẹ.

Àkọlé fídíò, A ti ń fẹ́ Hausa, Ibo, ó sàn ka jọ ṣe é ní tùbí-ǹ-nùbí lórí ọ̀rọ̀ Nàìjíríà ju ìjà ogun lọ - Ọba Alara

"Se ni o sa n rẹrin musẹ ninu fidio naa, ti n ko si fura pe akoko ikẹyin rẹ niyẹn tabi pe igba ikẹyin to rẹrin si mi ree.

Lẹyin igba naa lo tun fi atẹjisẹ ransẹ pe ẹ n lọ si Kaduna, kia ni ami ara sọ mi, ọkan mi ko balẹ mọ, mo n sare pe ẹ pada fun ọpọ igba, amọ o ko gbe ipe mi.

Mo fẹ bẹ ọ pe ko ma lọ si Kaduna, aya mi bẹrẹ si ja."

Jeniffer tun salaye pe Iyan ati ọbẹ ẹgusi ni ọkọ oun sọ fun oun fẹ jẹ ni ọsan ọjọ naa ti oun ba de lati Kaduna, amọ ikede ọfọ rẹ ni oun gbọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Obinrin opo naa wa n beere pe bawo ni oun se fẹ se igbe aye oun, bawo ni oun se fẹ da jẹun lai si ọkọ oun nitori awọn dijọ maa n se ohun gbogbo papọ ni.