Yemi Osinbajo: Fídíò tó ṣàfihàn bí ìjàmbá bàálù rẹ̀ ṣe wáyé

Baalu naa lẹyin to ja lulẹ.

Oríṣun àwòrán, Twitter/@akandeoj

Àkọlé àwòrán, Baalu naa lẹyin to ja lulẹ.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ti fi fidio kan sita, ti wọn fi ṣapejuwe bi ijamba baalu to ṣẹlẹ si Igbakeji aarẹ, Yẹmi Ọṣinbajo ṣe waye lọjọ Abamẹta, ọjọ keji, oṣu keji.

Ni ọsan ọj Abamẹta ni iroyin jade pe Ọṣinbajo ni ijamba lasiko to n lọ si ilu Kabba, ni ipinlẹ Kogi fun ipolongo ibo oun ati Aarẹ Muhammadu Buhari.

Botilẹjẹ wi pe ori ko Ọṣinbajo atawọn to wa ninu baalu naa yọ, ọpọlọpọ ọmọ Naijiria ti ba kẹdun, ti wọn si n ba dupẹ lọwọ Ọlrun fun idasi ẹmi rẹ.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Amọ ṣa, oludije fun ipo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu alatako, PDP, Atiku Abubakar ti ki Ọṣinbajo ku oriire fun bi ori ṣe ko o yọ ninu ijamba baalu lọjọ Abamẹta.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Ninu ọrọ tiẹ, Aarẹ ile aṣofin agba, Bukọla Saraki naa fogo fun Ọlọrun fun igbeaye Igbakeji Aarẹ.

O ni ''Mo darapọ mọ gbogbo ọmọ Naijiria lati dupẹ lọwọ Ọlọrun to da ẹmi Igbakeji Aarẹ, Yẹmi Ọṣinbajo si, to mu kori ko o yọ̀ ninu ijamba baalu ni Kabba loni."

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Bakan naa ni akẹgbẹ rẹ nile aṣofin kekere, Yakubu Dogara to ba Ọṣinbajo yọ, sọ pe ki awọn alaṣẹ to n mojuto awọn ọkọ ofurufu ijọba maa ṣe ayẹwo wọn daada lati ri daju pe iru iṣẹlẹ bayi ko waye mọ.

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Ninu ọrọ tiẹ, Gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayoṣe, sọ pe ''Mo ba Igbakeji Aarẹ yọ, mo si dupẹ lọwọ Ọlọrun fun pe o da ẹmi rẹ si. Mo gbadura pe ọgbẹ yowu to ba ni yoo tete san.

Ni iwoye temi o, ọrọ ẹmi lagbara ju oṣelu lọ, mo si gbadura pe ki Ọlọrun tubọ maa da ẹmi rẹ si.''

Skip X post, 5
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 5

Yatọ si awọn oloṣelu, awọn ọmọ Naijiria naa n ba igbakeji aarẹ yọ fun idasi ẹmi rẹ.

Amọ ṣa, atẹjade kan ti ọọfisi Igbakeji Aarẹ fi sita, Ọṣinbajo dupẹ lọwọ gbogbo ọmọ Naijiria to ba a dawọ idunnu, o si fi da wọn loju pe alaafia ni oun ati awọn to wa ninu baalu to ja ọhun wa."

Ati pe ''Ọlọrun gba wa lọwọ iku, ki a le raaye ṣe ọpọ nkan fun awọn eniyan wa ati orilẹede yii.''