Fola Alade biography: Ayàwòrán tó ya 1004 estate àti àwọn ilé ìjọba Naijiria tó làmì-laaka dolóògbé

Fola Alade

Oríṣun àwòrán, Others

Ọkan lara awọn ayaworan ile 'Architect' to kọkọ kawe jade ni Naijiria, Ọmọwe Folayan Alade ti ku.

Ọjọ Satide ni Alade ku lẹni ọdun mẹtadinlaadọrun.

Wọn bi Alade ni ilu Aramọkọ-Ekiti ni ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 1933.

Tani Fola Alade?

Ilu Aramọkọ lo ti lọ si ileẹkọ alakọbẹrẹ, ko to lọ si Christ's School, Ado-Ekiti laarin ọdun 1946 si 1951.

O kọkọ lọ si Nigerian College of Technology, Ibadan lọdun 1954 si 1956.

Lẹyin naa ni Alade kẹkọọ jade ni Nigeria College of Arts & Sciences and Technology, Zaria (to ti di Ahmadu Bello University bayii) ni ọdun 1961, gẹgẹ bi ikan lara awọn akẹkọọ nipa yiya aworan ile mẹrin akọkọ.

Fola Alade

Oríṣun àwòrán, NIGERIAN INSTITUTE OF ARCHITECTS

Lẹyin naa lo kawe si ni Architectural Association School of Tropical Studies, London, ni ọdun 1965, pẹlu eto ẹkọ ọfẹ ajọ Commonwealth.

Oun ni ayaworan ile akọkọ to di Akọwe Agba fun ijọba apapọ ni ọdun 1976.

Ipo naa lo wa titi di ọdun 1979 to fẹhinti, lati lọ da ileeṣẹ ara rẹ, Fola Alade Associates silẹ lọdun 1980.

Àkọlé fídíò, End SARS: Kemi jáde níle láti lọ bá mi ra oògùn ni mo gbọ́ pé ọlọ́pàá ti gbée- Ìyá Kemisol

Fola Alade, 'Architect' tó ya àwòrán ọ̀pọ̀ ilé àti ọ́fíísì tí Naijiria ní ti kú!

Lẹyin to tun kẹkọọ gboye si, o di ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ Royal Institute of British Architects ati Architect Registration Council ti United Kingdom lọdun 1963.

O darapọ mọ ileeṣẹ ijọba apapọ Naijiria to wa fun ile kikọ ati awọn akanṣe iṣẹ ni Western Region gẹgẹ bi Ayaworan ile Agba.

Lọdun 1969, o di Oludari akọkọ fun ẹgbẹ to n mojuto awọn ayaworan ile ni Naijria, Architects Registration Council of Nigeria.

Wọn yan gẹgẹ bi baba'salẹ ati alaga igbimọ oludari Federal University ni Port Harcourt lọdun 1990.

Àkọlé fídíò, 'CAC Agbala Itura ni mo ti bẹ̀rẹ̀ ìlú lílú kí ń tó máa bá Janet, àbúrò Michael Jackson lù Gangan àti Omele'

Awọn ile nlanla ati ọfiisi ijọba ti Folahan Alade ya aworan rẹ

•Armed Forces Rehabilitation Centre, Oshodi, Lagos (1970-71).

•Ileeṣẹ ijọba apapọ, Ikoyi 1972-75

•Ileeṣẹ ijọba apapọ ni awọn ipinlẹ ni Naijiria (1973-76)

•Ọfiisi aarẹ ni Dodan Barracks, Eko

•1004 estate, Victoria Island, Eko

•Ile igbalejo ileeṣẹ ijọba apapọ nilu Eko

•Greek Military Hospital, pẹlu ileegbe awọn dokita ni Ikoyi, Eko

1004 estate

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, 1004 estate, Victoria Island, ọkan lara awọn ile awodamiẹnu ti Fola Alade ya aworan rẹ

•Awọn ileeṣẹ aṣoju 'Embassies & Chancerie' Naijiria to ya, to si mojuto kikọ wọn ni:

i. Nigerian Embassy & Chancery at Brazilia, Brazil

ii. Nigerian Embassy & Chancery at Bonn, Germany

iii. Nigerian Embassy & Chancery at Rome, Italy

iv. Nigerian Embassy & Chancery at Washington

v. Nigerian Embassy & Chancery at Pecking, China.

Àkọlé fídíò, 'Ọwọ́ mi ti ń jẹ́rà ká tó mọ̀ pé àfi kí wọ́n tún gé e bí mo bá ṣì fẹ́ máa ṣe iṣẹ́ awakọ̀ lọ'

vi. Nigerian Embassy & Chancery at Coutonou, Benin

vii. Nigerian Embassy & Chancery at Lome, Togo.

viii. Nigerian Embassy & Chancery at Freetown, Sierra, Leone

ix. Nigerian Embassy & Chancery at Monrovia, Liberia.

x. Nigerian Embassy & Chancery at Younde, Cameroon

xi. Nigerian Embassy & Chancery at Islamabad, Pakistan

xi. Satellite Town, Eko

Àkọlé fídíò, 'Sister Tope Alabi yà mí lẹ́nu gan o pé "Oniduro mi" kìí ṣe orin tó yẹ kí ọlọ́run fún mi'

xii. Baraaki awọn ọmọ ogun ofurufu, Air Force Base, Ikeja ati Makurdi.

xiii. National Institute (NIPSS), Kuru, Jos

xiv. The National Remembrance Arcade & Tafawa Balewa Sq., Shopping Complex.

xv. National Institute for Sports, National Stadium, Surulere

Awọn miran ni:

i. Ileewosan ikọṣẹ iṣegun oyinbo ni Obafemi Awolowo University, Ile-Ife

ii. Elephant Cement House, Alausa Ikeja.

iii. Federal Secretariat, Plot 4, Central Area,. Abuja

iv. Ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ekiti State Government

v. National Judicial Institute, Abuja.

Àkọlé fídíò, Life saver car: Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ yì ti gba ẹ̀mí ọ̀pọ̀ aláboyún àtọmọ ọwọ́ lá ní Jigawa