Enugu Police Man Shoots Five: Ọlọ́pàá yìnbọn pa èèyàn márùn ún, mẹ́rin míì ń gbà ìtọjú nílé ìwòsàn

Oríṣun àwòrán, ENUGU STATE GOVERNMENT
Gomina ipinlẹ Enugu Ifeanyi Ugwuanyi ti ṣabẹwo sawọn eeyan to farapa ninu iṣẹlẹ ti ọlọpaa ti yinbọn lu awọn araadugbo Golf Estate ni Enugu.
Eeyan mẹrin lo n gba itọju lọwọ ni ileewosan naa ti Gomina si ti sọ pe ijọba yoo san owo itọju wọn.
Ṣaaju ni Kọmisana ọlọpaa ipinlẹ Enugu ọga ọlọpaa Mohammed Aliyu ti sọ pe ki awọn araalu ran ọlọpaa lọwọ pẹlu iroyin to le tan imọlẹ si iṣẹlẹ ọhun.
- Kolade Johnson; Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ọwọ́ ti tẹ àwọn afurasí ọlọ́pàá tó ṣekúpaá
- Ìgbìmọ̀ tó n gbọ́ ẹ̀sùn tako àwọn ọlọ́pàá SARS ní Eko fún opó kan àti èèyàn mẹ́ta mìí ní 16.2m Naira
- Ọmọ Nàíjíríà kan kú lásìkò tó bẹ́ sí River Thames ní London torí ó fẹ́ dóòlá ẹ̀mí obìnrin kan
- Ọlọ́pàá gbé àwọn tó yìnbọn lu olólùfẹ́ ní Ajegunle
- Àgùnbánirọ̀ t'ọ́lọ́pàá yìnbọn pa wọlẹ̀ sùn
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ afurasí ọlọ́pàá tó yìnbọn fún ọ̀dọ́kùnrin tó fún èèyàn lóyún s'átìmọ́lé
Ninu atẹjade ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Daniel Ndukwe fi sita, wọn ni nkan bi ago mẹsan abọ aarọ ọjọ Aiku ni iṣẹlẹ naa waye.
Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, niṣe ni Inspẹkitọ ọlọpaa kan to wa ni Golf Estate ni Enugu ṣina fawọn eeyan ti eeyan marun un si ku ninu iṣẹlẹ yi.
Awọn mẹrin miran to farapa wa ni ile iwosan ilẹ ẹkọṣẹ iṣegun fasiti Enugu, ESUT.

Oríṣun àwòrán, Enugu state government
Ọga ọlọpaa ṣalaye pe awọn ti mu ọlọpaa naa ti o si ti wa ni ahamọ titi tawọn yoo fi pari iwadii.
Wọn ko darukọ ọlọpaa ti ọrọ yi kan tabi ohun to ṣẹlẹ to fi yinbọn lu awọn eeyan.













