Folajimi Olubunmi-Adewole: Àwọn òbí rẹ̀ ní adóòlá ẹ̀mí kò ṣaáyan tó láti dóòlà ọmọ náà ló fa ikú rẹ̀

Folajinmi Olubunmi-Adewole

Oríṣun àwòrán, Screen Shot/SkyNews

Folajimi Olubunmi-Adewole: Àwọn adóòlá ẹ̀mí kò gbìyànjú tó láti dóòlà ọmọ wa lásìkò tó ń dóòlà ẹlòmíràn - Obi Jimi

Awọn ẹbi ọdọkunrin kan to ku lẹyin to kan lu odo River Thames niluu London, lati doola ẹmi obinrin kan to ko sinu odo naa ṣaaju, ti di ẹbi iku rẹ ru awọn tó wa oku rẹ ninu odo ọhun.

Won ni o ṣeéṣe kí ọmọ wọn ṣi wa láàyè, to ba jẹ pé wọn fi kun ìgbìyànjú wọn lati tete se awari rẹ ni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọdọkunrin náà ti orukọ rẹ n jẹ Folajimi Olubunmi-Adewole, ti ọpọ eeyan mọ sí Jimi, n bọ lati ibi isẹ rẹ lasiko to ri obinrin kan to re bọ sínú odò náà.

Idi ree ti Jimi àti ẹlòmíràn kan lu odo ọhún lati doola obinrin naa ni nnkan bíi aago méjìlá òru.

Awọn ẹbi Folajinmi Olubunmi-Adewole

Oríṣun àwòrán, Screen Shot/SkyNews

Lẹyin o rẹyin, ileeṣẹ to n ri sí ètò àbò orí omi ati ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ri sí ọrọ ori omi, doola obinrin naa sugbọn Jimi di awati.

Aago mẹfa aarọ ọjọ keji ni ọlọpaa sọ pé wọn tó ri oku ẹnikan to fara jọ ọmọ ogun ọdún náà.

Ṣugbọn baba oloogbe naa, Michael Adewole ati iya rẹ Olasunkanmi Adewole, ti n pé fún idajọ òdodo lori iku ọmọ wọn.

Ìyá ọmọ náà sọ fún àwọn akọroyin pẹlu omije loju pe "Ni ṣe ni ọmọ mi n gbiyanju lati gba ẹmi ẹlòmíràn la, nitori naa ìdájọ òdodo ni mo fẹ."

River Thames nilu London ti Jimi bẹ si

Oríṣun àwòrán, Screen Shot/SkyNews

Baba rẹ sọ pé èèyàn dáadáa ni ọmọ oun, oniwa tutu sí ni pẹlu, bẹẹ ni ọpọ èèyàn lórí ayelujara ti n kan sara si oloogbe ọhun gẹgẹ bíi akínkanjú èèyàn.

Lara àwọn tó gboriyin fún Jimi ni Mayor ti ilu London, Sadiq Khan, ẹni to sọ pe ọmọ gidi ni fún ọkàn akin to ni.

Baba ọmọ náà ni igbiyanju awọn ọlọpaa lati kan lu omi lati ṣawari ọmọ oun ko to, ko to dakẹ sinu omi.

Baba, iya ati Folajinmi Olubunmi-Adewole

Oríṣun àwòrán, Screen Shot/SkyNews

Ṣugbọn awọn adoola ẹmi sọ fún àwọn akọroyin pe, awon sa ipa wọn lati ṣawari rẹ loru ọjọ ti iṣẹlẹ naa waye ṣugbọn awọn kò ri.

Wọn ní nígbà tó di aago kan kọjá ogun iṣẹju loru, ni wọn dẹkun wiwa rẹ ki wọn tó rí oku rẹ laarọ ọjọ keji.

Amin iyasọtọ kan

Ikú Jelili kó lọ lásán, iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ Jonathan ọlọ́pàá tó ṣekúpa ní Quilox

Aworan ọlọpaa to yinbọn pa Jelili

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police

Inspẹkitọ ọlọpaa to yinbọn pa arakunrin kan Jelili Bakare ni ile igbafẹ Quilox ni ipinlẹ Eko ni wọn ti gba aṣọ lọrun rẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko lo fi ikede yi sita ninu atẹjade kan ti Muyiwa Adejobi alukoro ọlọpaa buwọlu.

O ni Komisana ọlọpaa ni Eko Hakeenm Odumosu ni awọn ko ni faaye gba iru iwa bayi laarin awọn agbofinro.

Lọjọ Kejidinlogun oṣu Kẹta ọdun yi ni Inspẹkitọ Jonathan Kompani yinbọn pa Jelili Bakare gbajumọ oniṣowo ni adugbo Lekki.

Gẹgẹ bi iroyin to jade, niṣe ni ọta ibọn ba Jelili ni aaye igbafẹ Quilox nigba tawọn ọlọpaa to wa ni Thera Peace Estate Sangotedo ṣadede bẹrẹ si ni yinbọn.

Inspẹkitọ Jonathan ati Jelila n fa ọrọ mọ arawọn lọwọ nitori pe Jonathan ni oun fẹ tu ara Jelilil wo ṣugbọn ti Jelili ni oun ko ni gba.

Lasiko iṣẹlẹ yi, wọn sọ pe Inspekitọ Jonathan ti mọti yo ti ko si bikita ẹnikẹni ti ọta ibọn rẹ baa le ba.

Eyi kii ṣe igba akọkọ ti awọn ọlọpaa yoo yinbọn pa araalu ti ariwo si ti pọ nigboro pe ki awọn ọga ọlọpaa ma ṣe foju fo aṣiṣe yi mọ.

Ohun to kan bayi ni pe Jonathan yoo foju ba ile ẹjọ.