Oduduwa Republic Agitators: Bí Oyetola ṣe lé ọ̀gá iléèwé mẹ́tẹ́ẹ̀ta jẹ́ àfihàn ìwà ìkórira sí wa

Oríṣun àwòrán, Koiki Media
Ẹgbẹ apapọ awọn eeyan to n beere fun idasilẹ orilẹede Yoruba, labẹ aburada Oduduwa Republic Agitators (ORA), ti sọrọ soke lori isẹlẹ to waye nipinlẹ Osun laipẹ yii.
Bẹẹ ba gbagbe, ijọba Osun pasẹ pe ki ọga ileẹkọ giram mẹta lọ rọọkun nile na nitori bi awọn eeyan to n beere fun iyapa orilẹede Naijiria se wọnu ọgba ileewe wọn lati fa oju awọn akẹkọọ ibẹ mọra.
Amọ nigba to n sọ ero rẹ lori isẹlẹ yii, ẹgbẹ ORA ni oun yoo seto atako alagbara nipinlẹ Osun lori igbesẹ ijọba naa nitori iya to fi jẹ awọn ọga ilẹẹkọ naa.
- Oluwo, tí wọ́n bá rán ọmọ níṣẹ́ ẹrú, kó fi t'ọmọ jẹ - Gani Adams
- Sùkẹ̀! Ọ̀rọ̀ òṣèlú ni gbogbo ẹ tí Akeredolu ṣe tako ìdásílẹ̀ Oduduwa Nation - Banji Akintoye
- A ò pe Sunday Igboho lọ́mọ alè Yorùbá o àmọ́, a ó jọ́ bèrè lọ́wọ́ Alálẹ̀ Ibadan àti gbogbo Yorùbá ni - Olubadan
- Ẹgbẹ́ tó ń fẹ́ Oduduwa Republic kọ̀wé ẹ̀hónú sí UN, EU, AU àti ìjọba Gẹ̀ẹ́sì
- Kò sí Oduduwa Nation kankan ni ilẹ̀ Iwo! Kí n má gbọ́ ọ - Oluwo
- Àwọn ọ̀nà tá gbà rèé tí orílẹ̀èdè Oduduwa yóò fi tẹ̀ wá lọ́wọ́ - Gani Adams
Atẹjade kan ti aarẹ ẹgbẹ agbaye fun Oduduwa Republic Agitators Worldwide (ORA), Segun Damilola Olaniyan fisita lo sisọ loju ọrọ naa.

Oríṣun àwòrán, ODUDUWA REPUBLIC AGITATORS/Facebook
Ẹgbẹ ORA ni bi gomina ipinlẹ Osun, Adegboyega Oyetola se ni ki awọn ọga ileẹkọ mẹtẹẹta naa lọ rọọkun nile fihan pe o korira awọn eeyan to n ja fun orilẹede tuntun naa.
Bakan naa ni wọn leri leka pe loore koore ni awọn yoo maa fi ẹhonu han lori isẹlẹ naa titi ti gomina Oyetola yoo fi da ọga ileẹkọ mẹtẹẹta naa pada.
"A ri igbesẹ gomina Osun gẹgẹ bii iwa ikorira si awọn eeyan to n polongo fun idasilẹ orilẹede Yoruba, a si tako igbesẹ odi to gbe naa pẹlu iwọde alagbara.
Awọn ọga ileẹkọ naa gbe igbesẹ naa tori ẹtọ ti wọn ni labẹ ofin lati seto ipolongo ni ayika naa.
Gbogbo ọba alaye ati agba ijoye nipinlẹ Osun la fun ni atẹjade yii, ki a le fi isẹlẹ yii to wọn leti."
Ẹgbẹ ORA tẹsiwaju pe oun ti ri daju pe ilẹ Yoruba nikan ni awọn asaaju oselu kii se atilẹyin fun ifẹ araalu nitori ifẹ tara wọn.
Ẹgbẹ naa ni oun lero pe gomina naa yoo se afihan iwa ọmọluabi nipa yiyi igbesẹ rẹ pada ki awọn ọga ileewe mẹtẹẹta le pada si ẹnu isẹ ni kiakia.
Ẹgbẹ ORA ni ti gomina Oyetola ba gbe igbesẹ naa, eyi to tubọ mu ki ifẹ tawọn ni si ru gọgọ si nitori baba ati arakunrin awọn lo jẹ.





















