Hope Uzodinma: ''Civil defense'' méjì àti ọlọ́pàá kàn wá lára àwọn tó faragba ikọlù ilé Gómìnà

Oríṣun àwòrán, OBINNA ONWUKA
Ijọba ipinlẹ Imo s pe ikọlu tawọn agbebọn ṣe sile Gomina Hope Uzodinma lọwọ oṣelu ninu.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Kọmisana feto ibaraẹnisọrọ nipinlẹ naa sọ pe iṣẹlẹ naa waye lẹyin wakati diẹ si'gba ti Gomina Uzodinma ṣabwo si aarẹ Buhari.
O ni yatọ si ikọlu ti wọn ṣe si ile ti Gomina maa n sun si yi wọn tun kan si ile ijọba ipinlẹ Imo to wa ni Owerri ti wọn si n kọrin ọtẹ ṣugbọn ko si ni to koju wọn.
Ko daju boya awọn ọmọ ẹgbẹ aabo Eastern Security Network,ESN, lo wa nidi ikọlu yi ṣugbọn ijọba ni o lọwọ oṣelu ninu.
Bakan naa wọn lawọn ti bẹrẹ iwadii lati mọ awọn to wa nidi ọrọ naa.

Oríṣun àwòrán, Nigerian Presidency
Àwọn agbébọn ti jó ilé Gómìnà ìpínlẹ̀ Imo, wọ́n tún pa ọdẹ ilé rẹ̀
Awọn aworan to n jade loju opo ayelujara fihan pe awọn agbebọn ti lọ sile gomina ipinlẹ Imo, Hope Uzodinma.
Wọn jo awọn ọkọ ayọkelẹ to wa nibẹ.
Wọn pa aṣọde kan to jẹ ọkunrin lara awọn to n ṣọ ile naa.

Oríṣun àwòrán, Screenshot/Twitter
Wọn tun pa awọn ọkunrin meji ti wọn n rin bọ lopopona to wọ adugbo naa.
Awọn agbebọn ti ẹnikẹni ko tii le sọ bi wọn ṣe jẹ naa jo ile aṣole to wa ninu ile gomina naa.
Wọn yabo ile naa laipẹ yii ni abule Omuma.
Titi di asiko ti iroyin yii n jade, awọn ijọba ati agbofinro ni wọn ko tii le sọrọ.

Oríṣun àwòrán, Obinna Onwuka
Sugbọn ẹni ti iṣẹlẹ naa ṣoju ẹ kan sọ fun BBC pe ẹni mẹta lo ba iṣẹlẹ naa rin ti wọn ti ri oku wọn.
Iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ lasiko ti Gomina Uzodinma ṣi wa ni Abuja.
Agbegbe Omuma yii jẹ iwọn irin wakati mẹta si Owerri to jẹ olu ilu ipinlẹ Imo.












