Democracy Day: Wo àwọn ààrẹ alágbádá tó ti jẹ ní Nàìjíríà láti ìgbà òmìnira di àkókò yìí

Awọn aarẹ orilẹede Naijiria

Oríṣun àwòrán, Goodluck Jonathan

Bọmọde o mọ itan, yoo ba arọba nitori arọba gan an ni baba itan.

Ẹyin n woo pé kí lo ba owe yii wa.

Ọrọ to kan yin, to kan mi ni o, ọrọ ijọba awaarawa lorileede Naijiria la n sọ.

Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lẹyin ijijagbara lọwọ ijọba amunisin ilẹ Gẹẹsi, Naijiria gba ominira lọjọ kinni oṣu kẹwaa ọdun 1960.

Bayii ni ijọba awaarawa ṣe bẹrẹ ni Naijiria eyi to mu ki Nnamdi Azikiwe di aarẹ àkọkọ ninu itan orileede Naijiria ti Alhaji Abubakar Tafawa Balewa si jẹ Olootu ijọba.

Hmmm... Yoruba kare lai! Wọn ní ile to ba n toro, ọmọ ale ibẹ ni ko tii dagba.

Nnamdi Azikwe ati Tafawa Balewa

Oríṣun àwòrán, Nigerian Facts and History

Lọjọ kẹẹdogun osu kinni ọdun 1966 lawọn ologun ditẹ gbajọba ninu eyi ti wọn ti ṣekupa Tafawa Balewa at'awọn olori ijoba mii bii Samuel Ladoke Akintola to jẹ olori ijoba ilẹ Yoruba nigba naa.

Ọdun mẹtala gbako ni Naijiria lo loko ẹru ijọba ologun.

Àmọ́, orileede Naijiria pada si ijọba awaarawa lọdun 1979 lẹyin ti Ọgagun Olusegun Obasanjo gbe ijọba fun alagbada ti gbogbo ilu dibo yan, Alhaji Shehu Shagari.

Bayii ni Shagari ṣe di aarẹ abaṣẹ-waa akọkọ lorileede Naijiria.

Aarẹ ana Naijiria Shehu Shagari

Oríṣun àwòrán, Shehu Shagari film documentary

Shagari lo ọdun mẹrin fun saa akọkọ, Koda o tun wọlé ẹkeji lọdun 1983.

Àmọ́, awọn ologun tun gbeṣe wọn dé, ọdun 1983 yii naa ni wọn tun fipa gbajọba.

Ọdun mẹwaa ni ijọba ologun tun fi dari orileede Naijiria ki aarẹ fidihẹ Oloye Ernest Shonekan to gori oye lọdun 1993 lẹyin ti Ọgagun Ibrahim Babangida wọgile ibo aarẹ to gbe Moshoodi Kashimawo Olawale Abiola wọlé.

Ṣugbọn oṣu perete bayii ni Oloye Shonekan lo ki Ọgagun Sani Abacha to gbajọba lọwọ rẹ.

Aarẹ fidihẹ

Oríṣun àwòrán, Earnest Shonekan

Oju ọmọ Naijiria ri to laye Abacha, ẹyin naa rántí?

Ṣebi ẹ mọ pe ẹni ti Ọlọhun ko le mu, faabada, ko tii da iru eeyan bẹẹ.

Lẹyin ti ijọba Abacha milẹ titi fún ọdun marun gbako, iku wọlé mu ùn lọ lọdun 1998.

Iku Abacha ko maa mu opin ba ijoba ologun ni Naijiria!

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ogagun Abdulsalami Abubakar lori gori aleefa, amọ oun naa lo gbejoba pada falagbada lọdun 1999.

Ṣe ẹ mọ pe, ori ti yoo ba Dade, ko ní ṣá lai d'ade.

Lẹyin ti ori ko o yọ lọgba ẹwọn ti Abacha ju sí, Oloye Olusegun Aremu Obasanjo wọle ibo ààrẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, o si di aare alagbada lọdun 1999.

Aarẹ ana Naijiria Olusegun Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Obasanjo lọdun mẹrin akọkọ lori oye.

O tun ṣe bẹ́ẹ̀ wọlé saa keji lọdun 2003 nibi to ti tukọ Naijiria f'ọdun mẹrin mìíràn.

Oloogbe Umaru Musa Yar'adua di ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, lẹyin to jawe Olubori ninu ibo aarẹ ọdun 2007, bo tilẹ jẹ pe awuyewuye pọ lori esi ibo ọhún.

Ọpọ ni magomago wa ninu idibo naa.

Ṣugbọn iku ko dọjọ, arun ko doṣu.

Umaru Musa Yar'adua

Yar'adua ko lo ju ọdun meji lọ lori aleefa.

Ọjọ karun osu karun ọdún 2009 lo jẹ Ọlọrun nipe leyin to ti Irinajo de lati Sáúdí.

Aṣe orukọ ọmọ maa n ro ọmọ ni tootọọ.

Goodluck Jonathan to jẹ igbakeji Yar'adua depo aarẹ lẹyin ti ọga rẹ jẹ Ọlọrun nipe tan.

Aarẹ ana Naijiria Goodluck Jonathan

Oríṣun àwòrán, Facebook/Goodluck Jonathan

Jonathan dije fún ipò ààrẹ ninu ibo ọdún 2011 ninu eyi to ji jawe Olubori labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP.

Jonathan gbe ijoba fun Muhammadu Buhari wọọrọwọ lẹyin to jawe Olubori ninu eto idibo ọdun 2015.

Buhari ti dupo ààrẹ tẹlẹ fún igba mẹta ọtọtọ ko to pada wọlé labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC.

Buhari ṣèlérí ayipada tawọn oloyinbo n pe ni "change" lẹgbẹ APC fawọn ọmọ Naijiria.

Aarẹ Naijiria, Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Muhammadu Buhari

Sai Baba gẹgẹ bi awọn ololufẹ Buhari ṣe máa ń pe tun wọle saa keji lọdun 2019.

Buhari naa lo sí wa lori oye titi di akoko yii.

Ẹyin ọmọ Naijiria nile, loko, lodo ati lẹyin odi, ẹ ku ayajọ ọdun ijọba awaarawa.

Iwaju iwaju lọpa ẹbiti n ree si, Naijiria ko ni rẹyin lasẹ Edumar