Emmanuel Macron Slap: Damien Tarel to fọ́ ààrẹ France létí, fi ẹ̀wọ̀n jura.

Igba ti Damien gba aarẹ Macron leti

Oríṣun àwòrán, Screen Shot

Ilé ẹjọ́ kan ni ilẹ Faranse tí ni kí ọkùnrin ẹni ọdún mejidinlọ́gbọ̀n kan lọ fi ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́rin jura, lẹ́yìn tó jẹ́wọ́ nílé ẹjọ́ pé òun fọ́ ààrẹ Macron létí ni tòótọ́.

Damien Tarel sọ fún ilé ẹjọ́ pé, òun kò mọ̀ọ́mọ̀ fọ́ ààrẹ létí ṣùgbọ́n adajọ́ ní nǹkan tó mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ni, ó sì mú ìwà ipá dání.

Ilé ẹjọ́ tún gbọ́ pé Tarel jẹ̀ ọmọ ẹgbẹ́ alátakò, bákan náà ló sún mọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Yellow-Vest.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ààrẹ Macron ni wọn kò nílò láti pín ọ̀rọ̀ ìfọ́tí náà yẹ́lẹyẹ̀lẹ, bí kò ṣe pé kí wọ́n mú gbogbo rẹ̀ wà ní iwọntún-wọnsì.

Macron kúrò ilé ìtura ilé ẹ̀kọ̀ kan ni ìhà ìlà oòrùn gúúsù Tain-I'Hermitage, nígbà tí ó sáré lọ kí àwọn ènìyàn tó ń dúró dèé lẹ́yìn irin tí wọ́n fi yí àgbègbè náà ká.

Igba ti Damien gba aarẹ Macron leti

Oríṣun àwòrán, Screen Shot

Bí Tarel ṣe gbá ààrẹ létí tán, ní àwọn ènìyàn gbọ́ tó ń pariwo "Montjoie àti Denis! Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ bi Macronism"

Ní kété tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀ ni ọ̀pọ̀ àwọn olóṣèlú jákèjádò orílẹ̀-èdè France bẹnu àtẹ́ lu nǹkan tó ṣẹlẹ̀ náà.

Kò tó ọdún kan mọ́ tí ìdìbò ààrẹ mìíràn yóò wáyé ní orílẹ̀ èdè France.

Àwọn adájọ́ mẹ́ta sọ́ pé ẹ̀wọ̀n oṣù méjìdínlógún ló tọ́ sí ọkùnrin náà, ṣùgbọ́n wọ́n dá oṣù mẹ́rìnlá nínú rẹ̀ dúró náà àti pé oṣù mẹ́rin rẹ̀ kò bẹ̀rẹ̀ ni kíákíá ṣùgbọ́n tí ó bá ṣẹ ẹ̀sẹ̀ mìíràn ni àwọn yóò mú èyí wá sí lílò.

Ẹnìkejì to ya àwòrán ìṣẹ̀lẹ̀ náà ń kojú ẹ̀sùn níní ǹkan ìjà lọ́nà aitọ́ lẹ́yìn tí alaṣẹ lábẹ́lé lọ tú ilé rẹ̀. Ìlú kan náà sì ni òun àti Damien Tarel ti wà.

Aarẹ Macron n bawọn eeyan kan sọrọ

Oríṣun àwòrán, EPA

Kini Damien Tarel sọ fún ilé ẹjọ́?

Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn AFP ṣe sọ, olùjẹ́jọ́ náà wá sí ilé ẹjọ́ pẹ̀lú aṣọ aláwọ̀ ewé tó wọ̀ lọ́jọ́ tí wọ́n mú.

Nígbà tí wọ́n bíi ìdí tó fi hu irú ìwà bẹ́ẹ̀, ó sọ fún ilé ẹjọ́ pé, lásìkò tí òun ń dúró de ọ̀rẹ́ òun nínú mọ́tò kí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó wáyé, ní òun ti ronú láti ṣe nǹkan tí àwọn ènìyàn kò ní gbàgbé láyé.

Ó ní òun ti kọ́kọ́ ro o láti lẹ ẹyin mọ, ṣùgbọ́n òun kò tilẹ̀ ro fífọ́ ọ̀gá Macron létí.

"Ṣùgbọ́n mo rí ojú tútù tó lọ, tó sì parọ́ tí gbogbo ènìyàn fi jáde dibò fún bí ààrẹ, èyí ló bomi nínú, bí Tarel ṣe sọ fún ilé ẹjọ́

Ó bẹnu àtẹ́ lu bí ààrẹ ṣe ń ṣe ìjọba, Tarel fi kún pé òun wòye pé ààrẹ wá lára àwọn tó lòdì sí ìdásílẹ̀ gilets jaunes (Yellow Vest) àwọn yìí ló wọ́de ìféhónúhan lásìkò tí Macron ṣẹ̀ṣẹ̀ di ààrẹ, " bí ó ṣe wá simi lọ́kàn ni mo ṣe huwa" èyí ni Tarel sọ.

Awọn ọ̀rẹ́ Tarel pẹ̀lú sọ pé, kii se ẹni tó nífẹ́ sí òṣèlú rárá.

Òpó ikansiraeni instagram Tarel pẹ̀lú ṣàkàwé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ayàwòrán àti olólùfẹ́ ìtàn ilẹ̀ Yúróòpù, tó sì gbé àmì àṣà àti ìdá síbẹ̀.

Àkọlé fídíò, Ogbomoso: Ẹ kálọ sí Ajilete láti mọ àwọn ibùdó tó mú kí ìlú náà yàtọ̀

ni Macron sọ?

Ṣáájú ni ààrẹ Macron tí mójú kúrò níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà pé, kii se nǹkan tí á ń gbé léwọ́, àti pé kò yẹ́ kí wọ́n máa fún àwọn ẹlẹ́mìí ipanle láàyè, láti máa ní ore ọ̀fẹ́ ọ̀rọ̀ tí yoo má gbàsìkò àwùjọ.

Lásìkò to ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ níbi ayẹyẹ ìpàdé ìlọ́wọ́sí orílè èdè France nínú Ìdíje European football Championship, lo ti sọrọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

"A ti kojú àsìkò kan tí nǹkan lè koko, nígbà tí àwọn gilets jaunes gbé wàhálà de ṣùgbọ́n àwùjọ tí yí padà báyìí loni"

Ó fi kún pé òun ti pinu láàyè ara òun, láti gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sì ilé ẹjọ́, òun sì ṣetán láti fi gbogbo ọ̀rọ̀ sọwọ́ àwọn adájọ́.