Ogbomoso: Wo àwọn ibùdó ìṣẹ̀ǹbáyé tó mú kí ìlú yìí gbajúmọ̀

Àkọlé fídíò, Ogbomoso: Ẹ kálọ sí Ajilete láti mọ àwọn ibùdó tó mú kí ìlú náà yàtọ̀

Yoruba ni ilu ẹni, ni ilu ẹni, ko si si ibi to dabi ibi ta gbe bi ni.

Lori eto Ẹ kalọ si ilu mi ni osu yii, ilu Ogbomoso ni BBC Yoruba balẹ si lati fi oju se mẹrin awọn ibi pataki to jẹ manigbagbe ni ilu naa.

Lẹnu irinajo wa silu Ajilete yii, Ogbomoso ọmọ afogboja, ilu ti wọn ti n jẹ ọka tan, ki wọn to mu ẹkọ yangan, a se alabapade oniruuru ohun amoriwu lọkan o jọkan.

A kan si mọsalasi akọkọ nilu Ogbomoso, ati sọọsi St. David Anglican, akọkọ ti wọn kọ lọdun 1854.

Bakan naa la de aafin ọba Soun tilẹ Ogbomoso ati ibudo ti baba agba n gbe ko to ku, eyiun ijapa to wa ni aafin, to lo ọdun to le ni ọọdunrun laye.

Irinajo wa naa tun gbe wa de ibudo Ogun o jalu, to n se ọwọn iranti pe ogun ko ko ilu Ogbomoso ri.

Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹnu ko gba iroyin, ẹ maa ba wa kalọ silu Ogbomoso loni, lati fi imọ kun imọ yin nipa ilu olokiki naa.