Oba Olayode: Egbo to ti fẹẹ́ jiná ni ẹ tún ń fi èékáná te yìí - Omo Soun Ogbomoso II

Àkọlé fídíò, 'Egbò tó ti fẹ́ẹ̀ jiná ni ìtàn bí wọ́n ṣe pa Soun Ogbomoso, Ọba Olayode tẹ ń bèrè'

Gbogbo awọn ti BBC Yoruba fọrọ wa lẹnu wo nipa bi Oba Olayode keji to ti jẹ Soun ti ilu Ogbomoso ri nigba aye rẹ ṣe waja lo fẹrẹẹ ma fẹ sọ bi o ṣe ṣẹlẹ tori o jẹ ibanujẹ ọkan fun wọn.

Ọpọlọpọ awuyewuye lo si rọ mọ ipapoda Oba alade yii gẹgẹ bi a ṣe ṣewadii.

Laarin ọdun 1966 si ọdun 1969, iyẹn ọdun mẹta pere ni asiko Oba emmanuel Olajide Olayode lori itẹ Ọba gẹgẹ bii Soun.

"Egbo to ti fẹẹ́ jina ni ọrọ ti ẹ tun n fi eekan te yii".

Latori ọmọ bibi inu Oba Olayode, to fi mọ gbogbo mọlẹbi lo tan imọlẹ si ẹdun ọkan wọn nipa bi Oba yii ṣe waja.

Wọ́n jẹ ko di mimọ pe ẹni ti tara ile tara oko fẹran gan ni Oba Olayode bo tilẹ jẹ pe ija oye wa lori didi Soun Ogbomoṣo.

Oun ni Ọmọwe akọkọ ti yoo jẹ Soun ti Ogbomoṣo ṣugbọn nigba to di ọdun 1969... itan yipada biri.

Ọrọ ko lee dun lẹnu wa bii ọlọrọ bi wọn ṣe sọ ọ ninu fidio to wa loke yii.