Ogbomoso: Ẹbọ ọkùnrin àti obìnrin tí kò ní ìbálòpọ̀ rí ni wọ́n rú láti dènà ogun Fulani

Àkọlé fídíò, Ogbomoso: Ẹbọ ọkùnrin àti obìnrin tí kò ní ìbálòpọ̀ rí ni wọ́n rú dènà ogun Fulani

Yoruba ni agba ko ni tan lorilẹ, bi ọmọde ko ba si ba itan, yoo ba arọba, tii se baba itan

Ọpọ eeyan lo ti n gbọ itan pe ogun ko ja ja ja, ko ko ilu Ogbomoso ri, ti adugbo kan si wa nilu naa, ti wọn n pe ni Ogun o jalu.

Amọ bawo ni ilu Ogbomoso ti see, ti ogun ko fi ri ilu naa ko? Ọna lati wadi okodoro ọrọ lo mu ki BBC Yoruba tẹkọ leti lọ silu naa.

Nibẹ si ni Ọmọọba Olawuyi Oyelayo Itabiyi ti salaye bi olori Fulani, Alfa Alimi se gbinyanju lati ko ogun ja Ogbomoso amọ ti ko ri se.

Ọmọọba Itabiyi ni ẹẹmẹta ni Fulani Alfa Alimi wa si Ogbomoso laye Oba Toyeje Akanni Abaya Oluoyo.

Bakan naa lo tun salaye iru ẹbọ ti wọn ru lati dena ogun Fulani to pa Aarẹ Ọna Kakanfo Afonja nilu Ilorin, ko mase wọ ilu Ogbomoso.

Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Baba agba naa ni ọkunrin ti ko mọ obinrin ati obinrin ti ko mọ ọkunrin ni wọn fi ru ẹbọ naa.

Ọrọ pọ ti baba Itabiyi ba BBC Yoruba sọ, ẹ maa gbọ ninu fidio yii.